Anecdote
Ìtàn kékeré anecdote[1][2] jẹ́ ìtàn "èyí tí ó ní kókó kan pàtó",[3] èyí tí ó wà láti gbé èrò lórí ẹni, ibi tàbí ohun kan jáde, sí sọ̀rọ̀ kíkún nípasẹ̀ ìtàn kékeré tàbí ṣíṣe ìfìwàwẹ̀dá àbùdá ohun kan pàtó.[4]
Anecdote,èyí tí ń ṣe ìtàn kékeré lè jẹ́ ìtàn lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí èyí tí kò ṣẹlẹ̀;[5] lílo ìtàn kékeré jẹ́ àbùdá kan tó wọ́pọ̀ nínú iṣẹ́ lítíréṣọ̀ [6], pẹ̀lú èyí, ìtàn ẹnu a máa ní àsọdùn àti àsọrégè láti dá àwọn olùgbọ́ lárayá.[7] A máa ń ṣe àgbékalẹ̀ ìtàn kékeré gẹ́gẹ́ bí ìtàn èyí tí ó dálè ìṣẹ̀lẹ̀ kan pàtó, èyí tí ó níṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ibi tí a mọ̀. Nínú ọ̀rọ̀ tí Jürgen Hein sọ, ìtàn kékeré a máa ṣe àgbéjáde "òtítọ́ èyí tí ó yàtọ̀" àti "apá mìíràn tí ó jẹ́mọ ìtàn àtijọ́".[8] Robbins ni ó ṣe àkọsílẹ̀ ìṣe pàtàkì àwùjọ sáyẹ́nsì lórí pé àwọn ìtàn kékeré yìí kò ní oríkì kan pàtó. Ó ṣe àkíyèsí pé ìgbéjáde àwọn ìtàn kékeré wọ̀nyí máa ń tẹ̀lé ìlànà èyí tó jọ àwọṣe àjàkálẹ̀- àrùn àti pé àwọn ìtàn kékeré yìí jẹ́ ìsúnkì ìròyìn lórí ọ̀rọ̀ àwùjọ àti ètò ọ̀rọ̀-ajé èyí tó rójú.[9]

Ìtàn Ọ̀rọ̀ àti Ìlò Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọ̀rọ̀ náà anecdote (nínú Gíríìkì àtijọ́: ἀνέκδοτον túmọ̀ sí "ohun tí a kò tẹ̀jáde", ìtumọ̀ rẹ̀ gangan literally "tí a kò pín") wá láti Procopius ti Caesarea, ẹni tí ó kọ ìtàn ayé Emperor Justinian I (Àdàkọ:Reign). Procopius gbé c. 550 CE iṣẹ́ èyí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Ἀνέκδοτα (Anekdota, jáde, tí wọ́n sì túmọ̀ ni onírúurú ọnà gẹ́gẹ́ bí Unpublished Memoirs tàbí gẹ́gẹ́ bí Secret History), tí àkóónú rẹ̀ jẹ́ àkójọpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kéékèèké láti inú ìtàn ìgbésẹ̀ ayé àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba Byzantine. Díẹ̀ díẹ̀, ọ̀rọ̀ náà "anecdote" di lílò.[10] ni fún ìtàn kékeré tí a lè lò láti fi ṣe ìtẹ́numọ́ tàbí àgbéjáde kókó tí òǹkọ̀wé fẹ́ láti ṣe àgbéjáde rẹ̀.Ní ti Gíríìkì, Estonian, Lithuanian, Bulgarian and Russian humor, ìtàn kékeré yìí túmọ̀ sí ìtàn kúkúrú èyí tí ó ń panilẹ́rìn láì nílò orísun tí ó jẹ́ òótọ́ tàbí tí ó jẹ́mọ ìtàn ìgbésẹ̀ ayé ẹni kénì.
Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀rí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹ̀rí ìtàn kékeré yìí jẹ́ ìròyìn tàbí àkọ́ọ́lẹ̀ àgbẹfẹ̀ ti ẹ̀rí kan ní ìlànà ìtàn kékeré. A máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi takò ẹ̀rí sáyẹ́nsì, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí a kò lè ṣe ìwádìí rẹ̀ nípasẹ̀ lílò àwọn ìlànà sáyẹ́nsì. Ìṣòro nínú lílò ẹ̀rí tí ìtàn kékeré ni pé kò ṣeé ṣe láti lò fún aṣojú; ẹ̀rí tí ó níṣe pẹ̀lú òǹkà nìkan ni a lè lò láti fi ṣe aṣojú ohun kan. A ka lílò ẹ̀rí ìtàn kékeré nílòkúlò bíi ìró.
Nígbà tí a bá lò ó nínú ìpolówó tàbí láti fi gbé ọjà, iṣẹ́ tàbí èrò kan lárugẹ, ìjẹ́risí ni a sábà máa ń pe ẹ̀rí ìtàn kékeré. A lè lo ọ̀rọ̀ náà ní ilé ẹjọ́, nígbà mìíràn, láti fi ṣàlàyé onírúurú ẹ̀rí. Àwọn sakọ́lọ́gísítì ti ṣàkíyèsí pé ó ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti rántí àwọn àpẹẹrẹ èyí tó làmìlaka ju èyí tó ń ṣe aṣojú lọ. [11]
Àwọn Ìtọ́kási
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Cuddon, J. A. (1992). Penguin Dictionary of Literary Terms and Literary Theory Third Ed.. London: Penguin Books. pp. 42.
- ↑ Oxford Dictionary's definition of an anecdote
- ↑ Epstein 1989, pp. xix
- ↑ Epstein, Lawrence (1989). A Treasury of Jewish Anecdotes. Northvale, NJ: Jason Aronson. pp. xix. ISBN 9780876688908. https://archive.org/details/treasuryofjewish00epst.
- ↑ Kennedy, X. J. (2005). Handbook of Literary Terms, Third Ed.. Upper Saddle River, NJ: Pearson Education. pp. 8.
- ↑ Cuddon 1992, p. 42
- ↑ Knörrich, Otto (1981). "Die Anekdote". Formen der Literatur in Einzeldarstellungen. Stuttgart: Alfred Kröner. pp. 15.
- ↑ Hein 1981, p. 15
- ↑ Robbins, Hollis. "Anecdotal Value in the Age of AI". Anecdotal Value. Substack. Retrieved 16 December 2024.
- ↑ Ibi àkọ́kọ́ tí wọ́n ti lò lédè Gẹ̀ẹ́sì, ní ọdún 1676 (OED).
- ↑ Graesser, A.C.; Hauft-Smith, K.; Cohen, A.D.; Pyles, L.D. (1980). "Structural Components of Reading Time". Journal of Verbal Learning and Verbal Behavior 19 (2): 135–51. doi:10.1016/S0022-5371(80)90132-2.