Krumen

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Orílẹ̀-èdè Cote d’Ivoire àti Liberia ni a ti lè rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Ó tó ènìyàn bíi mílíọ̀nù kan sí méjì tí wọ́n ń sọ èdè yìí. Tí a bá wo àtẹ ìsàlẹ̀ yìí, a ó ṣe alábápàdé àwọn èdè bíi Kuwaa, Tiegba, Seme àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lára orí èdè ‘Kru’.

Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Kru’ tí ó pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta. Àwọn ìsọ̀rí náà nìwọ̀n yìí

(a) Ìlà-oòrùn - Godie àti Kouya, Dida, Kwadia, Bakwe ati Wane.

(b) Ìwọ̀-oòrùn - Grebo complex, Guere complex, Bassa, Klao

(d) Ìsọ̀rí kẹ́ta ni àwọn bíi Kuwaa, Tiegba, Abrako, Seme.