Ìṣọ̀lá Oyènúsì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìṣọ̀lá Oyènúsì tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Dọ́kítà Oyènúsì (Dr. Oyènúsì) jẹ́ ògbóǹtarìgì adigunjalè tó fìgbà kan yọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lẹ́nu kí ọwọ́ ṣìnkún òfin tó tẹ̀ ẹ́. Iṣẹ́ adigunjalè tó yàn láàyò jẹ́ kó di ìlúmọ̀ọ́kà lọ́dún 1970s.[1] Nígbà ayé adigunjalè rẹ̀, Oyènúsì gbajúmọ̀ nínú dídigunjalè ilé ìfowópamọ́, àwọn ilé ìṣe ńláńlá àti ìdigunjalè gba ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́. Ọrọ́ rẹ̀ dàbí "Àjànàkú kọjá, mo rí nǹkan fìrí, bá a bá rérin, ká gbà pé a rí erin", ó jẹ́ adigunjalè tí gbogbo ènìyàn bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀, kódà, àwọn agbófinró bẹ̀rù rẹ̀ gidigidi. [2]

Bí Oyènúsì Ṣe Gba Orúkọ Ìnagijẹ Rẹ̀, Dókítà Oyènúsì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkọsílẹ̀ ìtàn kan sọ pé Oyènúsì kò kàwé gboyè dókítà rárá, ìṣe lo dédé sọ ara rẹ̀ ni orúkọ Ìnagijẹ òun. Oǹkọ̀wé náà jẹ́rìí pé, Oyènúsì fún ara rẹ̀ jẹ́wọ́ èyí lẹ́yìn tí owó ṣìnkún òfin báà kí wọ́n tó pa á. Ó ní Oyènúsì jẹ́wọ́ pé òun kò kàwé rárá nítorí àwọn òbí òun kò lowo lọ́wọ́ láti rán òun, ìdí nìyí tí òun fi yan iṣẹ́ adigunjalè láàyò. [3]

Bí Oyènúsì Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Adigunjalè[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìṣọ̀lá Oyènúsì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ adigunjalè nígbà tí ó ń wá owó láti fún olólùfẹ́bìnrin rẹ̀. Lásìkò yìí, ó fẹ̀ẹ́ tálákà ju èkúté ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Èyí ló mú un digun jalè gba ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ó tà ní irínwó náírà (N400), tí ó sì lówó náà fún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ náà. [4]

Bí ṣìnkún òfin Ìjọba ṣe Tẹ Oyènúsì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Taló jẹ́ gbéná wojú ẹkùn Oyènúsì nígbà tí ó ń digun jalè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ló tọwọ́ rẹ̀ bọ́. Ọ̀pọ̀ lọ ti pá ni ìfọnnáfọṣu, ọ̀pọ̀ ló pa lẹ́kún bákan náà. Ògbójú olè tí gbogbo ènìyàn ń sá fún ni Oyènúsì. Kódà, ọlọ́pàá fúnra wọn bẹ̀rù rẹ̀. Ayeta rẹ̀ gbóná débi pé ìbọn ọlọ́pàá, bí ó tilẹ̀ wù kó lágbára tó, kì í rán án. Olè Oyènúsì gbówọ́ tó bẹ́ẹ̀ gé tí àwọn agbófinrò fi ń sá fún un. Òun ni ọ̀dájú àti ògbójú olè àkókò tí òkìkí rẹ̀ kàn káàkiri ilẹ̀ Káàárọ̀-o-jíire àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Yorùbá bọ̀, wọ́n ní "ìgbà ò lọ bí òréré, ayé ò lọ bí ọ̀pá ìbọn", lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyànjú, ọwọ́ bá Oyènúsì nígbà tí ó lọ digun jalè lọ́jọ́ kan pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ adigunjalè rẹ̀ mẹ́fà mìíràn. Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mú lọjọ́ náà. Oyènúsì pa kọ́sítébù ọlọ́pàá kan nígbà tí òun àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ fijà pẹ́ta pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá. Ṣùgbọ́n, èwe sunko, ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá sì tẹ̀ ẹ́. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́, ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún Oyènúsì àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lọ́dún 1971.[5] Ìta gbangba ni wọ́n tí pa wọ́n ní ìlú Èkó.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Tayo, Ayomide O. (2017-09-14). "The rise and fall of the romantic armed robber in the 70s". Pulse Nigeria. Retrieved 2019-11-14. 
  2. Omipidan, Teslim Opemipo (2019-04-04). "The Real Story of Ishola Oyenusi - Nigeria's Deadliest Armed Robber - OldNaija". OldNaija. Retrieved 2019-11-14. 
  3. Omipidan, Teslim Opemipo (2019-04-04). "The Real Story of Ishola Oyenusi - Nigeria's Deadliest Armed Robber - OldNaija". OldNaija. Retrieved 2019-11-14. 
  4. Bankole, Evelyn (2018-01-15). "The story of a romantic gangster Doctor Ishola Oyenusi". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-11-14. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  5. PeoplePill (1971-09-08). "Ishola Oyenusi: Notorious nigerian robber - Biography, Life, Family, Career, Facts, Information". PeoplePill. Retrieved 2019-11-14.