Ọmú

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Ọmú
Weibliche brust en.jpg
Morphology of human breasts with the areola, nipple, and inframammary fold
Details
Arteryinternal thoracic artery
Veininternal thoracic vein
Latinmamma (mammalis "of the breast")[1]
Anatomical terminology

Ọmú tàbí Ọyàn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ẹ̀yà ara tí ó wà lọ́wọ́ òkè. Lára àwọn obìrin, ó jẹ́ ẹ̀yà tí ó ma ń sun wàrà gẹ́gẹ́ bí óúnjẹ fún àwọw òpónló tí wọ́n ń mumú.[2] Tọkùnrin tobìnrin ní wọ́n ma ń ní ọmú ní àyà wọn. Àmọ́, ní àsìkò ìbàlágà ẹ̀yà ara yí ma ń dàgbà sókè lára abo látàrí èròjà ara tí wọ́n ń pè ní (estrogen) àti (growth hormone). Ọ̀rá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Subcutaneous fat tí ó níṣe pẹ̀lú ibùsun omi tí ó ma ń jáde ẹnu kókó ọmú, awọ fẹ́lẹ́ yí ni ó ma ń fún ọmú ní àbùdá wọn. Níparí ọmú ṣáájú kókó ọmú ni agbẹ̀du tí wọ́n ń pè

alveoli ni omi ọmú ma ń sodo sí tí ó sì ms ń wà ní sẹpẹ́ fún fífà tàbí mímu ìkókó nígbà tí ọmọ bá gbẹnu si. [3]

Ọmú: àwòrán bí ó ti rí nínú mammary gland. Àdàkọ:Ordered list

Lásìkò tí obìnrin bá wà nínú oyún, ọmú ma ń ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èròjà àti ọmọ ogun ara tí wọ́n ń.pè ní (hormone), pàá pàá jùlọ èròjà estrogens, progesterone, àti prolactin, àti àwọn mìíràn bíi lobuloalveolar tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè àti ìgbaradì rẹ̀ fún ìfọ́mọlọ́mú lẹ́yìn tí obìrin bá bímọ tán.

Àríwísí nípa ọmú[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yàtọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́ ìfọ́mọlọ́mú àti àwọn èròjà àṣara-lóore tí ó kó sínú, wọ́n tún ka ọmú obìnrin sí àmì ìbálagà obìnrin fún ìbálòpọ̀ láti ṣòwò ọmọ bíbí. Ọ̀pọ̀ àti oríṣríṣi iṣẹ́ ọnà àti àwòrán ti àyé àtijọ́ àti tòde òní ni wọ́n ti ṣàfihàn ọmú nínú iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà orílẹ̀-èdè àgbáyé ni wọ́n ka ṣíṣàfihàn ọmú sí ìta gbangba gẹ́gẹ́ ohun ìríra tí kò sì bójú mu ní àwùjọ.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "mammal – Definitions from Dictionary.com". Dictionary.reference.com. Archived from the original on 14 November 2011. Retrieved 31 October 2011.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Breast – Definition of breast by Merriam-Webster". merriam-webster.com. Archived from the original on 6 September 2015. Retrieved 21 October 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "SEER Training: Breast Anatomy". National Cancer Institute. Archived from the original on 2 May 2012. Retrieved 9 May 2012.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)