Oduduwa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Odùduwà jẹ́ aláṣẹ àti olùdarí ìran Yorùbá, òun tún ni gbòngbò kan pàtàkì tí ó so ilẹ̀ Yorùbá ró láti Ife,[1][2] títí dé ibi k'íbi tí wọ́n bá ti ń jẹ Ọba káàkàkiri ilẹ̀ Káàrọ̀ -oò -jíire pátá.[3] Lára ìtàn tó fẹsẹ̀ Odùduwà múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọni ìgbà ìwáṣẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá sọ wípé ó jẹ́ ọmọ ọba ti ilẹ̀ Lárúbáwá tí wọ́n f'ogun lé kúrò nílùú baba rẹ̀ nílẹ̀ Mẹ́kà[4] tí ó wá di Saudi Arabia lónìí. Látàrí ogun yìí ló jẹ́ kí ó gbéra ọ́un àti àwón ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ̀n sì fi tẹ̀dó sí ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà títí di òní. Títẹ̀dó rẹ̀ náà kìí ṣe pẹ̀lú ìrọ̀wọ́-rọsẹ̀, bí kọ́ ṣe ogun tó gbóná janjan fún bí ọdún púpọ̀ kí ó tó borí àwọn ẹ̀yà mẹ́tàlá kan tí ó bá ní Ifẹ̀ tí Ọbàtálá jẹ̀ adarí fún, tí ó sì sọ ìlú náà di Ìlú kan ṣoṣo tí ó sì wà ní abẹ́ ìṣàkóso Ọba kan ṣoṣo.[5][6]

Ó gba àwọn ìnagijẹ bí : Ọlòfin Àdìmúlà, Ọlòfin Ayé àti Olúfẹ̀.[7] Àwọn elédè Yorùbá ma ń pe Orúkọ rẹ̀ báwọ̀nyí: Odùduwà , tì wọ́n sì tún le dàá pè báyìí:" Oòdua" tàbì "Oòduwà" tàbí "Odùduà" nígbà míràn ni ó ń tọ́ka sí akọni náà, tí ó sì ń fi pàtàkì àwọn ilẹ̀ Yorùbá hàn pàápàà jùlọ àwọn Ọba Aládé gẹ́gẹ́ bí àrólé, àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni iyì àti àpọnlé.[8][9]

A Statue of Oduduwa
Oduduwa

Ohun tì Odùduwà túmọ̀ sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Odùduwà túmọ̀ sí agbára inú tí ó ń jẹ́ kí ènìyàn ṣẹ̀mí tàbí sọni dalààyè
  • Odùduwà dúró fún agbára tó dá dúró, tí ó lè ṣàyípadà tàbí kí ó tún ǹkan ṣe sí bí ó bàá ṣe wùú làsìkòbtó bá dẹ..
  • Odùduwà - Odù- dá- ìwà, tàbí Odù tó dá ìwà. Túmọ̀ sí ohun kan tí ó dá ohun tó ṣeé fojú rí.

Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Odùduwà ó kúrò láyé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbrẹ̀ ni wọ́n tinfún ká orílẹ̀ kúrò ní Ifẹ̀, tí wọ́n sìbti lààmì -laaka kákiri ìletò tiiwọn nàà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni wọ́n ti dá ìjọba tiwón náà kalẹ̀ nílú tí àwọn náàbtẹ̀dó sí gẹ́gẹ bí Ọba, tí wọ́n sì ń fi yé àwọn ọmọ tiwọn náà wípé Ile-Ife ni àwọn ti wá

Ọ́rúntó tí ó jẹ́ ọmọ tí ọ̀kan lára àwọn èrú Odùduwà bí fun ni ó jẹ́ ìyá-ńlá àwọn tí wọ́n ń joyè Ọbalúfẹ̀ tí ó jẹ́ oyè igbá-kejì sí oyè Ọọ̀ni ní Ilé-Ifẹ̀ títí dòní

Ọbalùfọ̀n Aláyémore ni ó wà ní orí ìrẹ́ nígbà tí Ọ̀rànmíyàn ti ìrìn-àjò dé, tí ó sì pàṣẹ pé kí Ọbalùfọ̀n ó kúrò lórí àpèrè kí òhn sì bọ́ síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ọmọ Odùduwà tí ó lẹ̀tọ̀ọ́ sóróyè baba rẹ̀. Lẹ́yìn Làjàmìsà tí ó jé ọmọ Ọ̀rànmíyàn bi ó ni àwọn ọmọ rẹ̀ ń jẹ Ọọ̀ni nílé-Ifẹ̀ títí dòní.

Lápá kan, wọ́n ní ìtàn fiyeni wípé Odùduwà jẹ́ oníṣẹ́ láti ìlú Òkè-Ọrà ìlú tí ó wà ní apá ìlà -Oòrùn é-Ifẹ̀. Wọ́n ní ó rọ̀ láti orí òkè kan pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n, ní èyí tó mú kí wọ́n ma kìí wípé: "Oòduà Ayẹ̀wọ̀nrọ̀" tí ó túmọ̀ sí ( 'one who descends on a chain'). Abala ìtàn yí fi yéwa wípé jagun jagun ni Odùduwà jẹ́ pẹ̀lú bí ó ṣe wọ̀ éwù ogun onírin .Lásìkò tí ó wọ Ilé-Ifẹ̀ wá, àjọṣepọ̀ tó lọ́ọ̀rìn wà láàrín àwọn olùgbé ìran mẹ́tàlá(13) Ifẹ̀, tí ìlú kọọ̀kan sì ní Ọba tirẹ̀ bí Ọba Ìjùgbé, Ìwínrín, Ijió, Ìwínrín àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lẹ́yìn tí Odùduwà di aláṣẹ́ Ilé-Ifẹ̀ tán, òun àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ sapá tí wọ́n sì gba àwọn ìlú àti agbègbè mẹ́tàlá tí a mẹ́nu bà wọ̀nyí, tí wọ́n sì ṣí Obatala, nípò gẹ́gẹ́ bí olórí tí wọ́n sì gbé ìjọba titun kalẹ̀ pẹ̀lú ẹtò ìṣèlú tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Látàrí ìdí èyí, ni wọ́n fi ń pèé ní Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó mú ètò àti ìlànà ìṣèjọba aládé wọ ilẹ̀Yorùbá

Ìran Òwu gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkọ́bí Odùduwà tí orúkọ rẹ́ ń jẹ́ Ọ̀kànbí Iyùnadé, ni ó fẹ́ Obatala tí ó sì bí ẹbi tí ó jẹ Olówu àkọ́kọ́. Ìtàn fiblélẹ̀ wìpé Olówu àkọ́kọ́ yìí ni ó ti gorí ìtẹ́ látìgbà tí ó ti wàní òpóǹló.

Ìran Alákétu gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀kan lára àwọn ìyàwó Odùduwà tí ó jẹ́ ààyò tí orúkọ rẹ̀ ǹ jẹ́ Ọmọnidẹ, ni ó bí Sopasan, ẹni tí ó bí ọba Alákétu Sopasan was the first to leave Ile-Ife with his mother and crown. He settled at such temporary sites as Oke-Oyan and Aro. At Aro, Soposan died and was succeeded by Owe. The migrants stayed for a number of generations and broke camp in the reign of the seventh king, Ede, who revived the westward migrations and founded a dynasty at Ketu.

Oduduwa and the line of Òràngún[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ajagunlà Fágbàmílà Ọ̀ràngún, tí a lè pè ní ojúlówó ọmó Odùduwà ni ó jẹ́ Ọ̀ràngún ilé Ilé-Ìlála. Odùduwà ni a gbọ́ wípé ó fẹ́ láti bí ọmọ yanturu kí ó lè dẹ́kun àhesọ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ifa oracle, he went to a stream, where he found a naked lady by the name of Adetinrin Anasin. She eventually became his wife and the mother of Ifagbamila (which means "Ifa saves me")

Onísàbẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Àwọn àrọ́mọdọ́mọ Onísàbẹ ni ó ń jẹ Ọba Inísàbẹ títí dòní.

Onípópó gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Àbíkẹ́ta ọmọ Onípópó ni wọ́n jỌba Pópó dòní

Ìran Aláàfin ẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rànmíyàn ni ó tẹ ìlú Ọyọ́-Ilé dó. Lẹ́yìn tí lára àwọn ọmọ rẹ̀ Àjàká àti Ṣàngó náà darí ìjọba Ọ̀yọ́ lẹ́yìn baba wọn.

Ọ̀rànmíyàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rànmíyàn tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn àwọn ọmọ Odùduwà ni onírìn-àjò jùlọ láàrí àwọn ọmọ bàbá rẹ̀ jùlọ. Òni ẹni àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ jẹ He was the first Ọba ilẹ̀ Ìbìní tí ó sì tún jẹ́ ỌbaAláàfin ti Ìlú Ọ̀yọ́, bákan náàni òun ni Ọba Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ ẹlẹ́kefà nínú ètò.

Mọ́remì àti àwọn Ùgbò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn tí àwọmọ Odùduwà gbogbo ti túká kúrò ní Ifẹ̀ láti lọ dá ìlú àti ìletò tiwọ̀n sílẹ̀, ó ṣòro láti tukọ̀ ìlú náà fún olórí tó wà níbẹ̀ nígbà náà, fúndìí èyí, àwọn ìpèníjà oríṣiríṣi ni ó dojú kọ Ilé-Ifẹ̀ lásìkò yí. Àwọn ẹmẹ̀wà Ọbàtálá tí ó jẹ́ ẹni tó ti darí Ifẹ̀ ṣáájú Odùduwà ni a gbọ́ wíoé wọ́n sọra wọn di agbọ́n onígàn oró tí wọ́n sì ń gbẹẹ̀mí àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́, léte àti gbẹ̀san gbígba agbára tí Odùduwà gba agbára lọ́wọ́ Obàtálá. Wọn yóò múra gẹ́gẹ́ bí Th àlùjọ̀nú nígbà tí wọn yóò wọ àwọn kiníkan tó dàbí ewé, lọ́nà tí hóò dẹ́rù ba àwọn ènìyàn gidigidi, wọn yóò ma dáná sunlé tí wọn yóò ja àwọn ọlọ́jà lólẹ láàrín ọjà. Lásìkò yí ni ọmọba bìnrin Mọ́remí Ajasoro, tí ó jẹ́ ọmọba bìnrin ní ìlú Ọ̀fà, tì ó wá láti ìran Ọlálọmí Ọlọ́fà gangan, tí ó jẹ́ ẹni tì ó tẹ Ìlú Ọ̀fà dó tí ó sìbtún jẹ́ adarí pàtàkì fún Ìbọ̀lọ́ ní ìlú Ọ̀yọ́, tí ó sì tún jẹ́ ìbátan Ọ̀rànmíyàn ni a gbọ́ wílé ó dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó sì sapá gidi láti pẹ̀tù sí wàhálà náà níoa ṣíṣe alamí àwọn níṣẹ́ búburú náà. Ó fara rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ̀ kí wọ́n fipá kó ọòun lẹ́rú. Nínú ìgbèkùn ẹrú rẹ̀ ni Ọba àwọn Ùgbò náà ti fẹ láti fi ṣaya. Ọba náà gbìyànjú láti ba múfẹ̀ẹ́ lẹyìn tí ó fẹ ytan ṣùgbọ́n Mọ́remí kọ̀ jálẹ̀ ní torí ó ti ládé orí tẹ́lẹ̀, àti wípé iṣẹ́ alamí ló wá ṣe kìí ṣe ọ̀rọ̀ ìfẹ́ ló kàn. Ó ní bí Ọba náà bá le dọ ìdí abájọ àwọn amòòkùn-sìkà náà fún òun, kíá ni òun yóò gbà fun lát lájọṣepọ̀. Ọba náà kọọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ẹyí, ṣùgbọ́n ó ṣe ìfẹ́ inú Mọ́remi tí ó sì tú àṣírí náà si lọ́wọ́. Ó sọ fún Mọ́remí wí wípé ohun tí àwọn kórìíra jùlọ nígbà tí àwọn bá ti múra bí àlùjọ̀nnú náà bi iná, nítorí iná nìkan ló lè tú wọ́n láṣìírì, bí wọ́n bá sì ríná, àwọn yóọò sá lọ. Lẹ́yìn tí Mọ́remí ti gnọ́ àṣírí yìí tán ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ń dọ́gbọ́n ọ̀nà tí yóò gbà sákúrò níbẹ̀. OnÓ ní kí wọ́n bá òun wá ọsàn tó pọ́ tí ó sì fi ṣe oògùn orun fún gbogbo àwọn olùgbé Ààfin náà. Lẹ́yìn tí wọ́n jí ni wọ́n ri wípé Mọ́eemí ti na pápà bora tí ó sì ti lọ tú àṣírí àwọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀,. Báyìí ni àwọn Ifẹ̀ ṣe múra sílẹ̀ fún àÙgbọ́ lá ti bá wọn bami ìjà wò. Tí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn.[10]

Àwọn àríwòye mìíràn nípa Ofùduwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ipa tí Odùduwà kó nínú ìṣẹ̀dáyé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọb ìtàn ìbílẹ̀ kam di múlẹ̀ wípé Odùduqà jẹ́ ọkan lára àwọn Orisa tí Elédùmarè dẹẹ́ràn jùlọ nígbà ìwáṣẹ̀. Àwọn ìtàn wọ̀yí fi múlẹ̀ wípé Odùduwà ni Elédùmarè rán wá sáyé láti wádá ayé sorí ẹ̀kún omi. Iṣẹ yìí ni a gbọ́ wípé Ọbàtálá kùnà láti jẹ́ lẹ́ni tí a ti fún ní ìkarahun ìgbín, iyẹ̀pẹ̀, àti igi tíyóò fi tàn án ká fún iṣẹ́ pàtàkì náà. Ìtàn yí ni àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ Yorùbá gbàgbọ́ tí wọ́n sì fi ṣe ọ̀pákútẹ̀lẹ̀ ì)àgbọ́ wọn nípa ìṣẹ̀dá ayé. Wọ́n ma ń fi igbá àti ṣe àmì Ọbàtálá àti Odùduwà nígbà tí ọnọrí igbá ń rọ́pò Ọbàtálá tí ìyá igbá sì ń dúró fún Odùduwà gẹ́gẹ́ bíese Ọlọ́fin Ọ̀yẹ́tẹ tí ó túmọ̀ sí ẹni tí gba igbá ìyè lọ̀dọ̀ Elédùmarè.

Ẹ tún le wo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Àtòjọ àwọn Ọba alayé Ilé-Ifẹ̀
  • Àwọn akọn ìgbà ìwáṣẹ̀ tilẹ̀ Adúláwọ̀

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Empty citation (help) 
  2. Empty citation (help) 
  3. Empty citation (help) 
  4. a short history of WEST AFRICA A. D 1000-1800. 
  5. Empty citation (help) 
  6. Empty citation (help) 
  7. Empty citation (help) 
  8. Obayemi, A., "The Yoruba and Edo-speaking Peoples and their Neighbors before 1600 AD", in J. F. A. Ajayi & M. Crowder (eds), History of West Africa, vol. I (1976), 255–322.
  9. Empty citation (help) 
  10. Yoruba Alliance: Error in webarchive template: Check |url= value. Empty.Who are the Yoruba!

Wo eleyi na[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fún ìkàsíwájú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ojuade, J. S., "The issue of 'Oduduwa' in Yoruba genesis: the myths and realities", Transafrican Journal of History, 21 (1992), 139–158.