Àwọn àdúgbò ìlú Ìbàdàn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àwọn àdúgbò ìlú Ìbàdàn àti ìtumọ̀ wọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nọ. Àdúgbò Ìtumọ̀
1. Ìdí Ayùnrẹ́ Igi ayùnrẹ́ règèsì kan tí ó gbalè kankan, tí àwon ènìyàn máa ń ta osà ní abé rè ni wón fi so àdúgbò yìí ní ìdí-ayùnré.
2. Òjé-Ìgósùn Ìyá àgbà kan tí orúko rè ń jé Morádéyò ni ó máa ń gún osùn tá ní bií yìí ni wón fi so ibè di Òjé-ìgósùn.
3. Òkè Dàda Wèrè kan tí orúkọ rè ń jẹ́ Dàda láyé àtijó ni ó máa ń jókòó lórí òkè téńté yìí, ni àwon ènìyàn bá so àdúgbò yìí di Òkè-Dàda.
4. Ògbèré Èmí àìrí kan ni wón fún ní orúko yìí, Olú-odò nì èyí ní ìlú Ìbàdàn, èyí sì ni wón fi ń pe àdúgbò náà ní Ògbèré.
5. Ojà Oba Oba aládé kìíní ní ìlú Ìbàdàn, Olúbàdàn Àbásì ni ó te oja titun dó ní ààrin gbùngbùn Ìbàdàn, ìdí nì yí tí won fí ń pe àdúgbò yìí ní Ojà Oba.
6. Oríta mérin Òpópónà mérin tí ó forí so ara won ni èyí ibí yìí ni àwon àgbà ti máa ńse ìpàdé egbé aro láyé àtijó,
7. Láoyè Àgbà òjè ken ní ìlú Ìbàdàn ni alàgbà Laoye, àdúgbò tí ó tèdó sí ni èyí tí a ń fi orúko rè pe ibè ní Láoyè.
8. Elékùró Bàbá kan tí orúko rè ń jé gbàdàmósí ni onísòwò èkùró, Ògangan ibí yìí ni òsùwòn èkùró rè wà gégé bí ilé ìsé rè tí àwon àgbè onísòwò èkùró ti máa ń ta èkùré fún-un, ìdí nìyí tí won fi so agbègbè yìí ní elékùró.
9. Oríta Aperin Erin ń lá kan tí ó yaw o ààrin ìlú láyé àtijó, oríta yìí ni àwon Ode ti pawópò pa erin náà, ìdí nìyí tí won fi so ìkóríta yìí di oríta-aperin.
10. Idí Aró Ìyá àgbà kan tí orúko rè ń sé sìfááwù ni ó máa ń dá aró ní gbàgede yìí láyé àtijó. Ìsé aró dídá yìí ni ìyá náà yàn láàyò, ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò yìí ní ìdí aró.
11. Òde-ajé Ìyá eléko kan tí orúko rè ń jé wúlèmótù ni wón máa ń ta àkàsù èko ní gbàgede yìí. Tí ìyá bá ti gbé àpèrè èko rè dé gbàgede yìí, ní kíá ni yóò ti tà tán. Tí ìyá bá ti ń lo ni ó máa ń dágbére fún àwon ènìyàn pé òun ń gbé èko lo sí ode, ìdí nìyí tí àwon ènìyàn fi so àdúgbò yìí ní Òde-ajé.
12. Kòsódò Òdá omi ní àdúgbò yìí ni ó fàá tí gbajúmò alágbàfò Jádésolá se gbé ilé gégé bí odò adágún, tí ó sì fi ń fo aso àgbàfò rè, odò adágún yìí ya gbogbo ará agbègbè náà lénu, ìdí nìyí tí won se ń pe àdúgbò náà ní kòsódò.
13. Eléwùrà Ètò sògbé-dìgboro ló bá àdúgbò yìí, isu ewùrà ni isu stí ó gbajú-gbajà ní ibè láyé àtijó tó bé è tí won ń fi isu ewùrà se ààrò ìdánà. Ilè ibè tí ó gba isu yìí ló fàá tí won fi so àdúgbò yìí di eléwùrà.
14. Ògùn Èyí ni ibi tí ogun abélé parí sí ní ayé àtijó, Ogun parí ni ó dì Ògùnpa orúko àdúgbò náà.
15. Àgbède Adodo Èyí ni ìbùdó tí àwon alágbède tí máa ń ro irun, ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà di Àgède.
16. Abébì Igi Obì kan règèsì ni ó wà níbí yìí, gbàgede ni igi náà wà, èyí ló sì so àdúgbò náà dí ìdí obì.
17. Ináléndé Baálè Gbàdàmósí tí iná jó ilé rè ráúráú nì ó sá dé ibùdó yìí tí ó pè ní ibi tí iná le òun de, tí ó wá di Ináléndé.
18. Òkè Ààrẹ Èyí ni òkè tí ó wà ní ògangan ibi tí Ààre Látóòsà gúnwà sí ní ìlú Ìbàdàn.
19. Àlíìwó Ìbi tí jagunjagun Àlí láti ìlú Ìwó tí ó jagun fún Ìbàdàn tí ó sì ségun, ni ó tèdó sí ìbí yìí.
20. Olódó Alàgbà sùpò ní ó máa ń gbé odó tà ní ibí yìí, tí won bá ti fé ra odó, inú ilé ní wón ti máa ń pe bàbá yìí jáde láti wá ta odó fún won, báyìí ni wón se so ìbùdó yìí di olódó.
21. Gbági Ìtàn kan fi ye wa pé Gbagi tó jé erú ìbàdàn ni o wa te Gbági ìbàdàn do. wón ní ìgbà tí ogun ti mú Gáà ni Gbagi wa salo si ìbàdàn ìtàn miiran tún so fún wa pé àwon òyìnbó olókòòwò ló jé ki ìbè yen di Gbagi. Torípé gbogbo àwon èèyàn wá ń gba ìsò níbà. Àwon tó nà kan ìsò yen ló ń so fún àwon tó bá fé gba ìsò láti lo máa gbági mo ààyè won.
22. Dùgbè-Aláwo Àwo ni wón ń tà níbè.
23. Aliwo Ali iwo gan-an ni orúko re omo ìlú ìwó gan-an ni Àlí yìí. Sùgbón ó wá tèdó sí Ìbàndàn
24. Bódìjà Ní ayé àtijó jé kìkì koríko ló kún ibì tí a pè ní Bódìjà yìí. Ibè ni àwon eégún tó ba dára won lójú máa ti ń pe ra won nija. Àwon onílù á wá maa lùlù pé:

Bó bá dìjà só le dúró Bó bá dìjà sí lé adúró

Ibi tí wón ti rí Bódìjà nìyí

25. Odińjó Ìtàn fi yé wa pé odi kan wa ni àdúgbò yìí télè, ó máa ń sùgbón lójá kan ti onílù ń lù ìlù. Bí odi se bèrè sí jó nìyèn. Bí wón ti rí Odińjó nìyí
26. Amínígun Amúnígun bi esin Bàbá àlùfáà kan wa tí o maa ń kó àwon omo ni kewu. Ó wá ní esin kan tó máa ń gùn lásìkò tí àwon omo bá ń se wòlímò. Esin yìí lágbára gan-an Esin bàbá yìí ni won fi so ni orúko amúngun
27. Òré-méjì Àwon òré méjì ló te àdúgbò náà dó.
28. Ináléndé Àwon eni to ń gbé àdúgbò yìí jé bí ìjèbú tí ogun lé dé àdúgbò Naléndé.
29. Ìtamérin Oríta mérin ló pàdé ní àdúgbò yìí.
30. Ojà Oba Òjà yìí jé ojà tí wón ń ná ní ojúde Oba ìbàdàn. Ìdí rè é tí wón fi só ni ojà Oba.
31. Agbolé sàngóomí Nínú àgbolé yìí òrìsà sàngó ni wón ń sìn níbè.
32. Ìsàlè ìjèbú Ìwádìí fi yé wa pé àwon ìjèbú lé pò níbè jù.
33. Ìdí Obì Igi obì kan wa nì ògangan, ìbí yìí ìdí rè é tí wón fi pè ní ìdí obì
34. Ìdíosè Igi osè ràbàtà kan wa ni ògangan ibi yìí.
35. Abà alágbàá Ní àbà yìí eégún ni òòsà won níbè. Orúko eégún yìí sì ni eégún alágbàá.
36. Ìyànà ìwó-ònà yìí jé ònà tó lo sí ìlú Ìwó.
37. Sábó Àwon Hausa ló ń gbé ni ibè.
38. Ìdí osàn Igi Osan ló wà ní ògangan ibi yìí
39. Òkèàdò Àwon àjèjì ló pò níbè.
40. Orita UI Ilé ẹ̀kọ́ gíga yunifásitì Ìbàdàn ni wón fi so ibè lórúko.
41. Kúdetì
42. Pópótemoja Èèyàn ló di Bolò tí wón ń pè ni pópó temoja yìí.
43. Pápá ìsèré lékan salami Orúko èèyàn kan ni won fi se pápá ìsèré yìí. Eni yìí jé olórí àwon agbá bóòlù.
44. Academy Orúko ilé-ìwé kan tó wà ni ìbúdò ko yìí ni won fib o ni Academy orúko ilé-ìwé náà ni Bishop Philips Academy.
45. Oníyanrìn Ìtàn fi yé wa pé ìyèpè yanrìn po ni àdúgbò yìí télè ìdí rè tí wón fi so ni oníyanrìn
46. Oriyangi Òkúta yangí ńlá kan wa ni ògangan ibí yìí.
47. Wákájayé Àdúgbò tuntun ní àdúgbò yìí. Ìgbà tí àwon àjèjì bèrè sí wá ralè kale síbè ni àwon ará abà náà yìi orúko ibè padà si Wákájaye.
48. Òkè Àrèmò Ògangan yìí ni Àrèmo Aláàfin Òyó kókó dé nígbà tó wá sí Ìbàndàn.
49. Sevent-day Adventist orúko sóòsì tó wà ní àdúgbò yìí ni won fi so.
50. Òkèodò Àdúgbò yìí wa ni èyìn odò kan ni ònà odíńjó

51. Àdúgbo: Mòpó Ìtumò: Ilé ńlá kan tí ìjoba kó sí ìbàdàn ló ń je mòpó. Mapo Hill gangan ni orúko ibi yìí sùgbón ìgbà tó yá àwon ènìyàn bèrè sí ní pè nì òkè mòpó

52. Àdúgbo: Alésìnlóyé Ìtumò: orúko ojà kan ní ìbàdàn ni. Sùgbón orúko èèyàn kan ló ń jé béè.

53. Àdúgbo: Olówó ti n fi owó sànú-un Ìtumò: Ìbùdókoo kan ni èyí ní ìbàdàn; orúko èèyàn kan ni wón fi so. orúko eni náà ni Alhaji Múfútàù Oláníhùn. Ìbùdókò yìí wà ní ònà Gate.

54. Àdúgbo: Ìbàdàn Ìtumò: Èbá-Òdàn ni wón kókó ń jé télè nítorí pé ní èbá-òdàn ni àwon ògúnmólá tó té Ìbàdàn dó kókó de si kí wón tó ó bó sí àárín ìlú nígbà tí ojú ń là ni wón yí orúko náà padà sí Ìbàdàn.


55. Àdúgbo: Orogún Ìtumò: Ìyàwó méjì ni won jo wà lóòdò Oko gbogbo ìgbà ni ìjà ma ń wáyé láàrin àwon méjéèjì èyìn ìyàwó si ni oko ma ń gbèè sí Ìyàálé ka èyí sí àrínfín ló fi bínú dodo èyí ni wón fi ń pe odò yìí ní Orógún orúko yìí náà ni wón fi ń pe àdúgbò yen.

56. Àdúgbo: Ajíbode Ìtumò: Orúko ode kan ni wón fi ń pe ibí yìí kò sí ìgbà tí ènìyàn lè kojá níbè ti kò ní í bá odè náà níbè ìdí nìyí tí wón fi ń pe òdúgbò náà ni Ajíbóde.

57. Àdúgbo: Adéòyó Ìtumò: Adé ti àwon omo Osòrun gbé wá láti òyó ni wón kó sí ìlé kan ní àdúgbó yìí ni wón bá so ibè ní Adéòyó.

58. Àdúgbo: Ilé atééré Ìtumò: Ìrísí bàbà kan tí ń jé Yusuff ni wón fi so agboolé yìí ilé bàbá yìí ni ó wà ní àkókó kàn ní àdúgbò náà. Bí ó sé tééré ló mú won so àdúgbò náà béè

59. Àdúgbo: alágbàáà Ìtumò: ìdílé elégún ni ìdílé yìí. Eégún ilé won tí ń jé alágbàáà ni wón fi so àdúgbò náà

60. Àdúgbo: Dàádàá Ìtumò: enìkan tí ń jé Dáúdá ni wón so orúko rè di Dàádàá tí wón fi ń pe àdúgbò yìí.

61. Àdúgbo: Agbadagbudù Ìtumò: Odò àgbàrá tó ma ń dégún sí àdúgbò yìí tí ó ma ń dún gbodagbùdù ni wón fi so àdúgbò yìí ní agbedàgbùdù.

62. Àdúgbo: Agboolé Bánjo Ìtumò: Ode ni Okùnrin yìí ni àsìkò ogun ti àwon èèyàn bá ń sá sógùn ún sósì ó wá pe àwon ènìyàn pé tí àwon dijo dúró síbí ìdí nìyí tí wón fi ń pè é ní àgbolé Bánjo ibi tí àwon ènìyàn jo sí.

63. Àdúgbo: Òkè-Àrèmo Ìtumò: Àrèmo Obo kan ló yòó ti orúko rè ń jé Lándànì ló wá te ibí yìí dó nítorí ti ibè jé orí-òkè ni wón fi só di òkè-Àrèmo.

64. Àdúgbo: Basòrun Ìtumò: Ìdílé Osòrun òyó ló wá te àdúgbò yìí dó ni wón fi so orúko oyè ti ìdílé won ń je lóyòó so àdúgbò náà.

65. Àdúgbo: Olómo Ìtumò: Nínú àwon tí wón ma ń mo ilé-pàálábàrá láyé ìgbà yen bàbá kan wà ládùgbó yìí tó jé ìlú mò-ón-ká nínú ìsé òmòlé ló jé kí wón so àdúgbò náà ní ilé-olómo.

66. Àdúgbo: Ìdí-Osè Ìtumò: Igi ló ń jo osè yìí àwon ènìyàn ma ń dúró sídìí rè láti won okò nígbà tí ó wá dip é àwon ènìyàn ń kí ilé sí agbègbè yìí ni wón wá á fi igi yìí so àdúgbò náà.

67. Àdúgbo: Adábaálé Ìtumò: Egúngún ló ń jé Adábaálé láti ìlú òyó ni wón ti gbé eégún yen wá síbè, orúko eégún yìí ni wón fi ń pe àdúgbò yìí

68. Àdúgbo: Iyemetu Ìtumò: Ìyá kan wà lágbègbè yìí tó ń ta etu, ti àwon ènìyàn bá ń lo sódò ìyá yìí won á so pé àwon ń lo sílè yèyé metu, èyí ni wón súnki di Ìyemetu.

69. Àdúgbo: Odò onà-Eléwé Ìtumò: Odò kan ló ń jé onà àwon ìyá kan ma ń ta ewé lápákan ibi tí odò wáà ti sàn kojá idí nìyí ti wón fi ń lo ewé láti yán an kí ènìyàn lè mo ibi tí à ń tóka sí lápá odò náà.

70. Àdúgbo: Olóya Ìtumò: Wón ń bo òrìsà Oya ládùgbó náà ni orúko òrìsà yìí ni wón fi so àdúgbò yìí.

71. Àdúgbo: Bodè-Òjà Ìtumò: enu òpin ìlú ni bode wón tún wá á dé ojà síbè ni wón fi ń pè é ní bode-ojà.

72. Àdúgbo: Mòlété Ìtumò: Okùnrin kan tó jé àáfà mùsùlùmí ló ma ń kínrun níbi yìí yóò wàá lé téńté èyin ló jé kí wón máa wi pé ìmòle lé téńté èyí ni wón se àsúnkì rè sí mòlété.

73. Àdúgbo: Ògúntnlà Ìtumò: Òde ni bàbá yìí ìlú Abéòkúta ló ti sode wá sí Ìbàdàn ibi tí ó wá tèdó sí tó ń gbé ni wón ń pé lábè ògúntulà.

74. Àdúgbo: Òjé Ìtumò: ìdílé yìí jé ti àwon alágbède Òjé.

75. Àdúgbo: Òke-Sápátì Ìtumò: Òkè yìí ga ò wé rí gánrangánran bi òkè yúse rí ni wón fi ń pe àdúgbò yìí.

76. Àdúgbo: Ògbèré Ìtumò: Odò kan ló sàn kojá ládùgbó yìí ti orúko rè ń jé àgbèré èyí ni wón so di orúko fun àdúgbò náà.


77. Àdúgbo: Kòsódò Ìtumò: ní àdúgbò yìí kò sí omi kankan ní be tó jé pé tí wón bá gbé kànga kò lè kan omi èyí ló mú won so àdúgbò yìí ní kosódò.

78. Àdúgbo: Ayékalè Ìtumò: gbogbo àwon tí wón kókó wá láti ilú ìbòmíran sí Ìbàdàn agbègbè yìí ni wón kókó dúró sí kí wón tó ó fónká ló sí ìgboro orísìírìsìí àwon èyà ní ilè-Yorùbá la lè bá pàde nib í ìdí nìyí tó fi ń jé Ayékalè.

79. Àdúgbo: Ìdi-Obì Ìtumò: Igi Obì kan ràpàtà ló wà ládùgbóò yìí òhun ni wón ń to láti fi pè é.

80. Àdúgbo: Omólàde Ìtumò: Orúko ìnagije tí wón fún jagunjagun kán tí àwón ènìyàn rè rò pé ó ti kú sójú ogún nítorí won kò gbúròó rè fún ìgbà pípé. Ojó tó dé ó ua àwon ènìyàn lénu ni wón ba so pé omólàde tó di orúko àdúgbò yìí

81. Àdúgbo: Odińjó Ìtumò: Ní ayé àtijó, a maa n ní odi ìlú, bákan náà ni a máa n ní bode ìlú. Nígbà tó di ojó kun, àwon omodé tó ń dègbé bá seesi finá sí oko. Báyì ni odi ìlú se bèrè sii jóná. Enìkan sáré wádè sáàrín ìlú láti so fún wón pé odí ìlú ti ń jóná. Báyi ni gbogbo ènìyàn se ń pari wop e Odíńjo odíńjó tí `dúgbò náà sì dí odíńjó loni

82. Àdúgbo: Pópó Yemoja Ìtumò: Ojúbo òrìsà yemoja wà ni àdúgbò náà, ti kò sì sí onà míràn láti gbà dé ibè yàtò sí ojú ònà kan soso. Nítorí ìdí èyí ni won se ń pe ojú ònà yìí ní òpópó yemoja

83. Àdúgbo: Bodè Ìtumò: Ibi tí ojà Bodè wà lónì yìí ní enu odì ìlú nígbà náà. Ibè ni àwon omibodè maa ń dúró sí láti máa só ìlú náà.

84. Àdúgbo: Òrányàn Ìtumò: Ènìyàn ni ó n jè òrániyàn yìí, tí ó di odò pèlú ìbínú ńlà. Ojúbo odò náà ni wón fi so àdúgbò ibè ní orúko tó ń jé láti máa fi se ìránti rè.


85. Àdúgbo: Ògùnpa Ìtumò: Akínkanju Ológun kan ni ó di odò láyé àtijó. Ìdí nìyí tí wón fi ń pe odò náà ní orúko re Ògùnpa, ti oruko náà sì di orúko àdúgbò náà.

86. Àdúgbo: Èsù Awele Ìtumò: Ojúbo èsù ńlá kan wa ni ibi tí wón ń pè ni èsù àwèlé lorni. Ìdí sì nìyí tí wón fi ń pé àdúgbò náà ni orúko yìí.


87. Àdúgbo: Òrè-Àré Ìtumò: Orí òkè ti ààre Látóòsà kole sí ni wón ń pè ni òkè àrelónì

88. Àdúgbo: Ile-tuntun Ìtumò: Ibi tí a ń pè ní ilé-tuntun lónì jé igbó ń lá télètélè ti kò sì sí àwon ilé oní bíríkì kankan níbè. Àdúgbò yìí ni wón kókó kó ilé oní bíríki sí ní ìlú Ibadàn. Ìdí nìyí tí a fi ń pé é ní Ilé-tuntun.

89. Àdúgbo: Ìta ègé Ìtumò: Ilé eléégún tí ó ń jé afìdi èlégèé ni ó wà ní àdúgbò náà, tí ó sì ní orúko ńlá ní ìlú Ìbàdàn. Àti pé ibè ni wón ti máa ń se àseye fún eni tó bá kú tí kìí se elésìn mùsùlùmí tàbí ìgbàgbó.

90. Àdúgbo: Ìta-Baale Ìtumò: Àgbègbè tí bale kan tó n jé Olúgbòde ni ìlú Ìbàdàn láyé àtìjó kólé sí ni a ń pè ni Ìta-baálè lónì yìí.

91. Àdúgbo: Kudeti Ìtumò: Akinkanjú ológun kan un ó di Odò láye àfìjó nígbà tí àwon òdá rè fé mu. Ó wòó pé kàkà kí ilè kú ilè á sá. Ìdí nìyí tí wón fi so Odò náà ni kúde tì láti máa fi se ìrántí akoni náà, tí gbogbo agbègbè náà sì di kúdetì bákan náà.

92. Àdúgbo: Ìsale-Ìjebu Ìtumò: Ìbi yìí gan an ni ògangan agbègbè tí àwon Ìjèbú tèdó si nígbà ti wón de Ìbàdàn.

93. Àdúgbo: Inalende Ìtumò: Agbègbè kan tí àwon ènìyàn tí ogun lé kùró ní ìbùgbé won tèdó sí, tí wón sì fin í ìsinmi ni a ń pè ni Ináléndé lónì yìí.

94. Àdúgbo: Òde-Ajé-Olóòlù Ìtumò: Egúngún ni lá olókìkí kan wà ilú Ìbàdàn tí kìí pojú kan Obìnrin. Agbègbè tí ilé eni tí maa ń gbé eégún náa wà ni a ń pè ní Òde-ajé Olóòlù sì ni orúko egúngún náà ní Òde-ajé-Olóòtù.

95. Àdúgbo: Beyerunka Ìtumò: Okùnrin kan wà láyè àtíjó tó ní n àsìn bíi adìye ati eyele, okùnrin yìí sì fún je eni tó burú púpò. Bákan náà, okùnrin yìí féràn àgbàdo púpò. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń fun àwon ń nkan òsìn rè lóńje, ni oùn náà máà ń je àgbàdo ti rè. Nítorí ìwà yìí, àwon ènìyàn máa ń júwe ìlé rè gégé bíi bàbá-a-bá-eye-rún-oka bàbà. Báyìí ni wón se só ó di Béyerúnkà.

96. Àdúgbo: Elekùró Ìtumò: Agbègbè yìí jé ibi ti òwò èkùr’’o pípa wópò sí. Ìdí nìyí tí won fi so àdúgbò náà ní elékùró.

97. Àdúgbo: Ilé Abòkè Ìtumò: Agbègbè yìí ni bàbá tí ó máa ń bo òrìsà òkè-Ìbàdàn ń gbé. Ìdí nìyí tí won fi ń pe àdúgbò náà ni ìlé abòkè.

98. Àdúgbo: Dùgbè Ìtumò: Agbegbe tí àwon ènìyàn, tí ogun lé kúrò níbì kan, tí gbogbo wón sì ro gìlàgìlà dé sí ni a ń pè ní Dùgbè

99. Àdúgbo: Amúnígun Ìtumò: Ìtàn fi yé wa pé Òkan léhìn àwon omo Ogun Bashorun Ìbíkúnlé tí ó jé jagun-jagun pàtàkì ní ìlú Ìbàdàn ní ó ńgbé àdúgbò yìí. Nítorí àkíkanjú rè lójú ogun tú won fi ńpè ni amúló ju ogun. Ìnagije yìí sì ni won so di Amunigun

100. Àdúgbo: Agodi Ìtumò: Ibí jé àgó àwon abìrun kan, àwon odi ni wón máa ńkó síbè fún ìtójú, ní ayé àtijó ilé-ìtóju odi ní ibè jé.

101. Àdúgbo: Abébi Ìtumò: Ní àyé àtijó oko obì ní wón fi adúgbò yìí dá àwon àgbè alóko osì ní ó ńgbé ìbè tí o fí jé wípé tí ènìyàn bá ńlo abé obì ni yío màà tò lo.

102. Àdúgbo: Béyerúkà Ìtumò: Okùnrin kán wà ní àdúgbò tí féràn láti máa je àgbàdo, ni ìgbà yen àwon àgbe ka àgbàdo kún oúnje ye nítori, ìdí èyí ní wón se ńjè Okùnrin náà ní eni tí ó ń bá èye rú Okà.

103. Àdúgbo: Beere Ìtumò: Ibí yìí jé Ibi tí iwón máa ń pa koríko kan tí ó ń jé beere lo fún Aláàfin láyé àtijó.

104. Àdúgbo: Alakìa-Adegbiyi Ìtumò: Ìnagije alàgbà tí ó jé baákì àdúgbò yìí rí, tí ò si je oloro pèlu oun ti eni àkoko láti dé àdúgbò yìí.

105. Àdúgbo: Agbeni Ìtumò: Ní àárò ojó àwon onísòwò ni àwon tí ó tèdó sí ibí yìí. Ìtumò orúkoyìí ni agbeni bí owó.

106. Àdúgbo: Bédyà Ìtumò: Àwon àgbà fí yé wá pé awuye wuye kún tí ó wáyé láàrín àwon elegbé ode lórí ode tí ó tédòó láti de igbó yìí. Orúko àdúgbò yìí gan ni “Igbódìjà”

107. Àdúgbo: Adámásìngbà Ìtumò: Ìtàn yíì dá lórí okùnrin kan tí ó yá owó sùgbón tí kò lè singbà nípasè àíró wó san, ó dá ìgbà àti dá owó yìí padà sùgbón kò ri san.

108. Àdúgbo: Èkótèdó Ìtumò: Nítorí Ìwà òlàjú, òmòwé àti aláfé ti gbayì ní àdúgbò yìí ni wón fi so lórú ko yìí.

109. Àdúgbo: Òja Igbó Ìtumò: Igbó ni àdúgbò yí jé ní ayé Ìgbà yen, àwon ará àdúgbò yìí ni wón béèrè sì nà ojà alé ní bè Ìdí nà yí tí orúko àdúgbò yìí fi wáyé.

110. Àdúgbo: Ìdí arere Ìtumò: Igi kúnwá nì àdúgbò ewé aréré ni ó maa ń wù lórí rè, ewé yìí máa ńtàn tí o fi sé wípé Ibòji ré pò púpò, ìwon ènìyàn máa ńjoko láti gba ategùn níbè won sì máà ń se fàájì níbì pèlú.

111. Àdúgbo: Ita-maya Ìtumò: Alàgbà ken tí orúko rè ńké máyabìkan ni wón gé kúru ti wòn sí ńpè ní ìta máyà.

112. Àdúgbo: Ìsàlè-Òsì Ìtumò: Òkin lára àwon olóyè olúbàbàn kan tí ó ńjé òsì máyè ni ó tèdó sí ibí yìí láyé àtijó

113. Àdúgbo: Oke foko Ìtumò: Nkan ti o mu oriko adugbo yii wa nipe adapo yangi ati ile erofo ni olorun da ibe, o sit un je oke, Ibe maa n nira lati gba.

114. Àdúgbo: Ode Aremo Ìtumò: Ibi yíi ni awon oyinbo ajele gbe aremo Alaafin Oya sa pamo si ki o maa ba ku lehin Iku baba re gere bi asa awon Oyo.

115. Àdúgbo: Apata Ìtumò: Ibí yii ni awon ara ilu Egba fi se Ibí isadi won ni igba aye ogun nigabi.

116. Àdúgbo: Idi Ayanre Ìtumò: Igi ayanre kun ni o ti wa ni adugbo yìí kí ó ti wa dí wipe awon ènìyàn la ile loju de ibe.

117. Àdúgbo: gbénlá Ìtumò: Àdúgbò yìí jé ibi tí won ní orúkí asiwájú kan ni akoko kan ni Ibadan tí orúko rè ń jé Ológbéńlá. Ológbéńlá yìí ni wón wá so di “Gbenla”èka-èdè ló fà á

118. Àdúgbo: Alékúsó Ìtumò: A gbó pé ni àsìkò ogun Ìbàdàn àti ìjàyè, owó àwon ìjàyè ló kókó dun àwon Ìbàdàn ti won sì mu olórí ogun Ìbàdàn ìgbà náà sí ìgbèkùn won. Àwon omo-Ogun Ìbàdàn padà sí ilé láti lo tún ara mu, won sì padà ìjàyè ni àkókó yìí ni Ibàdàn ségun Ìjàyè pátápatá tí wón mú lérú Okàn àwon Ìbàdàn kò bale nígbà tí wón dé ilé nítorí èèyàn líle ni awon ìjàyè ìdí nìyí tí wón fi wá yan àwon òpò omo-ogun won sí ojú ònà tí àwon ìjàyè mó ó ń rìn wo Ìbàdàn, lásìkò ìgbà náà láti máa só won. A gbó pé àwon omo-ogun wònyí lò to osù méta dáádáá kíwon tó kúrò níbè, ni wón fi so ògangan ibè ni Alékúsó (ibi tí a gbé uan eeyan kó máa so won).

119. Àdúgbo: Òde-Ajé Alálùbósà Ìtumò: Ojà kan ló wà nì adúgbò yìí tó jé wí pé kìkì àlùbósà nì wón máa ń tà, ní bè gégé bí isé ajé won. Ibikíbi ní àwon ìlú tó wà léti Ìbàdàn sin i won ti máa ń wá ra àtùbósà tó bá ti je enì tó fé ra òpò.

120. Àdúgbo: Òde-Ajé Olóòlu Ìtumò: Àbúrò ni eni tó/te/ Ode-Ajé olóòlù yìí jé sí eni tó te àdúgbò òde-Ajé alálùbósà dó ó, kó tó di ojà. A gbó pé jagunjagun ni wón àti wí pé eégún Olóòlù yìí òkan lára erù ti wón ko bò láti ojú-ogun ni. Ègbón ló ní kí àbúlò òun sún sí ìsàlè díè kí ó tó dúró, èyí ló fà á tí àdúgbò mejeeji yìí kò fi jìnnà si ara won.

121. Àdúgbo: Òkè-Àpón Ìtumò: Àdúgbò yìí ń be láàrin òjé sí yemétu Ìdí tí wón fi ń pè é ni Òkè-Àpón ni pé òke-kere ni àdúgbò òhún wà tó sì takété sí títì lákòókò kan àwon tí kò tíì ni Ìyàwó nílé nì wón máa ń sáábà gba tàbí réǹtì ilé sí àdúgbò yìí, pàápàá àwon omo ile-ìwé èkósé Nóòsì ti na ìwe èkóse noosí tiko jinna sibe àti àwon òsìsé sekiteríàtì. Nítorí pé àwon òdó wá po níbè tíwon kò sì tíì ni ìyàwó tàbí oko ni won fi so àdúgbò yìí ní òkè-Àpón. Tí àwon olóńje bíi èbà, iyán fùfú èwà àti béèbéè/ lo bá ti apé ońje lé omo won lórí fún kíkiri, won á wà so fún-un pé kó tètè mó o gbé ojà rè lo oke-Àpón nítorí ojà, pàápàá ońje, a máa tà níbè púpò.

122. Àdúgbo: Agbeni Ìtumò: Abénà ìmò mi so pé àwon ará Ìbàdàn gbèjà Ìbikúnle tó jé Balógun won ní àkókò ken pé wón wá ta òtúu rè lójì (ojì -> gbèsè tàví fáìnì) wón wá so pé ibi ti baba won ìyen (ìbíkúnlé) gbé sanwo ojì náà ni won ń pè ni Agbeni ìdí nìyí tíwón fi máa ń ki àwon Ìbàdàn ní “Agbeniníjà omo òkè Ìbàdán

123. Àdúgbo: Móníyà Ìtumò: Àdúgbò yìí jé bí oríta tó ya ìlú ìjàyè àti Òyó sótò ní Ìbàdàn. Ìdí nip é ni Móníyá nì èèyàn tó ń lo sí ìlú ìjàyè yóò ti yà. Ní ojó ti àwon ará Ìbàdàn/wá ń lo sógun ìjàyè nígbà tí won dé móníyá wón pín ara won àwon kan yà sí ona tó gba ìjàyè lo tààrà, àwon kan gba ojú ònà òyó lo láti lè gba fìdítì wo ìjàyè Ògúnmólá ni wón so pé, ó sájú Ogun lódún náà, wón ní Ìbíkúnlé ò lo “Ibi ti gbogbo wa ti yà là ń pè ní Móníyà”

124. Àdúgbo: Gégé Ìtumò: Lójó tí àwon Ìbàdàn ń lo Ogun Èkìtì parapò ti àwon omo ogun tó jé akoni wa kó ara won jo sójú kan tí won ró gégé kí won ó tó wa ránsé re ilé Balógun Ìbíkúnlé pé kó máa bò pé àwon ti se tán ni “Gégé” “Won ró gégé-tan won ranse re ilé Balógun won”.


125. Àdúgbo: Òdè-Òlóló Ìtumò: Nígbà tí wón ń lo ogun Èkìtì parapò yìí wón ní ó pé won díè ki wón ó tó fi ìlú Ìbàdàn sí ilè nítorí won kò múra fún ogun yìí, òjíjì ni won rónísé Alaafin kí omo ogun tó ye kó lo, ó tó múra tán ó pe díè. Ibì tó wà gbé ló won jáí púpò kí won ó tó fi odi ìlú sílè ni wón so nì “òde-òóló”.

126. Àdúgbo: Lábó Ìtumò: Láyé ìgbà kan, Okùnrin ìjèsà kan wà nì ìlú. Ìbàdàn tó jé pé ó máa ń sòsómàáló. Okùnrin yìí gbajúmò púpò aso-òkè ló máa ń tà. Ní ojó kan owó rè wá bó sonù, ó wa owó yìí títí, kò ri, bàbá yìí wá bèrè sì í ké nitori owo yìí ká a lára, owó tó ti ń pa á bò láti àárò ni ‘Òwó bó, Olá bó, ìbòòsí àrè” Ibi tówó bàbá ìjèsà gbé bó sonù là ń pè nì “Lábó”

127. Àdúgbo: Eléta Ìtumò: Àdúgbò yìí ni won ti máa ń pín àgbá ota fún àwon omo-ogun Ìbàdàn tí wón bá ń lo ogun. Ibi ti won ti rí yíta Ogun fún wa ni “Eléta”

128. Àdúgbo: Ayéyé Ìtumò: Abénà-ìmó mi so fun mi pé ibi ti won ti yé àwon eni àkókó sí ni ayéyé. Òkan lára àwon tí wón yé sí nígbà náà lóhùn-ún nì “Agbájé Ayéyé “Ibi tí a gbé yéni sí là ń pè láyéyé”.

129. Àdúgbo: Òpóyéosà Ìtumò: Láyé ijóun, tí wón bá fe lo sí ogun ní ìlú Ìbàdàn, Balógun yóò se ìkéde láti pé àwon ode, olóògùn ológun tó bá dára rè lójú tó fé bá won lo sójú ogun. Nígbà tí gbogbo àwon èèyàn wòn yí ba péjú sìbà, ni Balógun àti àwon ìjòyè rè yòókù yóò tó wá á sa àwon to pójú-òsùwòn láti lo léhìn òpò Ìdánrawò. Òpóyéosà ni gbangba ibi tí wón ti máa ń se èyí Níbàdàn wà nitori ko jinnà si ilé Balógun. Irú èyí náà selè nínú ìwé Ògbójú Ode nínú Igbó Irúnmolè tí D.O. Fágúnwà ko. Ibi tí a gbe n sa won lójó tá a bá n lo ogun là ń pè ni yéosà nijo-un.

130. Àdúgbo: Náléndé Ìtumò: Wón ní ìná ló lé àwon ènìyàn tówà ní àdúgbò yìí dé ibè láyé ijóun. Wón wá so pé ní àdúgbò odinjo ni iná ti sé lójó náà, èyí fíhàn pé àwon tó sá kúrò níbè tí won kò padà síbè mó ni won so ibè ni orúko ìtumò re nip é (Ní-hàà-ín ní iná lémi dé)

131. Àdúgbo: Ìdí Arere Ìtumò: Lójó ti iyò wón ti gbogbo Ìbàdàn àti ìlú agbègbè rè kó rí iyò je tàbí se Obè. Ológbó tawón pé iyò pé iyò wà nì ìkòròdú lébàá Èkó ni gbogbo Ìbàdàn bá to jánà rere bí esú jáko. Ìyá baba mi máa ń pe odún náà ní “Odún gágá”. Nígbà tí wón wá n padà bò látìkòròdú, Ìdí Arere ni àwon èrò kókó gbé sò. Níjó èrò ìbàdàn n wayo o rekorodu tí gbogbo wón to jánà rere bi esú jáko, ìdí Arere lakokoso èrò”

132. Àdúgbo: Olóòsà-oko Ìtumò: Òòsà-oko nì won máa ń bon i àdúgbò yìí Níbàdàn. Àwon Oloosa oko ló wà ní bè títí di òní. Awoni ènìyàn a sì máa lo toro omo níbè 133. Àdúgbo: Agodi Ìtumò: Àgó-odi-ìlú ló di Agodi nítorí èhìn odi ìlú ni àdúgbò yìí wà láyé àtijó Níbàdàn Ibè si ni ilé-isé Telifísòn àkókó wà nítorí ìbè máa ń dáké róró ni.


134. Àdúgbo: Òkè Páàdì Ìtumò: Àdúgbò yìí ni àwon ìjo Àgùdà fi Ìbùjokòó sí nígbà tí wón dé pèlú èsìn won páàdi ni wón máa ń pe àwon olórí èsìn yìí.

134. Àdúgbo: Ìdí Ìrókò Ìtumò: Bàbá kan ni ó máa ń dá oko sí èbá ìdí Ìrókò ní àtijó. Ìgbàkúùgbà tí wón bá ti ń wá bàbá yí tàbí wón fé gba nǹken lówó rè, wón á ní kí won lo wò ó ní Ìdí-Ìrókò. Bí bàbá yí se kó abúlé síbè nìyí àti ìgbà yìí ni wón ti ń pe ibè ní ìdí Ìrókò.

135. Àdúgbo: Òkè Sápátì Ìtumò: Òyìnbó kátólíìkì ni a gbó pé ó kó ilé rè si orí okè kàn ti àwon ènìyàn sì máa ń wo ilé náà lórí òkè téńté ríí wón bá wá béèrè pé níbo ni enìkan ń lo o le ni ibi tí sápátì kólé kólé si. Bí wón se so ibid i òkè sápátì nìyí