Ayo Ayoola-Amale

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ayo Ayoola-Amale
Ayo Ayoola-Amale (oṣù kọkànlá ọdun 2011)
Ọjọ́ìbíAdebisi Ayo Adekeye
Ìlú Jos, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèỌmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Iṣẹ́Conflict resolution professional, ombudsman, poet

Ayo Ayoola-Amale jẹ́ Akéwì àti Agbẹjọ́rò ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ìpìlẹ̀ àti Ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Ayo Ayoola-Amale sí Ìlú Jos, Nàìjíríà.

Ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ peace movement[1] nígbà tí ó sì jẹ́ ọmọdé, ó sì di adarí ẹgbẹ Rotaract club àti Girls Guide nígbà tí ó sì jé ọ̀dọ́ ọmọbìnrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ obìnrin tí wọ́n dá kalẹ̀ nígbà náà jẹ́ ẹgbẹ́ tí wọ́n dá kalẹ̀ láti takò rírẹ́ àwọn obìnrin jẹ àti láti tako àwọn ìwà àìtọ́ míràn sí obìnrin. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ Rotary Club àti Women In Nigeria(WIN).

Bàbá rẹ̀, ẹni tí ó kàwé gboyè ní Yunifásitì ti London, jẹ́ agbẹjọ́rò àti òṣìṣẹ́ elétò àbọ̀ National Security Adviser, ẹni tí ó ń gba igbá kejì ààrẹ ní ìyànjú lórí ọ̀rọ̀ ètò àbò àti alága State Security Service. Ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹyẹ, pẹ̀lú àwọn ẹyẹ míràn láti orílẹ̀-èdè Amerika.[2] Ìyá Ayo jẹ́ ọmọ ọba, iṣẹ́ òwò sì ni ó ń ṣe.

Ó lọ ilé ìwé St Louis Secondary School, Bompai, ní Ìpínlè Kano fún ẹ̀kọ́ primari rẹ̀

Ó padà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmò òfin ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awolowo, wọ́n sì pé sínú iṣẹ́ òfin ní 1993. Ó padà tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Yunifásitì ìlú Èkó àti Yunifásitì ti Ghana.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Ayo Ayoola-Amale" (in en-US). Women in Peace. https://www.womeninpeace.org/a-names/2017/4/19/ayo-ayoola-amale. 
  2. Thailand), IEEE International Conference on Advanced Computational Intelligence (8th : 2016 : Chiang Mai (30 November 2017). 2016 Eighth International Conference on Advanced Computational Intelligence (ICACI) : 14-16 Feb. 2016.. ISBN 9781522530336. OCLC 956658431. http://worldcat.org/oclc/956658431.