Jump to content

Ayẹyẹ Odún Sango

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

  

Àwọn olùpèsè oúnjẹ ní agbègbè kan ń se oúnjẹ Amala (oúnjẹ tí a fi ìyẹ̀fun iṣu ṣe) ní ìlú Oyo, Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà nígbà ayẹyẹ Sango ní Ìlú Oyo.

Ọdún Ṣàngó jẹ́ ayẹyẹ olódọọdún tí àwọn ará Yorùbá máa ń ṣe láti fi bu ọlá fún Sango, òrìṣà ààrá àti iná tí ó jẹ́ jagunjagun àti ọba kẹta ti Ilẹ̀ọba Oyo lẹ́yìn tí ó gba ipò Ajaka ẹ̀gbọ́n rẹ̀. [1] Ìjọba Ìpínlẹ̀ Oyo yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ayẹyẹ Sango Àgbáyé ní ọdún 2013, ayẹyẹ náà sábà máa ń wáyé ní oṣù kẹjọ ní ààfin Alaafin ti Oyo, wọ́n sì tún máa ń ṣe é ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ogójì kárí ayé.

A le tọpasẹ ayẹyẹ Sango pada si nkan bí ẹgbẹrun ọdun sẹyin lẹhin ti Sango, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Yoruba olókìkí tí gbogbo ènìyàn si gbàgbọ́ pé òun ni ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí Baba nla àwọn ènìyàn Oyo .

Sango jẹ́ ọba alágbára àti onídán tí ó di ọba Ilẹ̀ọba Oyo lẹ́yìn tí ó gba ipò ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tí wọ́n gbàgbó wípé kò ní “akíkanjú”. Wọ́n gbàgbọ́ pé Sango mú ìlọsíwájú bá àwọn ènìyàn Ilẹ̀ọba Oyo nígbà ìjọba rẹ̀, lèyí tí ikú Ṣágo si ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtàn àròsọ lólókan-o-jòkan. Iṣé ijọba rẹ̀ parí nítorí ìparun ààfin rẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀ nípasẹ̀ ààrá. [2] Ìtàn sọ pé Sango jọba fún ọdún méje péré gẹ́gẹ́ bí ọba ní ìlú Oyo ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú ìdarí alágbára bẹ́ẹ̀, wọ́n kà á sí Ọba tó dára jùlọ nínú ìtàn àwọn ọba Oyo. [3] Nígbà ayẹyẹ ọdún 2021, àwọn Ayaba, ìyẹn ìyàwó Ọba, ń fọ́nnu nípa bí wọ́n ṣe dá òjò dúró kí ó má rọ̀, èyí tí yóò ti da ayẹyẹ náà rú lẹ́yìn tí wọ́n bá àwọn Yemoja àti atókùn Sango sọ̀rọ̀. Bákan náà, wọ́n sọ pé ayẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Iwure Agba tí ó túmọ̀ sí àdúrà àwọn àgbà tí atókùn Sango sábà máa ń darí.

Láti ìgbà tí wọ́n ti yí orúkọ padà ní ọdún 2013, ayẹyẹ náà tí wọ́n sábà máa ń ṣe ní oṣù kẹjọ, tí ó sì máa ń wáyé fún ọ̀sẹ̀ kan, ó máa ń fa àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (20,000) kárí ayé, títí dé àwọn ìlú bi Brazil, Cuba, Trinidad àti Tobago àti Caribbean . Ayẹyẹ náà tí UNESCO Jàn Ní òntè, ni a ṣètò láti mú kí àwọn ọmọ Yorùbá tó wà ní òkèèrè padà sílé, àti láti ṣe ayẹyẹ Sango, ẹni tí wọ́n kà sí akọni tó dára jùlọ nínú ìtàn ẹ̀yà Yorùbá. [4]

Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ayẹyẹ Sango

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ayẹyẹ Sango jẹ́ ayẹyẹ olójó mẹ́wàá, tí ó kún fún igbe lárugẹ aṣa ati ise to tún kún fún ayò àti oge, lèyí tí ó ṣe rí ní ojú àwọn olùjọsìn àti àwọn àlejò tí wọ́n wà wo ìran ayẹyẹ Odún na. A sábà máa ń fi aṣọ funfun tàbí pupa ṣe ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùjọ́sìn. Díẹ̀ lára àwọn ètò tí a ṣètò fún ayẹyẹ náà ni: ìdíje Ayo, ọjọ́ Ogun Ajobo, ọjọ́ Oya, ọjọ́ Aje Oloja, ọjọ́ Iyemoja, ọjọ́ Esin Elejo àti ọjọ́ Sango Oyo. [1]

Àwọn ìwé fún ẹni tó bá fẹ́ kà síwájú síi

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1 2 Oluseye Ojo (2 October 2014). "Magic, thunder as tourists storm Oyo for Sango festival". The Sun. Archived from the original on 26 August 2015. https://web.archive.org/web/20150826211223/http://sunnewsonline.com/new/magic-thunder-tourists-storm-oyo-sango-festival/. Retrieved 10 August 2015. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; name ":0" defined multiple times with different content.
  2. ↑ (in en-US) The History of the Yorubas: From the Earliest Times to the Beginning of the British Protectorate. 2010-09-30. https://books.google.com/books?id=7XSiGw4_qlAC.
  3. ↑ Empty citation (help)
  4. ↑ "The world hails Sango festival". 3 September 2013. http://www.thenationonlineng.net/the-world-hails-sango-festival/.