Jump to content

Adéníji Àdèlé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Oba Sir Adeniji Adele II, KBE
Ọba ìlú Èkó

Adéníji Àdèlé II
Oba of Lagos
Reign 1949–1964
Coronation 1949
Predecessor Fálolú Dòsùmú
Successor Adéyínká Oyèkàn
House Àdèlé Ajosun, Ológun Kútere
Father Bùráímọ̀ Àdèlé
Mother Moriamo Lalugbi
Born (1893-11-13)13 Oṣù Kọkànlá 1893
(N.S.: 13 November 1893)
Lagos, Nigeria
Died 12 July 1964(1964-07-12) (ọmọ ọdún 70)
Èkó, Nàìjíríà
Burial Ìgà Ìdúnganran
Religion Lahore Ahmadiyya Movement

Ọba Sir Musendiku Buraimoh Adéníji Àdèlé II, tí ó tún jẹ́ KBE (13 November 1893 – 12 July 1964) ni ó jẹ́ Ọba ìlú Èkó láàrín ọjọ́ kínní oṣù Kẹwàá ọdún 1949 sí ọjọ́ kejìlá oṣù keje ọdún 1964.[1][2]

Wọ́ bí Àdèlé ní inú ọdún 1893 sínú ìdílé alàgbà Buraimoh Àdèlé tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ Mọ̀ríyámọ̀ Lálúgbi ní ìlú Èkó. Bàbá bàbá rẹ̀ ni Ọba Àdèlé Ajósùn. Àdèlé lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Holy Trinity Primary School, tí ó wà ní agbègbè Èbúté-Èrò, tí ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti CMS Grammar School, Lagos bákan náà. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde nílé ẹ̀kọ́ girama ni ó dara pọ̀ mọ́ àwọn agbẹ̀kọ́ lábẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ Àwọnẹ̀ tí àwọn gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn ń ṣakóso rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó pari inẹ́kọ́ ilẹ̀ wíwọ̀n ni wọ́n gbe lọ sí ìlú kano gẹ́gẹ́ bí wọnẹ̀-wọnlẹ̀. Ó ṣíṣeẹ́ pẹ̀lú Cameroon Expeditionary Force gẹ́gẹ́ bí awọnlẹ̀ nígbà ogun agbáyé ẹlẹ́kejì.

Ní ọdún 1920, Adéníji Àdèlé sin olóyè Amodu Tijani Oluwa lọ sí ìlú London láti lọ farahan níwájú ìgbìmọ̀ privy council ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lórí rògbòdìyàn ilẹ̀ Olùwá tí Àmọ́dù sì borí ẹjọ́ náà. Adéniji Àdèlé tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akápò owó tí ó sì padà di kíláákì àgbà ní ọdún 1937. Wọ́n fi oyè Commander of the Order of the British Empire (1956) and Knight of the Order of the British Empire (1962) by the Queen of the United Kingdom dáa lọ́lá.[3][4]

Ipa rẹ̀ nínú ìṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọba Àdèlé nígbà ayé rẹ̀ jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Egbe Omo Oduduwa tí alàgbà Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ alátakò sí ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC àti NNDP tí ó ń ṣèjọba nígbà náà. Àwọn ẹgbẹ́ méjèjì tí a mẹ́nubà lókè yí ni wọ́n lòdì sí kí Adéníji Àdèlé ó gorí ìtẹ̀ àwọn bàbá ńlá rẹ̀ ní ìlú Èkó nítorí wípé kìí ṣe ọmọ oyè láti ìdílé Dòsùnmú. Ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ tí ó kalẹ̀ sí ìlú London ni ó sọọ́ di Ọba ní ọdún 1957.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àdàkọ:Obas of Lagos

Àdàkọ:Authority control


Àdàkọ:Lagos-stub Àdàkọ:Africa-royal-stub

  1. "LAGOS (Yoruba State)". Archived from the original on 17 May 2017. Retrieved 19 September 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Oba of Lagos". Retrieved 19 September 2015. 
  3. Moshood Ademola Fayemiwo, PhD; Margie Neal-Fayemiwo, Ed.D (6 July 2017). ASIWAJU: The Biography of Bolanle Ahmed Adekunle Tinubu. Strategic Book Publishing & Rights Agency, 2017. pp. 288. ISBN 9781946539434. 
  4. Toyin Falola; Ann Genova (July 2009). Historical Dictionary of Nigeria. Scarecrow Press, 2009. pp. 16. ISBN 9780810863163. https://books.google.com/books?id=QWTd1ftuCbwC&q=adeniji+adele+knight&pg=PA16. 
  5. Robert L. Sklar (8 December 2015). Nigerian Political Parties: Power in an Emergent African Nation. Princeton University Press, 2015. pp. 71. ISBN 9781400878239. https://books.google.com/books?id=xD7WCgAAQBAJ&q=adeniji+adele&pg=PA71.