Majek Fashek

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Majek Folabee Shamsudeen
Orúkọ àbísọMajekodunmi Fasheke
Ọjọ́ìbíFebruary 1949
Benin Edo State, Nigeria
Irú orinReggae, roots reggae, rock
Occupation(s)singer, songwriter, actor
Years activeearly 90s—present
LabelsInterscope Records
Associated actsJastix
Monicazation

Majekodunmi Fasheke, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Majek Fashek jẹ́ olùkọ orin, atajìtá àti olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó di ìlú-mọ̀ọ́ká olòlórin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àsìkò ọdún 1988, fún àwo orin rẹ̀ tí ó gbé jáde lásìkò yí tí ó pè ní _Onígbèkùn ọkàn (Prisoner of Conscience), àti àwọn orín rẹ̀ ọlọ́kan ò jọ̀kan bíi : Send down the rain àti bẹ̀è bẹ̀è lọ tí ó gha àwọn àmì ẹ̀yẹ òmìdáni lọ́lá oríṣríṣi. [3] Ẹ̀wẹ̀, Majek ti ṣeré pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré olórin oríṣríṣi ìlú mọ̀ọ́ká bíi: Tracy Chapman, Jimmy Cliff, Michael Jackson, Snoop Dogg, àti Beyoncé.[4][5]

Ìbẹ̀rẹ̀ Ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Fashek ní ìlú Benin tí ó jẹ́ olú ìlú fún to an Ìpínlẹ̀ Edo níbi tí ìyá rẹ̀ ti wá, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ìlú Ìjẹ̀ṣà.[1][2] Fashek yan ìlú Benin láàyò lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí bàbá àti ìyá rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀, tí ó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ Aládùúrà kan, níbintí ó kọ́ bí wọ́n ṣebń lu ìlú àti àwọn ohun èlò orin mìíràn, tí ó sì ń hun orin fún àwọn akọrin ìjọ náà.[6]

Iṣẹ́ orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nípa torin, a lè sọ wípé Majek ni àrólé fún olóògbé Bob Marley, nítorí gbogbo ìwọ́hùn olóògbé náà ni Fashek mú pátá.[7][8] Ó wà lára ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ [Nàìjíríà]] tí gbé orin Reggae tí ó ti ilẹ̀ Caribbean wá. Àmọ́, kàkà kí Majek ó gbàgbé ilé àti orin ìbílẹ̀ wa pátá, ń ṣe ló mú ọnà orin bíi Fújì àti Jùjú mọ́ orin reggae tí ó sì tibẹ̀ fa ọnà orin tirẹ̀ tí ó pè ní ''Kpangolo'' yọ lọ́nà arà.[9][10]

Ikú rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Majek kú sí ojú orun rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù Kẹfà ọdún 2020 sí ìlú New York.

Àwọn Ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 Harris, Craig. [[[:Àdàkọ:Allmusic]] "Biography – Majek Fashek"] Check |url= value (help). AllMusic. Retrieved 1 October 2010. 
  2. 2.0 2.1 Faosheke, John Olu (11 February 2007). "Majek Fashek's Ijeshaedo Roots Revealed". AllAfrica.com (AllAfrica Global Media). http://allafrica.com/stories/200702120313.html. Retrieved 1 October 2010. 
  3. "Nigeria: Rainmaker, Majek Fashek Re-Ignites Hope for a Comeback". allAfrica.com. 
  4. 40 Minutes with the Rainmaker Archived 1 October 2015 at the Wayback Machine.
  5. "Rainmaker, Majek Fashek Re-ignites Hope for a Comeback". Nigerian News from Leadership News. 
  6. "Majek Fashek Tragedy: The Inside Story No One Told You #SavingMajek". Entertainment Express. 18 April 2015. 
  7. Loder, Kurt. Rolling Stone. "Fashek's vocal and lyrical resemblance to the late Bob Marley is both eerie and earned...."
  8. Farber, Jim. Daily News|location=New York, 19 January 1992. "Ziggy may be Bob Marley's biological son, but Majek Fashek is his spiritual heir. In terms of vocal tone, Fashek is Marley's spitting image...."
  9. Pareles, Jon. The New York Times, 5 December 1990. "...a promising hybrid style, one that started in standard reggae but has added the bustling cross-rhythms of Nigerian juju and a touch of hard rock."
  10. "Joseph Edgar: Majek Fashek, a national tragedy". DailyPost Nigeria. 12 June 2015.