Akin Lewis
Akin Lewis (tí wọ́n bí ní ọdún 1957) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Akin Lewis bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1973.[1][2]
Akin Lewis | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1957 Ibadan, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1973 till;present |
Notable work | Silver Lining (2012) Heroes and Zeroes (2010) TinselHotel Majestic, Jemeji, Borokini, Madam Dearest, Mind Bending, Why Worry, Koko Klose, Alantakun, Were Alaso, King of Boys, No Budget, Up North |
Ìgbà èwe àti aáyan rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, Akin Lewis jẹ́ ọmọ bíbí Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìlú [] Zaria]] lókè Ọya ní ìpínlẹ̀ Kaduna ló dàgbà sí. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 1973 ní kété tí ó dara pọ̀ ẹgbẹ́ òṣèré sinimá àgbéléwò tí ọ̀jọ̀gbọ́n Bọ̀dé ṣówándé, gbajúgbajà oǹkọ̀wé àti onítíátà. Eré aláwàdà orí telifísàn tí ìjọba àpapọ̀, Nigeria Television Authority, NTA, kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Why Worry" ló mú un gbajúmọ̀ lọ́dún 1982. Kódà, Akin Lewis gba àmín ẹ̀yẹ lórí rẹ̀ lọ́dún náà. Àwọn eré mìíràn tó tún mú un gbajúmọ̀ ni "Madam Dearest" tí gbajúmọ̀ olùdarí eré sinimá àgbéléwò, Tádé Ògìdán darí lọ́dún 2005. Láti ìgbà náà ni Akin Lewis tí di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà, tí ó sìn tí kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá àgbéléwò. Oríṣiríṣi àmìn ẹ̀yẹ ló sìn ti gba.[4] Lọ́dún díè sẹ́yìn, ilé ẹ̀kọ́ gíga kan, Graig-Phillips College of Technology yan Akin Lewis ni ọ̀gá àgbà ilé ìwé náà tí ó fìkàlẹ̀ sí Maryland, ní ìlú Èkó. Ilé ẹ̀kọ́ Graig-Phillips College of Technology máa ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn nípa ìmọ̀ tuntun lórí fíìmù. [5]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Akin Lewis, Actor, Producer, Nigeria Personality Profiles". Nigeria. Retrieved 2019-12-02.
- ↑ Odunayo, Adams (2015-06-09). "Why I Always Act Rich – Nollywood Actor". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-12-02.
- ↑ "I never forget who I was -Akin Lewis - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2013-12-28. Retrieved 2019-12-02.
- ↑ "Akin Lewis filmography". INSIDENOLLY. Retrieved 2019-12-02.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Popular Actor, Akin Lewis Becomes School Rector". Nigeria Films. 2016-03-25. Retrieved 2019-12-02.