Tai Solarin

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Tai Solarin
Tai Solarin, director of the Mayflower school (right), with a guest from Israel in Ikene, Nigeria, 1962.
Ọjọ́ìbíAugustus Taiwo Solarin
(1916-08-20)20 Oṣù Kẹjọ 1916
Ikenne, Southern Region, British Nigeria (now in Ogun State, Nigeria)
Aláìsí27 July 1994(1994-07-27) (ọmọ ọdún 77)
Ikenne, Ogun State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànTai
Iléẹ̀kọ́ gíga
Iṣẹ́Educator, social activist, author (journalist) first African pilot[1]
Olólùfẹ́
Sheila Mary Tuer
(m. 1951)
Àwọn ọmọCorin Solarin
Tunde Solarin

Augustus Taiwo "Tai" Solarin (tí wọ́n bí ní 20 August 1916, tó sì ṣaláìsí ní 27 July 1994) fìgbà kan jẹ́ olùkọ́ ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ài òǹkọ̀wé. Ó ṣe ìdásílẹ̀ Mayflower School, ní Ikenne, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọdún 1956. Ní ọdún 1952, Solarin di ọgá ilé-ìwé Molusi College, ní Ijebu Igbo, ó sì wà ní ipò yìí títí wọ ọdún 1956 tí ó fi di ọ̀gá ilé-ìwé Mayflower School.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Ikenne ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ni wọ́n bí Solarin sí, ní 20 August 1916. Òun sì ni ọ̀kan lára àọn ìbejì tí Daniel Solarin àti Rebecca Okufule Solarin bí. Èkejì rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Caroline Kehinde Solarin kú ní ọdún 1991, ní ọmọdún mọkàndínláàádọ́rùn-ún. Òun àti èkejì rẹ̀ nìkan lọmọ tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Ilé-ìwé Wesley College Ibadan ni ó lọ. Àwọn àkọsílẹ̀ Nnamdi Azikiwe lórí gbígba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú láti lọ kàwé ní òkè òkun ló wú Solarin lórí. Ìgbìyànjú àkọ́kọ́ rẹ̀ láti gba passport ò bọ́ si, àmọ́ owọ́n padà mu, láti ṣiṣẹ́ ní British Air Force, ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Royal Air Force gẹ́gẹ́ bí atọ́nisọ́nà ní Second World War. Ìlú Britain ni ó wà, tó fi kẹ́kọ̀ọ́ ní University of Manchester, lẹ́yìn náà ni ó lọ sí University of London. Tai Solarin fẹ́ Sheila Mary Tuer níṣu lọ́kà ní ọdún 1951.[2]

Solarin padà sí Nàìjíríà, ó sì di olùkọ́ ní Molusi College, èyí tí àwọn ará-ìlú àti ẹlẹ́sìn kìrìsìtẹ́ẹ́nì ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ní Ijebu-Igbo. Ní ọdún 1952, wọ́n yàn án sí ipò ọ̀gá ilé-ìwé, lẹ́yìn tí Stephen Awokoya kúrò nípò, tó lọ di Mínísítà fú ètò ẹ̀kọ́. Solarin tó jẹ́ ọmọnìyàn ní èròǹgbà láti mú àyípadà bá ètò-ẹ̀kọ́, èyí sì mu kí ó yọ àdúrà àrààárọ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn kúró ní ilé-ìwé náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ìlú ló tako èyí. Ìlú yìí bákan náà sì jẹ́ èyí tí àbúròkùnrin rẹ̀ ti jẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Ó pinnu láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú láti lọ ṣèdásílẹ̀ ilé-ìwé tirẹ̀ pẹ̀lú ìfọ́wọ́sí Awokoya tó fìgbà kan jẹ́ ọ̀gá ilé-ìwé. Ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-ìwé Mayflower ní 27 January 1956.[3]

Ilé-ìwé Mayflower[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọgbà ilé-ìwé Mayflower tí ó ṣèdásílẹ̀ jẹ́ èyí tí ìwọ̀n ilẹ̀ rẹ̀ tóbi, ìlú tí wọ́n sì bí Tai Solarin sí, ní Ikenne, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ló wà. Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní ilé-ìwé yìí á tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000).

Ọgbà náà ní kíláàsì, ilé ìṣàkóso, ilé kékeré fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùkọ́, ilé-ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti oko. Ilé-ìé náà gbajúmọ̀ fún àṣeyọrí rẹ̀ nípa ètò ẹkọ́.

Ìṣeníwọ̀nba[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ìlú tí àwọn ọlọ́lá àti ọlọ́rọ̀ máa ń wọ agbádà olówó ńlá, láti fi ọlá àti ipò wọn hàn,kakí àti ẹ̀wù lásán ni Tai máa ń wọ̀.

Tai Solarin University of education[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù November, ọdún 2005, Nigerian National Universities Commission (NUC) ṣe ìdánimọ̀ "Tai Solarin University of Education" (TASUED) ní Ìpínlẹ̀ Ògùn gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹ̀kọ́ gíga àkọ́kọ́ tó ń rí só ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ìkọ́ni, àti ilé-èkọ́ gíga ẹlẹ́kẹtàdínlọ́gbọ̀n tó jẹ́ ti ìpínlẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ gíga ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínláàádọ́rùn-ún tó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Towards Nigeria's Moral Self-Government,[4]
  • Thinking with You.
  • A Message for Young Nigerians.
  • To Mother With Love.
  • Mayflower; the story of a school.
  • Timeless Tai.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. a Columnist of Nigerian Tribune journal
  2. "::. Tai Solarin Organization .::. Welcome". Taisolarin.org. Archived from the original on 20 March 2011. Retrieved 17 November 2010.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Onabule Duro. (1975). Tai Solarin: Educationist, Reformer, Atheist. Spear Magazine. P. 12
  4. Soyinka, Kayode (4 August 1994). "Obituary: Tai Solarin – People, News". The Independent (London). https://www.independent.co.uk/news/people/obituary-tai-solarin-1374193.html.