Johnson Aguiyi-Ironsi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ogagun-Agba Johnson Aguiyi-Ironsi
2ji Aare ile Naijiria (ekeji)
In office
January 16, 1966 – July 29, 1966
AsíwájúNnamdi Azikiwe
Arọ́pòYakubu Gowon
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1924-03-03)Oṣù Kẹta 3, 1924
Umuahia, Abia State, Nigeria
AláìsíJuly 29, 1966(1966-07-29) (ọmọ ọdún 42)
Lalupon, Nigeria
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúkòsí (iṣẹ́ ológun)

Johnson Thomas Umunnakwe Aguiyi-Ironsi (Ọjọ́ 3,oṣù Ẹ̀rẹ̀nà, ọdún 1924 - ọjọ́ 29, oṣù Agẹmọ, ọdún 1966) jẹ́ ológun ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn tí ológun gba ìjọba ní ọjọ́15, Oṣù Ṣẹrẹ, ọdún1966, Aguiyi-Ironsi di Olórí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà títí di ọjọ́ 29, oṣù Agẹmọ, ọdún1966 nígbà tí wọ́n dìtẹ̀ sí ìjọba rẹ̀ tí wọ́n sì pa á..[1][2]

Ìgbà èwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí i ní ìlú Umuahia tó wà ní Ìpínlẹ̀ Abia lónìí ní ọjọ́ kẹ́ta, osù kẹ́ta ọdún 1924 fún Mazi àti Ezugo Aguiyi. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́jọ̀, Aguiyi-Ironsi kó lo sí ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin Anyamma ẹni tó jẹ́ aya Theophilius Johnson to jẹ́ òṣìṣẹ́ asojú ìjọba fún ilẹ̀ Sierra Leone ní Umuahia. Nígbà tó tó ọmọ ọdún méjìdínlógún Ironsi bọ́ sí iṣẹ́ ológun Nàìjíríà botilejepe egbon re lodi si.[3][4]

Iṣẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ ológùn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1942, Aguiyi-Ironsi dara pọ̀ mọ àwọn ológun gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ogun onípò méje[5] Ó gbà ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1946 sí ipò méjọ̀ ságéńtì. Bẹè náà ni wọ́n rán Aguiyi-Ironsi lọ sí ilé-ìwé Staff College, Camberley, England ní ọdún 1946. Lẹ́yìn tí ó parí ìwé rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun kejì ní Royal West African Frontier Force, ní ọjọ́ kejìlá, oṣù Ogúdù, ọdún1949.[6]

Aguiyi-Ironsi gba àṣẹ ìgbìmọ̀ ní ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Èbìbí, ọdún 1953.[7] Aguiyi-Ironsi jẹ́ ọ̀kan lára ọmọ-ogun tí ó sin Ọbabìnrin Elizabrth II tí United Kingdom àti ìgbà tí ó wà ní ilẹ̀ Nàìjíríà ní ọdún 1956.[8]

Ní1960, Aguiyi-Ironsi di ọ̀gá fún àwọn ọmọ-ogun onípò karùn-ún ní ìlú Kano, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pẹ̀lú ìpò ọgáju. Nínú ọdún 1960 náà ni Aguiyi di adarí àwọn ọmọ-ogun àpájàwìrì ti ìlú United Nations Operation in the Congo.

NÍ oṣù Ṣẹrẹ, ọdún 1966, ọ̀gágu Chukwuma Nzeogwu, darí àwọn ọmọ-ogun láti gba agbára lọ́wọ́ àrin-gbùngbùn àti ìjọba agbègbè orilè-èdè Nàìjíríà, wọ́n pa olórí ìjọba, wọ́n sì gbìyàjuh láti gbà ìjọba ṣùgbón wọ́n kùnà nínú ọ̀tẹ̀ wọ́n. Ọ̀gágun Aguiyi-Ironsi ṣégun Nzeogwu, ó sìn tì í sẹ́wọ̀n.

Ọjọ́ mẹ́tàdínlógún, oṣù Ṣẹrẹ, ọdún 1966, Aguiyi-Ironsi dí olórí orílẹ̀-èdè. Ó sì di ipò yìí mú títí di ọjọ́ kankàndílọ́gbọ̀n, oṣù Ṣẹrẹ, ọdùn 1966, nígbà tí àwọn ológùn Àríwá gbógùn ti ìjọba rẹ̀ tí wọ́n sì pa Aguiyi-Ironsi.[9]

Àwọn ítokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Congress, The Library of. "LC Linked Data Service: Authorities and Vocabularies (Library of Congress)". id.loc.gov. Retrieved 2020-05-26. 
  2. "Aguiyi-ironsi". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-07-30. Retrieved 2022-02-28. 
  3. Obialo, Maduawuchi (2020-03-27). "Major General JTU Aguiyi-Ironsi Biography". Nigerian Infopedia (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-10-20. Retrieved 2021-01-28. 
  4. "nigeria johnson thomas umunnakwe aguiyi ironsi biography and profile". [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  5. "The rise and fall of Major general Johnson Aguiyi Ironsi: He was a brilliant soldier and a dictator - Opera News Official". news-af.feednews.com. Retrieved 2020-07-09. 
  6. You must specify issue= and startpage= when using {{London Gazette}}. Available parameters: Àdàkọ:London Gazette/doc/parameterlist

    , 5 August 1949.
  7. You must specify issue= and startpage= when using {{London Gazette}}. Available parameters: Àdàkọ:London Gazette/doc/parameterlist

    , 13 April 1954.
  8. You must specify issue= and startpage= when using {{London Gazette}}. Available parameters: Àdàkọ:London Gazette/doc/parameterlist

    , 12 December 1958.
  9. Obotetukudo, Solomon (2011). The Inaugural Addresses and Ascension Speeches of Nigerian Elected and Non elected presidents and prime minister from 1960 -2010. University Press of America. pp. 56–57.