Jump to content

Boohle

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Boohle
Orúkọ àbísọBuhlebevangeli Hlengiwe Manyathi
Wọ́n tún mọ̀ọ́ bíiboohle
Ọjọ́ìbí20 February 1999 (age 25)
Vosloorus, Gauteng, South Africa
Ìbẹ̀rẹ̀South Africa
Irú orin
Occupation(s)Singer
InstrumentsVocals
Years active2016–present
Labels2020

Buhlebevangeli Hlengiwe Manyathi, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Boohle, jẹ́ olórin ilẹ̀ South Africa àti agbórinkalẹ̀. Ó gbajúmọ̀ fún àwọn orin rẹ̀, bí i "Yini Na", "Mama", "Siyathandana" àti "Hamba wena". Orin rè jẹ́ àhunpọ̀ amapiano, afro-house, afro-soul, àti orin ẹ̀mí.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Vosloorus ni wọ́n bí i sí, ní Gauteng ní ọdún 1999, níbi tí ó dàgbà sí, tí ó sì lọ sí ilé-ìwé girama Lethulwazi.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ ní ọdún 2016 níbi tí òun àti àwọn àbúrò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin ẹ̀mí pọ̀.[3]

Ní oṣù keje, ọdún 2020, ó ṣe àgbéjáde Izibongo, èyí tó jẹ́ àwo olórin mẹ́jọ, níbi tí ó ti ṣàfihàn àwọn ọ̀jẹ̀ nínú ìgbé-orin-jáde, bí i Tee-Jay àti Elastic. Ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú JazziDisciples, Nonny D àti DJ Stokie. Ní oṣù kẹwàá ọdún 2020, ó ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Josiah De Disciple lórí àwo orin olórin mẹ́wàá tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Umbuso Wabam’nyama. Lára àwọn olórin tí wọ́n ṣàfihàn nínú àwò orin náà ni Le Sax, Chelete àti Mogomotsi Chosen.[4]

Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹjọ ọdún 2021, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí i Olórin tuntun ọdún náà ní African Social Entertainment Awards.[5]

Orin àdákọ rẹ̀, ìyẹn “Ngixolele” èyí tí Busta 929 tí ó jẹ́ agbé orin amapiano jáde ṣiṣẹ́ lórí, jẹ́ èyí tí ó rókè nínú àtẹ The Official South African Charts. Orin àdákọ náà jẹ́ èyí tí àwọn ènìyàn tó ń lọ bí i 778 200 gbọ́, káàkiri ìkànni ìgbórin bí i Spotify, Apple Music àti Deezer.[6][7]

Ní oṣù kọkànlá oṣù 2021, ó gba àmì-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí i òǹkọ-orin amapiano tuntun àti òǹkọ-orin amapiano lóbìnrin tó dára jù lọ ní South African Amapiano Awards.[8]

Láti ọdún 2023– Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí: Umhlobo

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ ogún oṣù Karùn-ún, ó ṣe ìkéde àwo-orin ẹlẹ́ẹ̀kẹta rẹ̀, ìyẹn Umhlobo.[9] Àwọn orin àdákọ méjì, tí àkọ́lé wọn ń jẹ́ Two "Mhlobo Wami" àti "Nakindaba Zakho" ni ó gbé jáde ní oṣù Karùn-ún ọdún 2024.[10]

Ó ṣe àgbéjáde orin náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Kẹfà ọdún 2024. [11]

Àtòjọ orin rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwo-orin inú studio

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Izibongo (2020)
  • iSlomo (2022)
  • Umhlobo (2024)

Àwo-orin alájọṣepọ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Umbuso Wabam' nyama (with Josiah De Desciple) (2020)

Àwọn orin mìíràn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Sfikile (2021)

Gẹ́gẹ́ bí i olórí akọrin

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àtòjọ orin àdákọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí akọrin, pẹ̀lú àṣààyàn ipò wọn lórí àtẹ àti ìwé-ẹ̀rí, pẹ̀lú ọdún tí wọ́n gbé e jáde àti àkọ́lé àwò-orin
Àkọ́lẹ́ Ọdún Ipò lórí àtẹ Àwọn ìwé-ẹ̀rí Àwo-orin
ZA
"Memeza" (featuring ThackzinDJ, TeeJay) 2020 Àdàkọ:Non-album single
"Tata/Iyalila" Izibongo
"Wanna Give it All"
"Buyisa" (Boohle, Josiah De Desciple) Umbuso Wabam' nyama
"Mama" (Boohle, Josiah De Desciple)
"Sizo' phumelela" (Boohle, Josiah De Desciple)
"—" denotes a recording that did not chart or was not released in that territory.

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Ayẹyẹ ìgbà-àmì-ẹ̀yẹ Ẹ̀bùn Èsì
2021 South African Amapiano Awards Best amapiano newcomer Gbàá[12]
Best amapiano female vocalist Gbàá[12]
African Social Entertainment Awards style="background: #FDD; color: black; vertical-align: middle; text-align: center; " class="no table-no2"|Wọ́n pèé[5]
2022 Basadi in Music Awards SAMPRA Artist of the Year Gbàá[13]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Boohle to debut at Bahama Lounge". mmegi.bw. Archived from the original on December 9, 2021. Retrieved 9 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Meet Boohle, the vocalist making people dance right now". news24.com. Archived from the original on December 9, 2021. Retrieved 9 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "The day that changed Boohle’s life forever". chronicle.co.zw. Archived from the original on December 9, 2021. Retrieved 9 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "#TheRadar: Have You Met Genre Bending Vocalist & Songwriter, Boohle?". thesouthafrican.com. Archived from the original on December 10, 2021. Retrieved 8 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. 5.0 5.1 "Boohle Reveals The Nomination She Has Bagged At The African Social Entertainment Awards". thesouthafrican.com. Archived from the original on December 9, 2021. Retrieved 8 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Busta 929 surges to the top of RiSA's new charts". thesouthafrican.com. Archived from the original on December 9, 2021. Retrieved 8 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. Ndlovu, Zonke (2024-05-23). "Boohle Releases ‘Mhlobo Wami’ & ‘Nakindaba Zakho’ From Upcoming Album". Metrobaze (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2024-05-23. Retrieved 2024-05-23. 
  8. "Soulful songstress Boohle wins big at inaugural Amapiano Awards [photos]". thesouthafrican.com. Archived from the original on December 9, 2021. Retrieved 8 December 2021.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. Moloi, Atlehang (2024-05-20). "Boohle Announces Upcoming Album ‘Umhlobo’ | Slikouronlife". Slikouronlife. Retrieved 2024-05-23. 
  10. Shumba, Ano (2024-10-22). "SA: Boohle shares two singles ahead of new album | Music In Africa". Music in Africa. Retrieved 2024-05-23. 
  11. Moganedi, Kgomotso (2024-06-14). "Boohle's newest album symbolises strength, appreciation and love". Tshisa LIVE. Retrieved 2024-07-11. 
  12. 12.0 12.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :12
  13. Shumba, Ano (October 15, 2022). "Basadi in Music Awards 2022: All the winners". Music in Africa. Archived from the original on October 16, 2022. Retrieved 2022-10-18.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)