Bí COVID-19 ṣe rápálá wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Bí COVID-19 ṣe rápálá wọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò ṣẹ̀yìn àrè kan láti ìlú Milan lórílẹ̀-èdè Italy tí ó wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún 2020. [1] [2]

Ìròyìn sọ wípé, àrè náà, ti wọn kò dárúkọ rẹ̀, rìnrìn àjò wá láti orílẹ̀-èdè Italy sí ilé-iṣẹ́ Lafarge, tí ó ń ṣe sìmẹ́ńtì ní Ewékorò, Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn láti wá ṣe àyẹ̀wò àwọn irinṣẹ́ tuntun kan tí ilé-iṣẹ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ rà láti orílẹ̀-èdè Sweden. [3] Ní kété tí ó wọ Nàìjíríà, kò pẹ́ kò jìnnà, tí àwọn àmìn ìfarahàn Covid-19 bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ̀yọ ní lára rẹ̀ ni àwọn elétò ìlera tí Ìjọba Àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ Èkó tá jìgí, tí wọn sìn mú un lọ sílé ìwòsàn ìyà sọ́tọ̀ tí wọ́n ti pèsè sílẹ̀ ní Yaba, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ibẹ̀ ni wọ́n tí ń tójú rẹ̀.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Nigeria confirms first coronavirus case". BBC News. 2020-02-28. Retrieved 2020-03-14. 
  2. "Nigeria Responds to First Coronavirus Case in Sub-Saharan Africa - The New York Times". Google. 2020-02-28. Retrieved 2020-03-14. 
  3. "Why we invited Italian who brought coronavirus to Nigeria – Lafarge". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-03-14.