Ẹ̀sìn-ìn Híndù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Esin Hindu ni èsìn ti ó lójó lórí jùlo, tó si lààmi-laaka jùlo nínú gbogbo àwon èsin. Ònà láti se èkúnréré àlàyé ìdàgbàsóké èsìn Hindu ta kókó púpò nítorí pé a kòlè so pàtó eni tó se agbáterù ìdásílè rè sùgbón inú àwon ìse èsìn èyà Aryan ti wón si lo si orílè-èdè India láti ààrin gbùngbùn Asia ló ti sè wá ní bi i i egbèrún odún méta séyìn. Àwon èyà Aryan gbógun ti àwon aráa Arapánì ti wón gbé ni orilè èdè India tòní ni bíi odún 500BC Séyìn. Àsèyín wá, àsèyìn bò, nípa ìfaramolé pèlú ìgbàgbó èsìn keji, àwon èyà méjéèjì se àgbékalè ìlànàn ìgbàgbó èsìn kan ná-àn to dálóríi ìgbàgbò pé èyà Aryan ni ju olórun kan lo àti ìwà ni mímó ìsèso, èyà Hárápáni. Láìpé, àwùjo to kún fún èyà Aryàn se àgbédìde ìlànà ti kò fààyè gba èyà mìíràn wón si se ìpínrò àwùjo won gégé bi isé owóo won se lóóòrìn sí.

Èsin Hindu dá lóri pé èmi ènìyàn àti èmi, eranko to ti kú sí n padà wá sáyé láti máa gbé láimo iye ìgbà àti ni orísiirísii ònàn. Ìgbàgbó pé èmi n lo sókè sódò lónà ta ò le so ni pàtó nipa ìwà èyi tí àwon Hindu yàn je yo nínú àwon àgbékalè isesi won. Ìlànàn ti kò fi àyè gba irúfé èyà miiràn yè, a kò sì gbo rárá pé èya kàn yónú si èyà kejì nítorí pé enikòòkan won ló n du ipò láwùjo ti a gbé bii. A fi elòmíràn si àwùjo tó ga jùlo nítorí pé ó ti hùwà omolúàbí séyìn, ní gbà ti a bi elòmiràn si àwùjo tó tòsi nítorí pé ó ti siwà hù séyìn.

Lónìí, elésin-ín Hindu le gbàgbó pé olórun jù òkan lo, òmíràn lè gbà pé òkan nì, a tún lerí èyi ti ó gbàgbó pé òkan ni olórun àti gbogbo àgba nlá ayé, béè a si tún ri èyi tó gbà pé kò si olorún rárá. Èyi mú ki ó sòro láti jiròrò lórii ìgbàgbó èsìn-in Hindu ni pàtó niwòn ìgbà tó jé wí pé orísiirísii ni òye tó wà nípa èsin Hindu. Nítorí ná-àn à gbodò má ménu ba àwon kókó wònyí.

Pàtàkì, si èsin, Hindu ni ètò ayé àtúnwá, èto èyà ti kò fi àyè gba òmiràn, tó dàpò pèlú ìsèlè tó lààmi laaka, wiwá ìwà omolúàbi àti bibó lówó sikún ayé àtúnwá lálàáfíà.

Lára àwon ònàn èsìn Hindù si igbàlà ni ònàn ìrúbo, mímo àwon ìsèlè tòóótó, ònàn ìfara eni ji, ìfara eni ji fún olórun èyi tó yàn láti tèlé. Bi àwon elésìn yii bá tèlé àwon ààlà àwon ònàn yi, ìgbàlà yóò jé tiwon.Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]