Fẹlá Ṣówándé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Fela Sowande)
Olóyè
Fẹlá Ṣówándé
MBE
Fáìlì:Fela Sowande.jpg
Ọjọ́ìbí29 May 1905
Abẹ́òkúta,
Aláìsí13 March 1987 (1987-03-14) (ọmọ ọdún 81)
Ravenna, Ohio, Amẹ́ríkà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Akọrin àti Olórin

Olóyè Olúfẹlá Ọbáfúnmiláyọ̀ tàbí "Fẹlá" Ṣówándé MBE tí wọ́n bí ní ọjọ́ọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n osù Karùn-ún ọdún 1905, tí ó sì papò da ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹta ọdún 1987. Olúfẹlá jẹ́ akọri àti olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ẹ̀ wípé Fẹlá jẹ́ ọ̀kan lara àwọn olórin ìgbàlódé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n mọ fẹlá pẹ̀lú ìṣọwọ́ kọ orin rẹ̀ jákè-jádò àgbáyé, pàá pàá jùlọ ní ilẹ̀ Europe, wọ́n gbà fun pẹ́lú ọnà orin Classic' rẹ̀. Oun sì ni wọ́n mú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó Mọ orin í ke jùlọ ní gbogbo ilẹ̀ Adúláwọ̀.[1]

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣówándé tí wọ́n ma ń àánú pe ní ( 'shoh-WAHN-daye') [2] ni wọ́n bí ní ìlú Abẹ́òkútaÌpínlẹ̀ Ògùn ni ó jẹ́ ọmọ bíbí inú ọ̀gbẹ́ni Emmaniel Ṣówándé tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ orin ilé-ìjọsìn. Fẹlá gẹ́gẹ́ bí ọmọ olùdásílẹ̀ orin ní inú ilé ìjọsìn "Cathedral Church of Christ" náà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ akọrin. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama C.M.S. àti ilé-ẹ̀kọ́ King's College.[3] Ipa Baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórin ati i Dókítà T. K. Ẹkúndayọ̀ Phillips tí ó jẹ́ (akọri, organist ati ọ̀gá akọrin) jẹ́ ohun tí ó ràn ọ́ lówọ́ nínú iṣẹ́ orin nígbà èwe rẹ̀. Lásìkò èwe rẹ̀, Ṣówándé jẹ́ ọ̀gá akọrin, àmọ́ wọ́n kọ bí ó ṣe lè ma fi èdè Yorùbá kọ orin rẹ̀. Lásìkò tí a ń wí yí, Ṣówandé kọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ dùrù ati àwọn irinṣẹ́ orin mìíràn lábẹ́ ọ̀gbẹ́ni Ẹkúdayọ̀ ati àwọn iṣẹ́ orin classic láti orílẹ̀-èdè Europe, ó gba ìwé ẹ̀rí ọmọ ẹgbẹ́ Dípúlómà ti (FRCO) láti ilé-ẹ̀kọ́ Royal College of Organists. Lásìkọ̀ tí a ń wí yí, Ṣówándé ti dá ẹgbẹ́ akọrin tirẹ̀ sílẹ̀ tí wọ́n kọ orin Jazz ayi orin Highlife ìgbàlódé. Gbogbo ìrírí àti ìmọ̀ orin wọ̀nyí ni ó sọ ọ́ di lààmì-laaka nídí iṣẹ́ orin kíkọ nígbà ayé rẹ̀.

Ìgbẹ́ ayé rẹ̀ ní ìlú Lọ́ndọ̀n[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1934, Ṣówándé lọ sí ìlú London láti lọ kọ́ nípa European classical ati popular music. Lẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti dé Lọ́ndọ̀n, ó bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ orin "Solo" pẹ̀lú dùrù ní inú George Gershwin's àti Rhapsody in Blue. Ó tún ma ń ta meta pẹ̀lú Fats Waller, ba kan náà ni ó tún ma ń ta jìtá fún àwọn òṣèré orí ẹ̀rọ asọ̀rọ̀mágbèsì ti BBC. Ó tún jẹ́ ọ̀gá akọrin ní Kingsway Hall àti olùta Dùrù ní inú eré oníṣẹ Blackbirds.ní ọdún 1936. Ó gbé orin tí ó fi dùrù kọ jáde tí ó jẹ́ orin àwọn gbajú-gbajà olórin Adelaide Hall àti Vera Lynn jáde ní ọdún 1939. Lẹ́yìn èyí, ó tu lọ kọ́ nípa dùrù siwájú si lọwọ́ ọ̀gbẹ́ni Edmund Rubbra, George Oldroyd, àti George Cunningham ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Royal College of Organists ní ọdún 1943, nígbà tí ó gb3yẹ mọ́ Limpus, Harding àti Read Prizes lọ́wọ́.

Lẹ́yìn èyí, ó tún ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ amì-ẹ̀yẹ pẹ̀lú, ba kan náà ni ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ orin ní ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì ìlú London tí ó sì di ọ̀kan lara àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Trinity College of Music. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ orin fún Colonial Film Unit tí ó wà lábẹ́ ilé iṣẹ́ ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ òde ní United Kingdom lásìkò Ogun agbáyé ẹlẹ́kejì, nígbà tí ó kọ orin fún àwọn sinimá adánilẹ́kọ̀ọ́.

Ìròrí ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ati funfun ni ó ń fara hàn jùlọ ní ú orin Fẹlá, lara àwọn ìṣeẹ́ tí a ri lè ri èyí ni orin

  1. Yorùbá Lament,
  2. Obangiji,
  3. Kyrie,
  4. Gloria,
  5. Jesu Olugbala, ati
  6. Oba Aba Ke Pe.

Àwọn orin wọ̀nyí fi ìmọ̀sí-lára re hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti àti ọmọ ilé ìjọsìn Anglican Church hàn pẹ̀lú ìwọ́hùn orin pentatonic rẹ̀

Lara àwọn iṣẹ́ orchestral rẹ̀ ni:

  1. Six Sketches for Full Orchestra,
  2. A Folk Symphony, àti
  3. African Suite ìyẹn fún string orchestra.

[4] [5] Fẹlá tún ke orin tí ó pọ̀ ń iye nípa ọnà orin secular ,coral àti cappela. Ó Púpọ̀ nínú àwọn orin yí ni ó ṣe akọsílẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú BBC. Ó padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ He went back to Nigeria to scholarly work with the Nigerian Broadcasting Corporation kí ó tó dara pọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ àgbà Yunifásitì Ìbàdàn. Wọ́n yàn an fún amì-ẹ̀yẹ MBE ní ọdún 1955 láti fi sàmì ọjọ́ ìbí Ọbabìrin ti ilẹ̀ England fún iṣẹ́ ribiribi rẹ̀ tí ó ti gbé ṣe nílé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Nigerian Broadcasting Service.[6] Ó gbe ra lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Howard University ní ìlú Washington, D.C. ní ọdún 1968, kí ó tún tó lọ sí University of Pittsburgh.

Ìgbé ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ṣówándé ṣe iṣẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Kent State University ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ orin ilé-ẹ̀kọ́ náà, ó ń gbé ní Ravenna,Ohio pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Eleanor Mackinney ẹni tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ agbòhùn-sáfẹ́fẹ́ Pacific Radio. Ó kú sí ìlú Ravenna, wọ́n sì sin sí Randolph Township ní Ìpínlẹ̀ Ohio. Yàtọ̀ sí wípé Fẹlá jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́ inọ̀ orin, wọ́n fi oyè Bariyo da lọlá ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Wọ́n ṣe ìgbésẹ̀ bí wọn yóò ṣe ṣe da ilé ìwádí inọ̀ orin léte àti mú itẹ̀síwájú bá iṣẹ́ ribiribi tí ó fi sílẹ̀ẹ̀ sáyé, yálà wọ́n ṣì wà lórí igbá ni tàbí wọn kò sí mọ́.

Àwọn àṣàyàn orin tí ó ke sílẹ̀ ni[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí tó jẹ mọ́ Dùrù[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 1945 – Ká Múra, Chappell, London
  • 1952 – Pastourelle (for organ), Chappell, London
  • 1955 – Jésù Olùgbàlà, Chappell, London
  • 1955 – Joshua Fit de Battle of Jericho, Chappell, London
  • 1955 – Kyrie, Chappell, London
  • 1955 – Obangiji, Chappell, London
  • 1955 – Yorùbá Lament, Chappell, London
  • 1958 – Òyígíyigì, Ricordi, New York
  • 1958 – Gloria, Ricordi, New York
  • 1958 – 'Prayer, Ricordi, New York
  • 1959 – Responses in 'A’
  • KÕa Mo Rokoso
  • Ọba Àbá Ké Pè

Èyí tí ó jẹ mọ́ Choral[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • "The Wedding Day" for S.S.A. with piano, 1957, RDH
  • "Sometimes I Feel Like a Motherless Child" for S.A.T.B. a cappella, 1955, Chappell, London
  • "My Way's Cloudy" for S.A.T.B. with piano, 1955, Chappell, London
  • "De Ol' Ark's a-Moverin" for S.A.T.B.B. a cappella with tenor solo, 1955, Chappell, London
  • "Same Train" for S.A.T.B.B. a cappella, 1955, Chappell, London
  • "Roll de Ol' Chariot" for S.A.T.B.B. with piano and rhythm combo, 1955, Chappell, London
  • "All I d"o for S.A.T.B.B. with piano and rhythm combo, 1961, Ricordi, New York
  • "Goin' to Set Down" for S.A.T.B. a cappella with soprano solo, 1961, Ricordi, New York
  • "Couldn't Hear Nobody Pray" for S.A.T.B. a cappella with soprano solo, 1958, Ricordi, New York
  • "De Angels Are Watchin'" for S.A.T.B. a cappella with soprano and tenor solo, 1958, Ricordi, New York
  • "Nobody Knows de Trouble I See" for S.A.TB. a cappella, 1958, Ricordi, New York
  • "Wheel, Oh Wheel" for S.A.T.B. a cappella, 1961, Ricordi, New York
  • "Wid a Sword in Ma Hand" for S.A.T.B.B. a cappella, 1958, Ricordi, New York
  • "Sit Down Servant" for T.T.B.B. a cappella and tenor solo, 1961, Ricordi, New York
  • "Out of Zion" for S.A.T.B. with organ, 1955
  • "St. Jude's Response" for S.A.T.B. with organ
  • "Oh Render Thanks" (hymn-anthem) for S.A.T.B. with organ, 1960
  • Nigerian National Anthem (an arrangement) for S.A.T.B. with organ, 1960

Àwọn orin Solo rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Three Songs of Contemplation for tenor and piano, 1950, Chappell, London
  • Because of You for voice and piano, 1950, Chappell, London
  • Three Yoruba Songs for voice and piano, 1954, Ibadan

Àwọn orin Orchestral rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Four Sketches for full orchestra, 1953
  • African Suite for string orchestra, 1955, Chappell, London
  • Folk Symphony for full orchestra, 1960

Àwọn àṣàyàn iwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • (1964). Ifa: Guide, Counsellor, and Friend of Our Forefathers. Ibadan.
  • (1966). The Mind of a Nation: The Yoruba Child. Ibadan: Ibadan University.
  • (1968). Come Now Nigeria, Part 1: Nationalism and essays on relevant subjects. Ibadan: Sketch Pub. Co.; sole distributors: Nigerian Book Suppliers. (All the material presented in this book first appeared in the form of articles in the pages of the Daily Sketch, Ibadan.)
  • (1975). The Africanization of Black Studies. Kent, Ohio: Kent State University Institute for African American Affairs. African American Affairs Monograph Series, v. 2, no. 1.

Àwọn àpilẹ̀kọ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • (1971). "Black Folklore", Black Lines: A Journal of Black Studies (special issue: Black Folklore), v. 2, no. 1 (Fall 1971), pp. 5–21.

Àwọn Itọ́kas sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. De Lerma, Dominique-Rene. "African Heritage Symphonic Series". Liner note essay. Cedille Records CDR055.
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 17 December 2011. Retrieved 18 February 2021. 
  3. Godwin Simeon Sadoh (May 2004). THE ORGAN WORKS OF FELA SOWANDE: A NIGERIAN ORGANIST-COMPOSER. p. 29. 
  4. "Fela Sowande (1905-1987)", African Heritage in Classical Music.
  5. "Fela Sowande", PhilPaine.org, 10 September 2006.
  6. "Page 3283 | Supplement 40497, 3 June 1955 | London Gazette | The Gazette". Retrieved 20 February 2020. 

Ẹ tún lè ka àwọn iwe bíi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Authority control