Jump to content

Àìsàn inú afẹ́fẹ́

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A red poster with illustrations and the text: "AIRBORNE PRECAUTIONS. EVERYONE MUST: Clean their hands, including before entering and when leaving the room. Put on a fit-tested N-95 or higher level respirator before room entry. Remove respirator after exiting the room and closing the door. Door to room must remain closed."
Àwòrán tí ó ń ṣàfihàn àtòjọ àwọn èèwọ̀ láti dènà ìtànkálẹ̀ àìsàn inú afẹ́fẹ́ ni agbègbè ìṣèwòsàn. Èròǹgbà ni lati gbé e kalẹ̀ sí ìta yàrá ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú aláìsàn tí ó ń ṣàárẹ̀ àìsàn inú afẹ́fẹ́.[1]

Àìsàn inú afẹ́fẹ́ tàbí atẹ́gùn jẹ́ àìsàn kí àìsàn tí kòkòrò afàìsàn lè fà tí ẹ̀rún rẹ̀ nínú atẹ́gùn lè ṣàkóbá fún ẹlòmíràn bí wọ́n bá mí í sínú.[2] Ògùn irú àìsàn báyìí ṣe pàtàkì sí ènìyàn àti ẹranko. Àwọn kòkòrò afàìsàn náà lè jẹ́ kòkòrò ààrùn-ẹ̀ràn, bakitéríà, tàbí fọ́nńgaì tí wọ́n lè ràn káàkiri nípa èémí, ọ̀rọ̀ sísọ, ikọ́ wúwú, èésín sí sín, pípo eruku, fífọ́n nǹkan olómi ká, tàbí ìṣe tó bá ń fa ẹ̀rún inú atẹ́gùn tàbí nǹkan tó lè fọ́nká nínú atẹ́gùn.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ẹ̀rún àìsàn nínú atẹ́gùn máa ń fa àrùn láti imú, ọ̀fun, sinuses, àti ìfun, èyí ló máa ń fa ikọ́, ọgbẹ́ ọ̀fun àti àwọn àmìn àwọn àìsàn míì tó lè ṣẹ́yọ lágọ̀ọ́ ara.

Lára àwọn gbajúmọ̀ àrùn inú afẹ́fẹ́ ni : ẹ̀ràn kòrónà, àrùn ilẹ̀ gbígbóná, morbillivirus, àrùn ilẹ̀ tútù, ikọ́ fée tàbí ikọ́ àwúgbẹ, Mycobacterium tuberculosis, influenza virus, enterovirus, norovirus, àti, adenovirus, èyí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ àti respiratory syncytial virus. Irúfẹ́ àwọn àrùn ẹ̀ràn wọ̀nyí nílò afẹ́fẹ́ àyíká àdáwà nígbà ìtọ́jú.

Àwọn ẹ̀rún kòkòrò àìsàn tí atẹ́gùn máa ń fọ́nká ló máa ń fa àwọn àrùn inú atẹ́gùn. Orísun wọn máa ń sáàbà máa wá láti ara omi ara alárùn ẹ̀ràn tàbí ẹranko, tàbí àwọn ìdọ̀tí ohun èlò. Àwọn ẹ̀rún àìsàn tí wọ́n máa ń fa èyí ni wọ́n ń pè ní kòkòrò afàìsàn. Wọ́n lè ràn ká nínú afẹ́fẹ́, eruku tàbí omi, tí wọ́n sì lè rìn jìnnà tàbí wà nínú afẹ́fẹ́ fún ìgbà pípẹ́.Fún àpẹẹrẹ, sínsín lè fọ́n àwọn ẹ̀rún àìsàn ká káàkiri inú ọkọ̀ akérò kan.[3]

Mímí sínú àwọn ẹ̀rún àìsàn máa ń sáàbà fa àìsàn inflammation, èyí sìn máa ń ṣàkóbá àwọn ẹ̀yà èémí. Dídọ̀tí afẹ́fẹ́ kò sí lára àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́ tí ó máa ń ṣe ènìyàn, ṣùgbọ́n dídọ̀tí afẹ́fẹ́ máa ń kópa pàtàkì nínú àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́ tí kò jẹ mọ́ ìṣe ènìyàn bí i ikọ́-kéfe Àwọn ìdọ̀tí afẹ́fẹ́ máa ń ṣàkóbá fún ọ̀fun ènìyàn nípa ṣíṣokùnfà ọ̀pọ̀ àìsàn inú afẹ́fẹ́ ti inflammation. [4] Àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́ náà lè ṣàkóbá fún àwọn ẹranko. Fún àpẹẹrẹ, Newcastle disease jẹ́ àrùn àwọn ẹyẹ tí ó máa ń ṣe àwọn ẹyẹ ọ̀sìn káàkiri àgbáyé nípa ìdọ̀tí inú afẹ́fẹ́.

Àwọn àrùn ẹ̀ràn máa ń jà kálẹ̀ nígbà tí alára dídá bá mí ẹ̀rún àìsàn sínú tàbí bí irú ẹ̀rún àìsàn bẹ́ẹ̀ bá bà lé e lójú, lẹ́nu, tàbí imú. Kò pọ̀n dandan kí alára dídá ènìyàn ní ìfojúkojú pẹ̀lú aláàrùn kí ó tó lè kó àrùn wọ̀nyí. Bí ojú ọjọ́ ṣe rí, nígbà òjò tàbí ẹ̀rún, yálà ní ìta gbangba tàbí nínú ilé máa ń kópa pàtàkì nínú ìkóràn àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́. Àwọn nǹkan mìíràn tí ó máa ń ṣokùnfà ìtànkálẹ̀ ẹ̀rún àìsàn ni ìjì, òjò, àti ìṣe àti ìmọ́tótó ènìyàn.

Lẹ́yìn ìyàsọ́tọ̀ ètò ojú-ọjọ́, ìwọ́jọpọ̀ àwọn ẹ̀rún-àìsàn fọ́nńgàá nínú afẹ́fẹ́ máa ń dínkù; lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, àwọn ẹ̀rún-àìsàn wọ̀nyí máa ń pọ̀si ní ìlọ́po tó pọ̀ sí i ju ìgbà tí ojú ọjọ́ bá dá geere.

Eto ọ̀rọ̀ ajé òun àyíká máa ń kópa péréte nínú àjàkálẹ̀ àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́. Ní àwọn ìlú ńlá, rírànkálẹ̀ àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́ máa ń pọ̀ púpọ̀ ju ti àwọn abúlé àti àwọn ìlú kéréje lọ. Títànkálẹ̀ awọn ẹ̀rún-afàìsàn fọ́nńgàá máa ń wọ́pọ̀ ni àwọn abúlé.

Wíwà ní ìtòsí àwọn òdò ńlá lè ṣokùnfà àjàkálẹ̀ àwọn àrùn inú afẹ́fẹ́.

Àìmójútó ẹ̀rọ amúlétutù dáadáa tí fa ìbẹ́sílẹ̀ àrùn Legionella pneumophila.

Àìsí ìmójútó tó péye fún àwọn irinṣẹ́ ilé ìwòsàn ló máa ń fa àwọn àìsàn inú afẹ́fẹ́ tó jẹ mọ́ ilé-ìwòsàn

Lára awọn ọ̀nà Láti dènà àìsàn inú afẹ́fẹ́ ni lílọ àwọn ògùn-àjẹsára àìsàn kan pàtó, wíwọ ìbòjú àti yíyàgò fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ti kó àrùn.[5] Níní àjọṣe pọ̀ pẹ̀lú ènìyàn tàbí ẹranko tí ó bá láàrùn àìsàn inú afẹ́fẹ́ kò ní kí ènìyàn lárùn náà dandan, nítorí kíkó àrùn náà dá lórí bí àwọn èròjà ìlera ara ènìyàn bá ti lágbára tó àti bí mímí sínú àwọn ẹ̀rún afaìsan tí onítọ̀ún mí sínú ṣe pọ̀ tó.

Nígbà mìíràn, a lè lo àwọn ògùn antibiotics láti wo àìsàn inú afẹ́fẹ́ bí i pneumonic plague.[6]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ètò ìlera tí dábàá pé ìmọ́tótó àti Ìjìnnà-síra-ẹni ( èyí tí a tún mọ̀ sí Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ) jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti dènà ṣe àdínkù rírànkálẹ̀ àìsàn inú afẹ́fẹ́. [7].[8] Kò ṣeé ṣe kí ènìyàn ṣe àdínkù ìjàmbá àti kó àìsàn inú afẹ́fẹ́, ṣùgbọ́n ènìyàn lè dènà kíkó àrùn. Láti ṣe àdínkù kíkó àrùn:

  • Jìnnà sí àwọn àwọn tí wọ́n tí kó àrùn.
  • Wọ ìbòjú ni gbogbo ìgbà tí ó bá fẹ́ lọ sí àwùjọ àwọn ènìyàn púpọ̀.
  • Bo ẹnu rẹ́ nígbà tí ó bá ń wúkọ́ tàbí sín.
  • Máa fọ ọwọ́ rẹ dáadáa, ó kéré jù fún ìṣẹ́jú- àáyá ogún lóòrèkóòrè.
  • Yẹra fún fífi ọwọ́ pa ojú ara rẹ tàbí tí àwọn mìíràn láìfọwọ́.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Transmission-Based Precautions". U.S. Centers for Disease Control and Prevention (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-01-07. Retrieved 2020-03-31. 
  2. Siegel JD, Rhinehart E, Jackson M, Chiarello L, Healthcare Infection Control Practices Advisory Committee. "2007 Guideline for Isolation Precautions: Preventing Transmission of Infectious Agents in Healthcare Settings" (PDF). CDC. p. 19. Retrieved 2019-02-07. Airborne transmission occurs by dissemination of either airborne droplet nuclei or small particles in the respirable size range containing infectious agents that remain infective over time and distance 
  3. https://www.chicagotribune.com/opinion/ct-xpm-2014-04-19-ct-sneeze-germs-edit-20140419-story.html
  4. "Airborne diseases". Archived from the original on 28 June 2012. Retrieved 21 May 2013. 
  5. American Academy of Orthopaedic Surgeons (AAOS) (2011). Bloodborne and Airborne Pathogens. Jones & Barlett Publishers. pp. 2. ISBN 9781449668273. https://books.google.com/?id=8hbEOpBtBJIC&printsec=frontcover&dq=books+airborne+disease. Retrieved 21 May 2013. 
  6. Laura Ester Ziady; Nico Small (2006). Prevent and Control Infection: Application Made Easy. Juta and Company Ltd.. pp. 119–120. ISBN 9780702167904. https://books.google.com/books?id=kSKwP3v99dYC&pg=PA119. 
  7. "Redirect - Vaccines: VPD-VAC/VPD menu page". 2019-02-07. 
  8. "Targeted social distancing design for pandemic influenza". Emerging Infect. Dis. 12 (11): 1671–81. November 2006. doi:10.3201/eid1211.060255. PMC 3372334. PMID 17283616. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3372334.