Iyọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Iyọ̀

Iyọ̀ jẹ alumoni afaralokun tó jẹ́ àkópò sodiomu oniklorini tó ṣé pàtàkì fún ìgbádún eranko, ṣùgbọ́n tí ó le léwu nígbà míràn fún òpò àwọn ogbin orile. Iyọ̀ wà lára àwọn nkan tí wón ń fi sí oúnjẹ kí ó le dùn, èyí mú kí iyọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ǹkan tí àwọn ènìyàn ń lò jù láti mú kí oúnjẹ dùn. Idayobo ni ọ̀nà tí a ń lò láti fi onje pamo.

Iyọ̀ ti ènìyàn ń jẹ le wá láti oríṣiríṣi ọ̀nà: iyọ̀ àìmó (bi iyo okun), iyọ̀ mímọ (iyo onje), ati iyo oniayodini. A lè rí iyọ̀ láti inú omi okun tàbí àwọn òkúta ilẹ̀.

Àwọn ioni inú iyọ̀ bi Klorínì ati sodiomu, se pàtàkì fún ìwàláàyè gbogbo ohun ẹ̀dá alààyè. Iyọ̀ ń kópa nínú àmójútó omi inú ara, bí ó tilè jẹ́ wípé jíjẹ iyọ̀ jù le fa àìlera fún ara, ó le fa Ẹ̀jẹ̀ ríru[1].


Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Blood Pressure UK". Blood Pressure UK. Retrieved 2023-02-02.