Isaac Folorunso Adewole

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Isaac Folorunso Adewole
Ọ̀jọ̀gbọ́n Isaac F. Adewole Mínísítà fún Ìlera tẹ́lẹ̀.
mínísítà fun ìlera ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
Ọjọ́ kọkànlá Oṣù kọkànlá Ọdún 2015
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíỌjọ́ karùndínlógún Oṣù karún ọdún 1954
Ilesa, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
ProfessionDókítà, olùkọ́ àti olóṣèlú

Isaac Folorunso Adewole (bíi May 5, 1954) jẹ́ Ọ̀jògbọ́ dókítà olóyún ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lati ẹ̀yà Yorùbá. Ó jé mínísítà lábẹ́ Ìsàkóso Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí. Kí ó tó di mínísítà, Ó jẹ́ alàkóso Yunifásítì ìlú Ìbàdàn ati Ààrẹ àwọn àjo Áfíríka fún iwadi àti ikẹ́kọ́ àìsàn jẹjẹrẹ. Kí ó tó di alàkóso Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, Ó jẹ́ alàkóso ilé Ìwòsan ti Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, ilé Ìwòsan Yunifásítì tí ó tóbi jù lo in Orílẹ̀- èdè Nàìjíríà.[1][2]

Ní àtẹ̀jade Ìwé ìròyìn Tẹ́lígíráfu, a ríi kà wípé ọ́ jé Ògbónta rìgiì Ọ̀mọ̀wé àti olùdarí ẹ̀kọ́ ìmo ìlera.[3] Ní ọjọ́ karún osù karún, ó se ayẹyẹ ọgọta odún ìbí rẹ̀. ayẹyẹ naa sélé ni Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Awọn èèyan jakanjakan ni ó wá se àyẹ́sí rẹ́. Alaga ayẹyẹ naa ni Amòfin àgbà tí a n pè ní Wole Olanipekun.[4]

Ìgbà èwe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Adéwolé ni ọjọ́ karún osù karún,1954 ni Ilesa, ìlú tó wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn lóòní. Àtẹ̀jade Ìwé ìròyìn The Punch sọ wípé ìya rẹ̀ bíi sínú ọ̀kọ ayọkẹ́lẹ́ tí o n gbé lọsí ilé Ìwòsan ní ìgbà tí ó rọ́bí ati bíi.[5] Adewole lọ ilé ẹ̀kọ́ alakọ́bẹ́rẹ́ tí a mọ̀ sí Ògùdù Methodìst àti ilésà girama sùkùù ni ìlú ilésà ní ibi tí gba Ìwe ẹ̀ri tí a mọ̀ sí West Africa School Certificate. Lèyìn èyi ni ó lọ sí Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, Ìbàdàn tí ó fi ìgbà kan jé olùìlú Agbègbè Apáìwọ̀òrùn Nàìjíríà láti ba di dókítà. Adéwlé tèsíwájú nínú èkó rè, ó sí gbà ìwé erí kékeré ni ọdún 1972, kí ó tó lọ láti gba ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ gíga nínú ìmọ̀ ìlera ni ọdún 1976."[6]

Ìgbésí ayé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1978, gẹ́gẹ́ bí dókítà, ódara pọ̀ mọ́ ilé Ìwòsan ti a mọ̀ sí University College Hospital, lábẹ́ àkóso Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Ní ọdún 1979, ó kúrò ni ilé Ìwòsan ti Yunifásítì ìlú Ìbàdàn lọ Sókótó fún ètò Àgùnbánirọ̀ tí ó se pàtàkì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Lèyìn rè, ó sisẹ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lu ilé Ìwòsan ti a mọ̀ sí Adeoye Maternity hospital ìlú Ìbàdàn kí ó tó padà darapọ̀ mọ́ ilé Ìwòsan ti a mọ̀ sí University College Hospital ní ibi tí o ti kọ́kọ́ sisẹ́ kí ó tó lọ ìpínlẹ̀ Sòkòtò fún ètò Àgùnbánirọ̀.[7] Ní ọdún 1982, ó di akọ̀wé àgbà ní ilé Ìwòsan náà kí ó tó lọ sí òké òkun (United Kingdom) fun fún ètò tí a mọ́ si Fellowship Program. Lèyìn náà ní ó padà sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lati darapọ̀ mọ́ ilé Ìwòsan ti a n pè ní Royal Crown Specialist Hospital níbi tí ó lo ọdún mẹ̀erin gbáko ki ó tó padà sí ilé Ìwòsan, University College Hospital, Ìbàdàn.[8] Ni ọdún 1992, ó di olùkọ́ àgbà. Ni ọdún 1997, o di Ọ̀jọ̀gbọ́n (Professor) nínú ìmọ̀ ìlera ni Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Ní ọdún yi kan náà ni won yáàn ni asòfin Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Bakan náà ni won yáàn ni alàkóso ti department of Obstetrics and Gynaecology. Lèyìn ọdún, o di alàkóso College of Medicine. Ni osù kejila ọdún 2010, ó jẹ alàkóso Yunifásítì ìlú Ìbàdàn. Ipò yí ni o wá ti ó fi di mínísítà lábẹ́ Ìsàkóso Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí.[9]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "UI sets tone for selection of new VC". Nigerian Tribune. Archived from the original on November 19, 2015. Retrieved September 18, 2015. 
  2. "Stakeholders salute UI VC". The Punch News. Archived from the original on May 14, 2014. Retrieved September 18, 2015. 
  3. "Celebrating UI VC at 60". New Telegraph. Archived from the original on November 18, 2015. Retrieved September 18, 2015. 
  4. "UI VC gets new roles". The Nation Nigeria. Retrieved September 18, 2015. 
  5. "Celebrating UI VC @ 60". Nigeria Headlines. Archived from the original on November 19, 2015. Retrieved September 13, 2015. 
  6. "Forget Past Injustices Olanipekun Tells UI VC,". Thisday News. Archived from the original on November 19, 2015. Retrieved September 18, 2015. 
  7. "Professor I.F. Adewole- VICE-CHANCELLOR". University of Ibadan. Archived from the original on September 22, 2015. Retrieved September 18, 2015. 
  8. "Finally, Ambode Emerges Winner in Lagos Guber Contest". Thisday News. Archived from the original on November 19, 2015. Retrieved September 18, 2015. 
  9. "Guber Poll: APC Sweeps Out PDP". Leadership Newspaper. Retrieved September 18, 2015.