Sókótó

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ipinle Sokoto
Sokoto market 2006
Sokoto market 2006
CountryNigeria
StateSokoto State
Government
 • TypeDemocratic
 • Executive GovernorRt Hon. Aminu Waziri Tambuwal[1]
 • Deputy GovernorManir Muhammad Dan Iya [2]
 • Head of ServiceAlhaji Sani Garba-Shuni
 • Chief of StaffAlhaji Muktar Umar Magori [3]
 • Accountant GeneralUmar Ahmad Balarabe[4]
Population
 (2021)
 • Total5,307,154 [5]
Websitehttps://sokotostate.gov.ng

Sokoto je ilu pataki kan ni ariwa iwo oorun Naijiria, nitosi idapomora Odo Sokoto ati Odo Rima. Ni Odun 2006, olugbe ti o wa ni be ju 427,760. Sokoto ni oluilu Ipinle Sokoto, o si je oluilu awon ipinle ti o wa ni ariwa iwo oorun Naijiria tele.

Oruko Sokoto (oruko atijo re ni Sakkwato) ni ipilese Larubawa, je sooq ti o tunmo si oja ni Yoruba. Atun mo si Sakkwato, Birnin Shaihu da Bello tabi "Sokoto, Oluilu Shaihu ati Bello" Bello Umar Maikaset.

Ibujoko Kalifu Sokoto teleri, esin musulumi ni o bori ni ilu naa ti o si je ibujoko pataki ti won ti n ko eko Islam. Sultanu ti o je oludari Kalifu ni adari elesin awon Musulumi Naijiria.

Oju ojo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sokoto ni oju ojo ologbele-ogbele (Isori oju ojo Köppen BSh). O wa ni apa Sahel to gbe, Savana oniyanrin ati oke die si yiika. Pelu iwon igbona tabi otutu odoodun to saba ma n je 28.3°C (82.9°F), Sokoto je ikan lara awon ilu to gbona julo ni Naijiria, sibesibe iwon igbona tabi otutu ni osan saba ma n je 40°C (104.0°F) fun pupo igba lodun, gbigbe re kii je ki ooru poju.[6] Osu keji titi de Osu kerin ni o ma n gbona julo, ti gbigbona re le ju 40°C lo. Iwon igbona tabi otutu ti o ga julo ni 45°C. Igba ojo beere lati Osu kefa titi de Osu kewa, nigbati ojo ma n ro lojoojumo. Ojo naa kii saba ma n pe, oyato si bi ojo ti ma n ro ni awon agbegbe ti ojo ti man ro daradara. Lati opin Osu kewa de Osu keji, ni 'igba otutu', ategun oye ti o n fe eruku Sahara ma n bo oju ojo. Eruku yii ma n bo oorun, o si ma n di iwon igbona tabi otutu ku lopolopo.

Anfani ti agbegbe naa ni lati gbin irugbin ni ibi isan omi odo Sokoto-Rima, ti o ni ile olora. Awon irugbin ti won ma n gbin ni Sokoto ni jero, oka baba, ewa to fere poju, leyin re ni agbado, iresi, yamati/eeku, awon irugbin oka ati ewebe miran ni alubosa, tomati, ata, igba/ikan, letusi, ati kabeeji.[7] Yato si jero, Sokoto ni o n pese alubosa julo ni Naijiria. Ni ti eweko, Sokoto bosi agbegbe Savana. Eyi jẹ ilẹ-koriko ti ko ni eṣinṣin tse-tse, o dara fun ogbin awọn irugbin ọkà ati osin ẹran. Òjò máa ń pe bẹ̀rẹ̀ ó sì ma n tete dawoduro pẹ̀lú ìwọ̀n idaji òjò odoodun láàárín 500mm ati 1,300mm. Awọn igba meji pataki lo wa ni Sokoto, igba otutu ati ogbele. Ogbele ma n bẹrẹ lati Oṣu Kẹwa titi di Oṣu Kẹrin ni awọn apa kan o si le di Osu Karun tabi Osu Kefa ni apa miiran. Igba otutu ni apa keji bẹrẹ ni Osu Karun titi di Oṣu Kẹsan tabi Oṣu Kẹwa ni opo ibi ni ipinle naa. Oye, gbigbẹ, otutu, ati afẹfẹ eruku ni iriri ipinle naa laarin Oṣu Kọkanla ati Osu keji. Ooru ma n po ni ipinlẹ naa ni Oṣu Kẹta ati Oṣu Kẹrin. Ṣugbọn oju ojo ni ipinle naa ma tutu ni owurọ o si ma n gbona ni awọn ọsan, yato si igba oye lile. Petele ti o wopo ni ile Hausa, apa ariwa Naijiria ni o poju ni ipinle naa. Ilẹ fadama ti o tobi pupo ti awọn ọna Odo Sokoto-Rima wa ni pẹtẹlẹ ti o si pese ilẹ olora ti o dara fun ogbin ọpọlọpọ irugbin ni ipinle naa. Awọn oke ati oke-nla wa kaakiri ipinlẹ naa.

Itan-akoole idagbasoke[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Shehu Usmanu Dan Fodiyo ti lo Sokoto ni ibere osu kewaa odun 1804 gege bi ibi ipade pelu Galadima, Yunfa's Vizier. Lẹyin naa, Muhammad Bello lo o gẹgẹbi ibi ikọlu Dufua ni ibere ọdun 1806. Bovil daba pe won ti mo agbegbe naa si Sokoto lati ibẹrẹ awon ọdun kẹtadinlogun. Ni iwoye itan, Sokoto ni a da sile bi agọ ologun ni ọdun 1809, nigbati Shehu Usmanu wa ni Sifawa. Lẹhinna o di olu-ilu kalifu lẹhin iku Shehu.

Ni awọn ọdun 1820, Sokoto wa ni ipo giga rẹ ti aisiki ni ibamu pẹlu ipo giga ti awọn agbara 'awọn alaṣẹ' ni aarin kalifu, ti o n gba isakole lododun lati ọdọ gbogbo awọn fiifu ṣaaju ki agbara won to dinku. Oluwakiri Hugh Clapperton (1827) ni iwunilori pupọ nipasẹ aisiki yii ati awọn ipa rẹ lori ilu naa.

Clapperton ṣe akiyesi pataki bi agbegbe Sokoto se sunmora won: awọn odo, dipo iṣowo jijinna, ni ọrọ-aje ilu naa. Ṣugbọn iṣowo Sokoto ko da bii ti tele mo, nitori ipo idamu ti orilẹ-ede ti o sunmo wa.

Ni akoko ti oluwakiri Heinrich Barth de ni 1853, die eniyan lo n gbe Sokoto o si ti bajẹ pupọ. Barth ni 1857 ṣe iṣiro awọn olugbe ni 20,000-22,000, ṣugbọn ọja naa si n se daadaa, ati agbegbe eyin odi ti o dara ju Sokoto funrararẹ.

Bovil ṣapejuwe ni deede Sokoto gẹgẹbi ipo ti o lagbara, pẹlu awọn apata giga lati ila-oorun si ariwa-iwọ-oorun ati afonifoji kekere kan ni iwọ-oorun ati guusu iwọ-oorun ti o daabobo lodi si awọn ikọlu alagbara aimotele. Ilu naa jẹ gaba lori ilẹ pẹtẹlẹ ti o gbooro nibiti awọn odo meji, Rima ati Sokoto pade, ti o jẹ ipade ọna lati Gobir ni ariwa, Kebbi ni guusu ati Burmi Zamfara ni ila-oorun.

Ni ibẹrẹ orundun kọkandinlogun, ilu naa (Sokoto) ti pin si awọn eka. Irú àwọn eka bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka Magajin Gari, ẹ̀ka Waziri, ẹ̀ka Sarkin Musulumi, ẹ̀ka Sarkin Adar, ẹ̀ka Magajin Rafi, àti eka Sarkin Zamfara. Ni akoko yii awọn wọọdu naa jẹ kekere ti wọn si fi odi yi wọn ka, pelu eyiti o wa ninu mọṣalaṣi Sultan Bello ati Shehu, Aafin Sultan ati awọn ile miiran ati agbo ile Shehu.

Ni ọdun 1818, won fe odi naa si iwọn ti o ni awọn ẹnu-ọna ti o wọle ati jade lati odi Birni. Iru ibode ni Kofar-Kade, Kofar-Kware, Kofar-Rini, Kofar-Dundaye, Kofar-Taramniya, Kofar-Aliyu Jedo, ati Kofar-Marke.

Agbegbe Sokoto ti o wa lọwọlọwọ jẹ ile ti ọpọlọpọ awọn ijọba ti ìwọ̀ oòrùn Sudan ṣaaju ikonileru. Awọn yii ni ijọba Gobir ati Kebbi pẹlu kalifu olokiki agbaye ti olu-ilu ti ẹmi ati ti iṣelu jẹ olu-ilu ipinlẹ naa[8].

Lẹ́yìn ìṣẹ́gun kalifu látọwọ́ àwọn Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1903, oríṣiríṣi ẹ̀yà ara rẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àdáṣe tí wọ́n sì darapọ̀ mọ́ ìjọba Àríwá Nàìjíríà. Ẹkùn àríwá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ apá kan kalifu Sokoto àti ijoba Kanem-Bornu. Eyi tẹsiwaju titi di Oṣu Kini ọdun 1967 nigbati a ṣẹda awọn ipinlẹ lati rọpo awọn ijọba agbegbe nipasẹ Ajagun Yakubu Gowon. Sokoto di olu-ilu ipinlẹ àríwá ìwọ̀ oòrùn ti a ṣẹda ni ọdun 1967. Ni ọdun 1976 lẹyin idasile ipinlẹ Niger kuro ni ipinlẹ àríwá ìwọ̀ oòrùn, ipinlẹ Sokoto farahan pẹlu olu ile rẹ. Sibẹsibẹ ni Sokoto, ipinle Kebbi ati Zamfara ni won yo kuro ni Sokoto, ni 1991 ati 1996 lẹsẹsẹ.

Ilu Sokoto ti jẹ olu-ilu fun ọpọlọpọ awọn ijọba lati igba idasile rẹ nipasẹ Kalifu Muhammad Bello ni ọdun 1809.

Eniyan ati asa[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ipinle Sokoto ni iye eniyan bii 3.7 milionu[9] ti o da lori ikaniyan ọdun 2006 ti ẹya meji ti o jẹ Fulani ati Hausa . Ilu Sokoto, olu ilu ipinle Sokoto, ni iye eniyan ti o to 2.5 milionu. Yatọ si Fulani ati Hausa, eya kekere Zabarmawa ati Tuareg wa ni awọn aala ti ijọba ibilẹ. Gbogbo awọn ẹgbẹ wọnyi n sọ Hausa gẹgẹbi ede ti o wọpọ. Fulfulde ni awọn Fulani n sọ.

Awon Hausa ni ipinle naa je Gobirawa, Zamfarawa, Kabawa, Adarawa ati Arawa. Awọn Fulani ni apa keji jẹ ti awọn ẹgbẹ pataki meji; ilu Fulani (Hausa: Fulanin Gida; Fula: Fulbe Wuro) àti awon awọn alarinkiri. Awọn akoko ni Torankawa, awọn idile ti Shehu Usmanu Danfodiyo, Sullubawa ati Zoramawa. Awon Torankawa jẹ kilasi aristocratic lati ọdun 1804.

Ni aṣa, ipinle na jẹ isokan. Awọn eniyan ti ipinle na jẹ Musulumi, ati pe ẹsin Islam n fun wọn ni eto ti iwa ati ihuwasi. Ilana imura wọn tun jẹ ti orisun Islam. Awọn ayẹyẹ pataki meji ti o jẹ, Eid-el-Fitri ati Eid-el-Kabir ni won ma n se ni ipinle na ni odoodun. Ayeye akoko duro fun opin awe Ramadan, nigba ti ikeji wa fun pipa àgbo ni iranti ise Anabi Ibrahim (Abraham).

Ijakadi ibilẹ (Kokawa) ati ese (Dambe) ni ere idaraya meji ti Hausa n gbadun nigba ti Fulani ati Sullubawa ma n daraya pẹlu Sharo ati Doro lẹsẹsẹ. Awọn alejo ti o ṣe pataki si ipinlẹ naa ni won ma n pe si ibi ayeyedurbar nla tabi kekere, ayeye ti o wa fun iwode ẹṣin ti a ṣe lọṣọ daradara ati awọn ibakasiẹ ti awọn ọkunrin ti o wo aso ogun ibile ati aso asa maa n gun.

Awọn iṣẹ-aje[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

O ju ọgọrin ninu ọgọrun (80%) awọn olugbe ilu Sokoto ti o n ṣe iru iṣẹ-ogbin kan tabi omiran. Wọ́n ń pese irúgbìn bii jéró, okababa, àgbàdo, ìrẹsì, anoman, ege, ẹ̀pà, àti ẹ̀wà fún oúnjẹ, wọ́n sì ń pese àlìkámà, òwú, àti ẹfọ̀ jáde fún owó. Iṣẹ́ ọnà abẹ́lẹ̀ bíi alágbẹ̀dẹ, aso híhun, pipa aso laro, gbígbẹ́ ona àti iṣẹ́ áwọ̀ tún kó ipa pàtàkì nínú ètò ọrọ̀ ajé àwọn ará Sokoto; nitori eyi, awọn agbegbe oriṣiriṣi bii Makera, Marina, Takalmawa ati Majema di pataki. Sokoto tun jẹ ọkan ninu awọn agbegbe ti o n pese ẹja ni orilẹ-ede. Nitori naa, opolopo eniyan lẹba agbada odo ma n peja pẹlu. [10]

Bakanna ni Sokoto ni awọn ohun elo adayeba ati erupẹ. Awon ile ise ogbin ti o n lo owu, epa, oka, goomu, agbado, iresi, ireke, alikama, ege, goomu Arab ati taba bi awọn ohun elo ise ni won le dasilẹ ni agbegbe naa. Ogbin aladanla ni won tun le ṣe ni ipinlẹ na nipa lilo omi irigeson lati Daamu Goronyo, Lugu, Kalmalo, Wammakko ati adagun Kwakwazo laarin awọn miiran.

Awọn ohun alumọni bii kaolini, gipisum, okuta-efun, lateraiti, awọn ọlọ pupa, fosifeti mejeeji ofeefee ati alawọ ewe, amọ iboji, iyanrin ati bẹbẹ lọ, wa ni awọn iwọn iṣowo. Awọn ile-iṣẹ ti o nlo awọn ohun elo ise wọnyi le ti fi idi mulẹ ni ipinlẹ naa.

Àìsí esinsin tse-tse lórí ilẹ̀ pápá oko tí ó ṣí sílẹ̀ ní èrè fun àwọn ẹranko igbó àti ẹran agbéléjẹ̀. Sokoto wa ni ipo keji ni ipese ẹran-ọsin ni iye ẹranko ti orilẹ-ede ti o ju miliọnu mẹjọ lọ. [10]

Wiwa awọn agbara eto-aje wọnyi n pese awọn anfani idoko-owo to dara, ni pataki ni awọn ile-iṣẹ ogbin gẹgẹbi bii ọlọ iyẹfun, ṣiṣe awọn tomati, isọdọtun suga, awọn aṣọ, goomu, soradi, ẹja agolo, ati bẹbẹ lọ.

Gbigbe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Sokoto ko ni eto irinna gbogbo eniyan. Gbigbe laarin ilu naa (nigbati kii ṣe nipasẹ ẹsẹ) ni nipasẹ okada eyiti o ṣiṣẹ bi takisi eniyan kan ati nigbamiran awọn kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ma n gbe eniyan lati ibi kan si ekeji; eyi ngbanilaaye fun gbigbe eniyan diẹ sii ju ọkan lọ ni akoko kan (sibẹ ni idiyele olowo poku bi awọn okada). Awọn ọkọ akero ati awọn takisi kii ṣe loorekoore ati pe wọn lo fun gbigbe laarin awọn ilu.

Papa ọkọ ofurufu agbaye pẹlu asopọ deede si Abuja, Kano ati Eko wa ni kilomita mewa guusu si Sokoto.

Ile-iṣẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni Oṣu Kẹjọ ọdun 2008, won se adehun fun kikọ awọn iṣẹ simenti ni Sokoto.

Didi Ilu Nla[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Didi ilu nla ni Ìtàn tó ti pẹ́ gan-an ní ilẹ̀ Hausa. Eto naa bẹrẹ nigbati awọn agbegbe ilana kan ti ilẹ Hausa ni idagbasoke lati Kauyuka si Birane. Sibẹsibẹ ọkan ninu awọn abajade pataki ti jihadi ni iyara ti iṣẹlẹ yii kii ṣe ni ilẹ Hausa nikan ṣugbọn ni gbogbo awọn agbegbe ti iṣakoso kalifu. Awọn ilu tuntun dide ati ilu Birane to ti pe wọ inu akoko idagbasoke ti a ko ri tẹlẹ, diẹ ninu won bi awọn agbegbe tuntun ti awọn iṣẹ iṣowo, awọn miiran bi awọn olu-ilu Emirati ati aarin gungun iṣakoso ati iṣowo.

Ọkan ninu awọn ẹya olaju ninu itan kalifu Sokoto bẹrẹ pẹlu idasile ilu Sokoto (olu-ilu kalifu). Ki jihadi to sele, agbegbe laarin Ijọba Gobir ati Kebbi ni agbegbe ti a n pe ni “ilẹ awon arinkiri”. Sugbon pelu aseyori jihad ti Shehu Usmau dan Fodiyo (1804–1808) dari ati isegun ti awon jihadi lori awon olori ile Hausa, ilu Sokoto (olori ile ijoba kalifu) ni Muhammad Bello ko. Pẹlupẹlu, gẹgẹbi Abdul-Razaq Shehu ṣe akiyesi ninu iwe rẹ Sakkwato Birnin Shehu ), won ti ya aworan ilu Sokoto lori iwe nipasẹ Muhammad Bello paapaa ṣaaju ki won to kọ ọ. Bello, ọmọ Sheikh, wa ninu awọn ogagun baba rẹ ati awọn adari ogun. O ja ogun ti o lera julo ti o si gun julo, o si je ayaworan kalifu Sokoto Birnin Shehu.

Ilu Sokoto gẹgẹ bi a ti ya aworan re nipasẹ ayaworan Muhammad Bello ni gbogbo awọn ẹya ara ti ilu ode oni pẹlu awọn ọna, awọn afara, ọja, ganuwa (awọn ibi agbara kaakiri ilu) ati pẹlu awọn ile-iṣẹ iṣakoso ati iṣowo. Lara awọn ile-iṣẹ iṣakoso ti Muhammad Bello ṣe ni Kanwuri, Binanchi, Galadanci, Alkalanci, Dogarawa ati bẹbẹ lọ. Sibesibe, yato si ọja aarin ti a mọ si Yardole, awọn agbegbe iṣowo miiran ti a ṣe nipasẹ Muhammad Bello ni Makera, Madinka, Marina, Siriddawa, Takalmawa, Runji ati Jirgawa. Ni afikun, ninu awọn ohun miiran ko si ilu ni boya ṣaaju jihadi tabi orundun kokandinlogun ile Hausa ti o le di ilu nla laisi odi ti o munadoko (ganuwa). Eyi ni a kọ pẹlu ọpọlọpọ awọn ibi agbara bi Kofar Aliyu Jedo, Kofar Dundaye, Kofar Marke, Kofar Rini, Kofar Kware, ati Kofar Taramniya, ati pe idagbasoke pataki yii fa ọpọlọpọ eniyan lati lọ kuro ni agbegbe wọn si ilu Sokoto fun iwalaaye.

Lati akiyesi ti o wa loke lori bi kalifu Muhammad Bello ṣe ya aworan ilu Sokoto, a o ri pe Sokoto jẹri sii awọn aṣikiri ti o ni ifẹ si awọn iṣẹ alagbẹdẹ, ise awo, ohun elo amọ ati bẹbẹ lọ. Fun apẹẹrẹ, diẹ ninu awọn eniyan wọnyi ṣe iṣowo ti alagbẹdẹ tabi ni iṣowo miiran ti o jọmọ bi Makera Assada. Awon eniyan kan wa ti won maa n rin irin ajo lo si orisiirisii ilu Naijiria ati awon orile-ede to wa nitosi lati ra awon ohun elo irin to baje bii oko to yonu, oko ayokele, oko nla, oko ofurufu ati beebee, paipu irin, ati tanki epo ki won le tu won ka, ti won si n ta won fun ẹnikẹni ti o fẹ lati loo tabi yi wọn pada si ọja miiran.

Awọn eniyan olokiki[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Egbo Osita (ojoibi 1998), agbaboolu

Ìtókasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Governor". Official Website of Sokoto State Government - The seat of Caliphate. 2020-05-06. Retrieved 2022-03-19. 
  2. "Deputy Governor". Official Website of Sokoto State Government - The seat of Caliphate. 2020-05-06. Retrieved 2022-03-19. 
  3. "Tambuwal appoints Ubandoma SSG, reappoints Chief of Staff, Magori". The Nation Newspaper. 2019-06-06. Retrieved 2022-03-19. 
  4. "Umar Balarabe: Astute accountant and public officer par excellence". Vanguard News. 2019-04-21. Retrieved 2022-03-19. 
  5. "Sokoto State". Nigerian Investment Promotion Commission. 2019-01-09. Retrieved 2022-03-19. 
  6. Umar, B A (2013-03-01). "ANALYSIS OF THE MEAN MONTHLY VARIATION OF PRESSURE, RAINFALL AND TEMPERATURE AT SOKOTO - Request PDF". ResearchGate. pp. 1–5. Retrieved 2022-03-25. 
  7. "Sokoto - Location, History, Facts, & Population". Encyclopedia Britannica. 2005-09-11. Retrieved 2022-03-25. 
  8. Government of Sokoto State, 2022. About Sokoto State. Retrieved from https://sokotostate.gov.ng/history-of-sokoto/
  9. Government of Sokoto State, (2022). People of Sokoto. Retrieved from https://sokotostate.gov.ng/history-of-sokoto/people-of-sokoto/
  10. 10.0 10.1 Government of Sokoto State, (2022). The Economy. Retrieved from https://sokotostate.gov.ng/history-of-sokoto/the-economy/