Adesuwa
Adesuwa (A Wasted Lust) | |
---|---|
[[File:Fáìlì:Movie poster of Adesuwa (A wasted lust).jpg|200px|alt=]] | |
Adarí | Lancelot Oduwa Imasuen |
Olùgbékalẹ̀ | John Chukwuma Abua Lancelot Oduwa Imasuen |
Òǹkọ̀wé | Ossa Earliece |
Àwọn òṣèré |
|
Orin | Henry Edo |
Ìyàwòrán sinimá | Lanre Oluwole Ejim Fortune Kezi |
Olóòtú | Victor Ehi-Amedu |
Ilé-iṣẹ́ fíìmù | John Films Sources |
Olùpín | Nollywood Distributions |
Déètì àgbéjáde |
|
Àkókò | 124 minutes |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Èdè |
|
Ìnáwó | ₦18 million[2][3] |
Adesuwa (A Wasted Lust) jẹ́ fíìmù ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó jáde ní ọdún 2012. Ó jẹ́ fíìmù ajẹmọ́tàn èyí tí Olùdarí àti aṣagbátẹrù rẹ̀ jẹ́ Lancelot Oduwa Imasuen. Lára àwọn òṣèré tó kópa nínú fíìmù náà ni Olu Jacobs, Bob-Manuel Udokwu, àti Kofi Adjorlolo. Wọ́n pinnu láti gbé fíìmù náà jáde ní ọjọ́ kẹrin oṣù Karùn-ún ọdún 2012, [4] ṣùgbọ́n nítorí àríyànjiyàn tó wáyé láàárín olùdarí àti aṣagbátẹrù àgbà lórí aláṣẹ fíìmù náà, wọ́n gbé jáde sórí DVD. Ìbùdó ìyàwòrán fíìmù yìí jẹ́ ìlú Benin, ní ìpínlẹ̀ Edo.[5][6]
Wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ mẹ́wàá ní Africa Movie Academy Awards, ti ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ rẹ̀, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ mẹ́ta níbi ayẹyẹ náà.
Àwọn òṣèrẹ́ tó kópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Olu Jacobs bíi Ezomo
- Bob-Manuel Udokwu
- Kofi Adjorlo
- Ngozi Ezeonu
- Cliff Igbinovia
- Jennifer Iyobosa Olaye - Adesuwa
- Martha Ankomah
Ìtẹ́wọ́gbà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Nollywood Reinvemted fún fíìmù Adesuwa ní 49%; wọ́n gboríyìn fún ìgbéjáde náà, ìdarí rẹ̀ àti jíjẹ́ iṣẹ́ àtinúdá. Ó ní fíìmù náà dùn púpọ̀ àmọ́ kò múni lọ́kàn tó.[7]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Adesuwa set for DVD Release". Archived from the original on 30 November 2012. Retrieved 2 April 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Adesuwa cost me 18 million naira". Nigeria films. Archived from the original on 7 April 2014. Retrieved 2 April 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "An Interview with Adesuwa Executive Producer". NaijaRules. Archived from the original on 7 April 2014. Retrieved 2 April 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Empty citation (help)
- ↑ "Power Tussle over Award winning film Adesuwa". The Nation Newspaper. Retrieved 2 April 2014.
- ↑ "Adesuwa set for Premiere". Nigerian Voice. Retrieved 2 April 2014.
- ↑ "film review: Adesuwa". Nollywood REinvented. 28 January 2013. Retrieved 2 April 2014.