Àrokò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àrokò jẹ́ ìlànà bí a ṣe ń fi nǹkan ṣe ìfidípò ọ̀rọ̀ ẹnu láti bá ènìyàn sọ̀rọ̀ láyé àtijọ́. Àrokò jẹ́ ọ̀nà tí àwọn alágbára, Ọba tàbí àwọn olóyè ń gbà ṣe ìbánisọ̀rọ̀ sí ara wọn láìlo ọ̀rọ̀ ẹnu.[1] Ènìyàn lásán náà lè pàrokò ránṣẹ́ sí ẹlòmíràn, tàbí kí wọ́n fi pa àlè lé nǹkan.

Àrokò Pípa Ní Ayẹ́ Àtíjó

Àrokò pípa jẹ́ ònà ti Yorùbá maa n gbà se ìkìlò tàbí ránsẹ́ sí ẹlòmíràn láyẹ́ àtíjó. Àrokò máà nje mò isé, ẹ̀sìn tàbí ẹgbẹ́ tí àwọn ènìyàn nse. Òtító tàbí ìgboràn se Pàtàkì nínú àrokò pípa. Ìdí ni yi tio fi je wípẹ́ pé ẹnikéni tía bá fi àrokò rán gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí o fetí si òfin àti olótító ènìyàn.

Àwọn àrokò kan wa ti o máà n wa lójú kan, àwọn àrokò wònyí ní a npe ni àte, irú àwọn àrokò bayi wa láti se ìkìlò ewu.

Lááyé àtíjó, orísirísi àwọn ènìyàn lo máà n pàrokò ránsẹ́. Die lára wón ni:- Ode, Babaláwo, awo, ògbóni, jagunjagun, àgbẹ̀, àti bee lo.

Àwọn Ohun Tó Se Pàtàkì Ti A Ba Pa Àrokò

  • Ẹni tí o pa àrokò
  • Ẹni tí a fi àrokò ran
  • Ẹni tí a fi àrokò ránsẹ́ si

Ẹni Tí O Pa Àrokò: Ẹni tí o pa àrokò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí o mò irú ẹ̀rọ̀njà tí o tó fún irú àrokò ti o fẹ́ pa. Ẹni náà gbọdọ̀ jẹ ẹni tó gbangba sùn lóyé.

Ẹni Tí A Fi Àrokò Ran: Ẹni tí a fi àrokò náà ran gbọdọ̀ jẹ ẹni tí o se fi ọkàn tán tí ki se màdàrù ẹ̀nìyàn rárá.

Ẹni Ti A Àrokò Ránsẹ́ si: Ẹni náà gbọdọ̀ mò ìtumò àrokò tí wón pa fún sùgbón tí ẹni náà ko ba mò irú àrokò tí o pa fún o gbọdọ̀ lo ba àwọn àgbà láti so ìtumò àrokò náà fún.

Oríṣìíríṣìí Àrokò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Àrokò Ìkìlọ̀
  • Àrokò Ẹ̀bẹ̀
  • Àrokò Ogun
  • Àrokò Íransé
  • Àrokò Ìfẹ́
  • Àrokò ìtọ́nisọ́nà[2]
  • Àrokò Àlè Pípa
  • Àrokò Àṣẹ́wélé
  • Àrokò Àgà yíya[3]
  • Àrokò ajemówe
  • Àrokò afohùn gbéwà jáde
  • Àrokò ajemásìírí

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọlátúnjí,O (1986);Àrokò.Ìbàdàn,Vintage Publishers.