Ṣàngó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
"Òrìṣà Ṣàngó"tí a figi gbẹ́
Igbá Sango

Ṣàngó Olukoso, Oko Oya.

Òrìṣà Ṣàngó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òrìṣà tí àwọn Yorùbá ń bọ. Ṣàngó jẹ́ òrìsà takuntakun kan láàárín àwon òrìsà tókù ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó jẹ́ orisà tí ìran rẹ̀ kún fún ìbẹ̀rù, Ìrísí, ìṣe àti ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá kún fún ìbẹ̀rù nígbàtí ó wà láyé nítorípé ènìyàn la gbọ́ pé Ṣàngó jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí ó tó di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Ìtàn sọ wí pé ọmọ Ọ̀rányàn ni ṣàngó ń ṣe àti pé Ọya, Ọ̀ṣun àti Ọbà ni wọ́njẹ́ ìyàwó rẹ̀.

Ìhùwàsí búburú ati dídá wàhalá ati ìkọlura pẹ̀lú ìjayé fàmílétè-kí-n-tutọ́ pọ̀ lọ́wọ́ ṣàngó g̣ẹ́gẹ́ bí Ọba tó bẹ́ẹ̀ títí ó fi di ọ̀tẹ́yímiká, èyí jásí wí pé tọmọdé tàgbà dìtẹ̀ mọ́ ọ. Wọ́n fi ayé ni í lára. Ó sì fi ìlú Ọ̀yọ́ sílẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ó pokùnso sí ìdí igi àyàn kan lẹ́bà ọ̀nà nítòsí Ọ̀yọ́ nígbàtí Ọya: Ìyàwó rẹ̀ kan tókù náà sì di odò.

Ọgbọ́n tí àwọn ènìyàn ṣàngó tókù dá láti fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà nípa títi iná bọlé wọn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ó sọ ṣàngó di òrìṣà tí wọ́n ń bọ títí dòní tí wọ́n sì ńfi ẹnu wọn túúbá wí pé ṣàngó kò so: Ọba koso.

Àwọn orúkọ tí Ṣàngó ń jẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Oríṣiríṣi orúkọ ni a mọ ṣàngó sí nínú èyí tí gbogbo wọn sì ní ìtumọ̀ tàbí ìdí kan pàtó ti a fi ńpè wọ́n bẹ́ẹ̀. Àwọn orúkọ bíi ìwọ̀nyìí:

  1. Olúkòso: Ẹnití a mọ̀ mọ́ kòso tàbí ọba tí ó wọlẹ̀ sí kòso.
  2. Arẹ̀kújayé:
  3. Àjàlájí:
  4. Ayílègbe Ọ̀run:
  5. Olójú Orógbó: nítorípé orógbó ni obì tirẹ̀, òun ni ó sì máa ń ṣàfẹ́ẹ́rí nígbà ayé rẹ̀. Orógbó náà sì ni a máa ń lo ní ojúbọ ṣàngó títí di òní.
  6. Èbìtì-àlàpà-peku-tiyẹ̀tiyẹ̀: Òrìṣà tí ó máa ń fi ìbínú gbígbóná pa ènìyàn ni àpalàyà tàbí àpafòn.
  7. Onibon ọ̀run: gẹ́gẹ́ bí òrìṣà ó ń mú kí àrá sán wá láti ojú ọ̀run pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ tó lágbára.
  8. Jàkúta: gẹ́gẹ́ bí òrìṣà tí ń fi òkúta jà (ẹdùn àrá). Irúfẹ́ òkúta kékẹrẹ́ kan tí ó máa sekúpa ènìyàn nípasẹ̀ ṣàngó
  9. Abọtumọ-bí-owú: Òrìsà léè wọlé pa ènìyàn bi ẹni pé ẹrù ń lá ni ó wólu irú ẹni bẹ́ẹ̀.
  10. Èbìtì-káwó-pònyìn-soro: Irúfẹ́ Òrìṣà tí ó jẹ́ wí pé ìṣọwọ́-sekúpa asebi rẹ̀ máa ńya ènìyàn lẹ́nu gidigidi.
  11. Alágbára-inú-afẹ́fẹ́: Òrìsà tí ó jẹ́ wípé ọwọ́jà a rẹ, máa ńwá láti inú afẹ́fẹ́ tàbí òfurufú ni.
  12. Abánjà-májẹ̀bi: òrìṣà tíí jà láì ṣègbè lẹ́yìn aṣebi tàbí ṣe àṣìmú elòmíràn fún oníṣẹ́ ibi.
  13. Lánníkú-ọkọ-ọya: Òrìsà tí o ni ẹ̀rù iku níkàwọ́.
  14. Òkokoǹkò ẹ̀bìtì: Òrìsà tí ó le subú lu ènìyàn bii ìgànnán tí ó ti dẹnukọlẹ̀.
  15. Eléèmọ̀: Òrìsà tí ó ni èèmọ̀.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Daramola Olu [1967] Awọn Asa ati Orisa Ilẹ Yoruba. Lati ọwọ Olu Daramola ati jẹjẹ Adebayọ
  • Adeoye C. L. [1985] Igbagbọ ati Ẹsin Yorùbá. Ibadan. Evans Brother. Press