Orúkọ Àdúgbò ní Àkùngbá-Àkókó, Ìpínlẹ̀ Òndó, Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Awon itumo awon oruko awon adugbo ilu Akungba-Akoko, ni Ipinle Ondo, Naijiria.

ÀKÙNGBÁ-ÀKÓKÓ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ÀKÚNMI : ìsèlè tí o mu ìpayà wa sele ní àdúgbò yi ti o mu ki ìpàdé pàjáwìrì wáyé nílé Oba. Nígbà tí onísé yoo jísé fún oba ohun tí o kó so ni pé àkún mi eyi tí o túmò sip e Àkùn ni àdápè Àkùngbá sugbon nígbà tí ìsèlè yi mi gbogbo Àkìngbá ni won fi n so pe Akun mi ti won si waa so adugbo naa ní Akunmi lati ìgbà naa ni won ti n je olóyè ti a n pè ni Alákúnmù. ÒKELÈ : Àwon jà-ǹ-dù-kú ènìyàn ni won fe àdúgbò yìí dó; Awon alo-kólóhun-kígbe, olè ati ìgára. Ibi ti won si tèdó si je ibi ti o ga sókè. Bi enikeni ba fee lo sí àdúgbò yi won a ni o lo òkè olè. Òkè olè ni won so di òkelè di òní-olónìí.

AKÙWÀ: Ìgbàgbó awon ènìyàn nip é awon to wa ni àdúgbò yi je òdàlè, atan-ni-je Àgàbàgebè ènìyàn ni won. Èdè Akungba ni Akuwa eyi ti o túmò sí pe ìwà nikan ni o kù won kù.

ÙBÈRÈ: Eni ti o kókó kó ilé ni ilú Àkùngbá Ùbèrè ni o ko o sí. Ibè ni àwon ènìyàn sì gbàgbó pe Àkùngbá ti se wá Ibè ni olóyè àkókó ti je. Idi niyi tí wón fi ń pè é ni Ubere-ibi ti nǹkan ti bèrè tàbí sè.

OKÙSÀ: Orúko eni tí o kókó kó ilé ni àdúgbò yí ni a fi n pèé. Òhun ni won n pè ni Okusa. Ìdílé re ni won ti n je oye olókùsà.

ÌBÀKÁ: Òbe ìrelé ti bàbá àgbà kan lo lati ségun àwon òtá ni àwon omo-omo rè ri ni òkè àjà ti won n pe ni ìká ni àkùngba. Lati igba yen ni won ti n pe àdúgbò náà ni ìbàká.

ÒDODÒ: Àgbàrá san gba èhìnkùlé àdúgbò yi kojá. Gbogbo Ilé ti o wa ní àdúgbò yi ni won si n pè ni òdodò eyí tí o túmò si ode (ile)-odo Òde-ode tasí Ododo.

ÒLÁLÈ: Oloye ti o koko je ni àdúgbò yi ni o létòó lati máa pín ilè fún àwon ènìyàn. Ilè ni Akungba n pè ni alè. Ìdí nìyí tí won fi n pea won to leto lati tai le tabi latí pín ìlè ni alale ti adugbo won sì n jé Olale. Ni adugbo bi ni won sit i n je oba titi ji oni-Oloni eyi wá wà ni ìbámu pèla òrò Yorùba tó so pé Oba ló nile.

AROKUNPANLE : Oke pupo wa ni adugbo yi to béè gee bi ènìyàn ko ba jeun kánú dáadáa yoo maa fidi wo kó tó wolé míràn ni. Itumo arokunpanle ni afìdímólè.

APOLE: Eni ti o koko te àdúgbò yi do maa n mo ògiri yi àwon ilé ibè po. Awon ilé tí a bá sì mo ògiri yip o ni a n pè ní apolé lati ìgbà náà ni wón ti ń pe àdúgbò yìí ní apolé.

ÀLÙJÙ: Ni àràárò ni baba arúgbò kan máa n fi ìlù ji awon ara adugbo yòókù. Nigba ti won bi baba yi léèrè èrèdí to fi n lu ilu o ni o n mu oun larada ni. Lati igba naa ni won ti n pe àdúgbò yìí ni àlùjù.

OKOGBO: Inú igbó ni bàbá àgbàlagbà ti o te àdúgbò yi do ń gbé kí àwon ènìyàn to de ba a nibe ìdí nìyí ti awon ènìyàn fi n pe àdúgbò náà ni okogbó.

ODÈÈGBÒ: Àwon to kókó te àdúgbò yí dó máa n da agbàdo sise sinu omi to n sàn to wà níbè. Àgbàdo yìí ni won n pè ni ègbo tì won sì ń pe odò yìí ní odo-egbo ti wón sì so àdúgbò yin i odèègbo.

ÒNÀKÈ: Ile pupa àti òpòlopò òkìtì-ògán wa ni adugbo yìí. Òpòlopo ona ni o sì já si ìlú yìí. Ona ti o wà ni ese òkè yi ni eni ti o te e dó ń gbé ìdí nìyí ti won fi n pe àdúgbò yí ní ònàkè.