Ẹran

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
ẹran tí wọn kò tíì sè
Màlúù Wagyu tí wọ́n ń sìn láti pa fún jíjẹ

Ẹran jẹ́ orúkọ gbogbo gbò fún ẹran tí a lè rí lára ara ẹran yálà ti ewúrẹ́ tàbí ti màlúù.[1]

Nígbà láé láé, àwọn ọmọ ènìyàn ma ń dẹdẹ àwọn ẹranko láti pa wọ́n fún jíjẹ, amọ̀ nígbà tí ó yá wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń rè tàbí sìn wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀sìn ní ilé tí wọ́n sì ma ń mú wọn pajẹ nígbà tí àyè rẹ̀ bá ṣì sílẹ̀. Lágbàáyé lóní, ẹran malúù ni àwọn ènìyàn ń jẹ jùlọ ní gbogbo agbáyé, lẹ́yìn náà ni ó kan ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ẹran adìyẹ. Ní ọdún 2018, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Brazil àti China ni wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pèsè ẹran yí jùlọ.

Wọ́n lè lo ẹran màlúù ní oríṣiríṣi ọ̀nà; wọ́n lè ge wẹ́wẹ́, tàbí kí wọ́n sin sínú pẹ̀pẹ́ kí wọ́n fi ṣe Súyà, wọ́n lè lọ̀ọ́ kí wọ́n fi ṣe meetpie ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹran ní àwọn èròjà bíi: purotéènì, ayọ̀nù, vitamin B12 àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí a bá jẹ ẹran lájẹ ju, ó lè fàá kí àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ ati àìsàn ọkàn ó mú ni pàá pàá jùlọ bí wọ́n bá ti fi àwọn kẹ́míkà kan kun láti lè jẹ́ kí ó má tètè bajẹ́. [2]

Àwọn itọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Definition of BEEF". Merriam-Webster. 2022-12-22. Retrieved 2023-01-08. 
  2. "Beef Meat Identification". Animal Science. Retrieved 2023-01-08.