Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ ni oruko iwe ti D.O. Fagunwa ko.

Ìwé ìtàn-àròso yìí dá lé orí Àkàrà-ogun àti ìrìnàjò rè sí inú Igbó Irúnmolè.

Nínú ìwé yìí, a ó ka nípa Àkàrà-ogun àti Lámórin, àwon èro òkè Láńgbòdó, Àkàrà-ogun lódò Ìrágbèje nílé olújúléméje àti àbò òkè Láńgbòdó

Àkàtúkà ni Ògbójú Ọdẹ nínu igbó irúnmọlẹ́

O ti je ayipadaede si ede Geesi ati ede Larubawa.

Akara-ogun ati awọn obi rẹ̀ Ojú-Ìwé 1-4.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Eyin orẹmi, bi owe bi owe ni a nlu ilu ogidigbo, ologbon ni'ijo o, omoran ni si imo o. Itan ti n o sọ yi, ilu ogidigbo ni; emi ni eniti yio lu ilu na, eyin ni ologbon ti yoo jo o, eyin si ni omoran ti yoo mo o pelu. Awon agba a màá pa owe kan, ẹko bi mi bi won ti n paa ndan? Won ni, “Bi egun eni ba jo’re ori a ya ni.” Toto o ṣe bi owe o....

Igba ekini akara-ogun ninu igbo irunmalẹ Ojú-Ìwé 5-20.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Ohun ti oju baba mi ri kò to nkan lara temi. Nigbati mo ba si ronu nipa temi yin a, ẹru awọn ti noẉn tun dagba ju mi lọ a ma ba mi: nitori bi arugbo ba ni ki on ka ohun ti oju on ri ki on to gbo sinu aiye, awọn ọmọde miran iba ma gbadura ki awọn ku ni ewe.

“Nigbati mo ti mọ bi ọmọ odun mẹwa ni mo ti nba baba mi lọ si igbẹ ọdẹ; nigbati mo si ti to ọmọ ọdun mẹdogun, ni mo ti da ibọn ni fun ara mi....

Igba ekeji akara-ogun ninu igbo irunmalẹ Ojú-Ìwé 21-39.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nigbati ọkunrin yi lọ tan ti mo pada de ile, mo pe awọn aladugbo mi jọ, mo pe ọrẹ ati ojulumọ mi mọ sip e awọn ibatan mi pẹlu mo ro gbogbo nkan wọnyi fun wọn. Ẹnu ya wọn gidigidi gbogbo wọn si fi ohun si i pe ki awọn ji wa si ile mi lowurọ ọjọ keji ki ọkunrin na to de, ki awọn ba lè gbọ itan ti ọkurin na yio tun sọ, nitori irohin temi kò nil è to afojuba ti wọn....

Akara-ogun ati lamọrin Ojú-Ìwé 40-46.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Nigbati o to bi wakati kan mo jade ninu iho yi si gbangba, mo mu okuta nì mo fi i sinu apo ọdẹ mi nitori lati igbati iya ti bẹrẹsi jẹ mi yi, ibọn mi ati apo ọdẹ mi kò kuro lọwọ mi. Jijade ti mo si jade na ọkunrin kan ti orukọ rẹ njẹ Lamọrin ni mo ba pade: ọkunrin na ti ṣina si aginju igbẹ yi lati ọdun mẹta.

“Nigbati o ri mi o yọ de ìmùdùnmúdùn ti mbẹ ninu egungun rẹ̀ nitoripe aladugbo mi ni o jẹ ni ile. Emi ati Lamọrin ki ara wa olukuluku si sọ ohun ti oju on ti ri sẹhin-oju mi kò ri nkan lara ti Lamọrin nitori o pẹ ti on ti ṣina ti kò si ti ifi oju kan ile....

Ọjọ ekini lọdọ iragbeje ni ile olojulemeje Ojú-Ìwé 71-81.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Ni ọjọ keji ti a de Oke Langbodo ni ọba paṣẹ ki awọn iranṣẹ rẹ̀ mu wa lọ si ọdọ Iragbeje, nitbati a si de ibẹ o mu wa lọ sinu iyara nla kan bayi ti o wà ni ipẹkun ile na. Ẹnyin ẹlẹgbẹ mi gbogbo, iyara ti a nwi yi dara, okuta olowo iyebiye ni noẉn fi ṣe ilẹ ibẹ o ndan bí digi o mọlẹ̀ bi omi inu apata; nigbati a tilẹ kọ de ibẹ a ṣebi oju omi ni nwọn kọ ile si ni, àṣé didan okuta wọny ni o jẹki o jọ bẹ loju wa-A! iragbeje pọ lọkunrin....

Ọjọ ekeji lọdọ iragbeje ni ile olojulemeje Ojú-Ìwé 82-93.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Nigbati ilẹ ọjọ keji mọ ti a ji, Iragbeje mu wa lọ si iyara miran ti o dara ju ti ana ni ilọpo meji, nigbati gbogbo wa sit un joko bi ti ana tan o bẹrẹsi ọrọ isọ o wipe: “Lana mo sọrọ fun yin nipa awọn ọmọde, ṣugbọn loni ngo sọrọ nipa awọn ti nwọn dagba ti nwọn si jẹ alaṣeju, ẹ gbọ bi ngo ti ṣe ma sọrọ si wọn: ...

Ọjọ ekeje lọdọ iragbeje ni ile olojulemeje ati abọ oke langbodo Ojú-Ìwé 94-102.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Nigbati ilẹ ọjọ keje mọ ti a jẹun tan, Iragbeje mu wa lọ si ode a si yi gbogbo Oke Langbodo ka. O pẹ diẹ ki a to pade de ile, nigbati a si jẹun ọsan tan a bẹrẹsi iṣe ere-a sare, a ja ijakadi, a fò, a takiti, a gun igi a si fi oniruruọna da ara way a. Nikẹhin Iragbeje pew a o si mu wa lọ si iyara rẹ̀ kan ti o ku ti a kò ti iwọ nitoriti a ti wọ iyara mẹfa ni ọjọ mẹfa ti a ti lo sẹhin. Iyara ekeje yi yatọ si awọn ti a ti nwọ̀ ri-ati ilẹ ni, ati oke ni, ati ẹgbẹ ogiri ni, ati ohunkohun ti o sa wà ni iyara yi ṣa ni, gbogbo wọn funfun bi ẹgbọn owu. Nigbati a de ibẹ Iragbeje to wa siwaju rẹ̀ ni iduro o sọ fun w ape a kò gbọdọ joko on na papa si duro niwaju wa o wọ aṣọ funfun o si bẹrẹsi ọrọ isọ o ni,...


  • Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀, D.O. Fagunwa (1951), Nelson Publishers Limited in association with Evans Brothers (Nigeria Publishers) Ltd, Ibadan, Nigeria. ISBN 978-126-237-0. Ojú-ìwé 102. it is also translated to english and arabic