Onyeka Onwenu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Onyeka Onwenu
Onyeka Onwenu
Onyeka Onwenu's Presentation At The 50 Years After The Biafran War Summit
Ọjọ́ìbíOnyeka Onwenu
Ọjọ́kẹtàdínlógún Oṣù karún Ọdún 1961
Onitsha
Iṣẹ́Olórin, Òṣèré, àti olóṣèlú

Onyeka Onwenu (ọjọ́ìbí ọjọ́ mọ́kànlélógbọ̀n oṣù kìíní ọdún 1952[1]) jẹ́ oniroyin, olórin, òṣèré a jíjà gbàrà ati òṣèlú ni Nàìjíríà. Ó wá láàrin àwọn tí ó má ń dá jọ fún ètò X Factor tẹ́lẹ̀.[2] Òun ni alága tẹ́lẹ̀ fún àṣà àti ìṣe fún ìpínlè Imo.[3][4][5] Òun ni adarí àti olórí Aláṣẹ fún ìdàgbàsókè àwọn obìnrin ní orílè èdè.[6]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onyeka jẹ ọmọ ìdílé Arodizuogu ni ìlú Ideato North ni ìpínlè Imo. Òun ni ọmọbìnrin àbíkẹ́yìn fún àwọn òbí rẹ. Bàbá rẹ̀, D. K Onwenu tí ó jẹ́ òṣèlú kú ní ìgbà tí Onyeka wá ní ọdún mẹ́rin sì inu ìjàmbá ọkọ̀.[7][8] [9][10] .Onwenu gboyè nínú International Relations and Communication láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Wellesley College, ó sì gba masters ni The New School for Social Reasearch ni New York.[11]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1984, Onyeka ṣe ère ìwé ìtàn A Squandering of Riches tí ó ṣọ̀rọ̀ nípa ìwà ibajẹ àti nípa bíi àwọn Niger Delta ṣe ń sọ fún àwọn ìjọba pé kí wọn dẹkùn tí wọn ṣe bá ìlú wọn jẹ́ pelu ìdọ̀tí tí ó ń jáde lára èpò rọ̀bì.[12] Ó ṣe atọkun fún ètò "Contact" ni ọdún 1988 àti "Who's On" ni 1993 lórí NTA.

Ó bẹ́ẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ní ọdún 1981, o kọ orin For the love of you àti Endless life.[13] [14] Òun àti gbajúmọ̀ olórin Sunny Ade jọ kọrin Madawolohun, Choices àti Wait for me.[15] Ó kọ orin Polygon tí ó sì fi yẹ Nelson Mandela sì nígbà tí ó wá sí Nàìjíríà ni 1990 lẹ́yìn tí ó kúrò ní ẹ̀wọ̀n.[16] Ní ọdún 2013, ó wá láàrin àwọn mẹta tí ó ṣe adájọ́ lóri ètò X Factor ni Nigeria.[17] Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ People Democratic Party.[18] Ó ti du ipò alága ìbílẹ̀ ni Ideato North ni ìpínlè Imo ni ẹ méjì ṣùgbọ́n pàbó ló jà sì.[19] Gómìnà tẹ́lẹ̀, Ikedi Ohakim fi ṣe alága fún àṣà àti ìṣe fún ìpínlè Imo. Ní ọjọ́ kẹrin di lógún, oṣù kẹsàn-án ọdún 2013, Olórí orile-ede Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan fi ṣe adarí àti olórí Aláṣẹ fún ìdàgbàsókè àwọn obìnrin ní orílè èdè. Ní ọdún 2000, òun ati NTA jọ ní àríyànjiyàn lórí pé wọn lọ orin rẹ láì sọ fún.[20][21] Eré tí Onwenu má kọ́kọ́ farahàn ni Nightmare.[22] Ó ti kópa nínú àwọn eré bíi bíi Women's Cot, Half of a Yellow Sun àti Lion Heart.[23]

Aiyé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onyeka tí bí ọmọ méjì.[24][25][26]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Makams, Ahman (20 October 2012). "Onyenka Onwenu: Queen Of African Pop Music". Leadership. Archived from the original on 2013-09-25. https://web.archive.org/web/20130925231923/http://leadership.ng/nga/articles/38037/2012/10/20/onyenka_onwenu_queen_african_pop_music.html. Retrieved 21 October 2012. 
  2. "Onyeka Onwenu, Toolz, MI excited about Glo X factor". Archived from the original on 12 April 2014. Retrieved 31 March 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Charles O'tudor Fetes Onyeka Onwenu". AllAfrica Global Media. http://allafrica.com/stories/200811031100.html. Retrieved 13 August 2010. 
  4. Nwangwu, Onyinyechi. "NCAC Honours Onwenu, Samanja, Others". AllAfrica Global Media. http://allafrica.com/stories/200912240727.html. Retrieved 13 August 2010. 
  5. "Charles O'tudor Fetes Onyeka Onwenu". AllAfrica. 1 November 2008. http://allafrica.com/stories/200811031100.html. 
  6. "Onwenu bags FG appointment". The Nation Newspapers. 21 September 2013. Retrieved 21 September 2013. 
  7. Amadi, Ogbonna (2 March 2012). "Onyeka speaks at 60". Vanguardngr.com (Vanguard Media). http://www.vanguardngr.com/2012/03/onyeka-speaks-at-60/. Retrieved 4 April 2014. 
  8. "Am I married to the father of my kids? No comment ––––Onyeka Onw". Ghanaian Agenda. Retrieved 4 April 2014. 
  9. Adetayo, Ayoola. "Onyeka Onwenu: 10 things about the legendary musician you need to know" (in en-US). http://www.pulse.ng/entertainment/celebrities/onyeka-onwenu-10-things-about-the-legendary-musician-you-need-to-know-id4844862.html. 
  10. Plight of Widows
  11. "Onyeka Onwenu’s Biography". AFROBIOS. Archived from the original on 22 November 2022. Retrieved 21 August 2014. 
  12. "Nigeria, A Squandering of Riches". BBC/NTA. 1984. Retrieved 21 September 2013. 
  13. [label.https://www.discogs.com/Onyeka-Onwenu-For-The-Love-Of-You/release/5335012 For the Love of You}
  14. Endless Life
  15. MUSIC-NIGERIA: There’s A Message in the Sound
  16. Why I Wrote Winnie Mandela
  17. Onyeka Onwenu, M.I, Reggie Rockstone unveiled as X Factor judges
  18. Onyeka Onwenu gets political appointment
  19. [1]
  20. Nigerian singer on hunger strike
  21. Nigerian singer's hunger strike over
  22. Nightmare
  23. "AMAA 2006 – List of Winners". African Movie Academy Awards. Archived from the original on 12 February 2008. Retrieved 15 October 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  24. https://www.legit.ng/1166292-onyeka-onwenu-husband-children.html
  25. https://www.informationng.com/2015/11/photos-meet-the-son-of-legendary-singer-onyeka-onwenu.html
  26. https://theirworld.org/news/my-inspirational-teacher-by-nigerian-singer-and-actor-onyeka-onwenu

[Ẹ̀ka:Àwọn ọmọ Yorùbá]]