D. O. Fagunwa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Chief
Daniel Ọlọ́runfẹ́mi Fágúnwà
Ọjọ́ ìbíDaniel Oròwọlé Fágúnwà
Àdàkọ:Birth year
Oke-Igbo, Nigeria
Ọjọ́ aláìsíDecember 7, 1963(1963-12-07) (ọmọ ọdún 59–60)
Bida, Nigeria
Resting placeOke-Igbo, Nigeria
Iṣẹ́Olùkọ́ èdè Yorùbá ati ònkọ̀wé ìtàn àròsọ
ÈdèYorùbá
Ìgbà1930–1963
GenreÌtàn Àròsọ (prose)
Notable worksÒgbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀ ní ọdún 1938; Igbó Olódùmarè in 1949; Ìrèké Oníbùdó ọdún 1949; Ìrìnkérindò nínú Igbó Elégbèje ọdún 1954 Àdìtú Olódùmarè ọdún 1961
SpouseChief Elizabeth Adébánkẹ Fágúnwà (1932–2018)

Olóyè Daniel Oròwọlé Ọlórunfẹ́mi Fágúnwà MBE (1903 – 7 December 1963), tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí D. O. Fágúnwà, Ó jẹ́ ògúná gbòngbò tí dá ìtàn àròsọ ní èdè Yorùbá sílẹ̀, ati olùkọ́ èdè Yorùbá nígbà ayé rẹ̀..[1]

Ìgbé ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Fágúnwà ní ìlú Òkè-Ìgbò, ní Ìpínlẹ̀ Òndó. Bàbá rẹ̀ ni ọ̀gbẹ́ni Joshua Akíntúndé Fágúnwà nígbà tí ìyá rẹ ń jẹ́ Rachel Òṣunyọmí Fágúnwà.[2] Bàbá bàbá re ni Fáníyì Arójò, tí ó jẹ́ jagun-jagun. Ọmọ ọmọ Fa ni yi yí ni Égúnṣọlá Asungaga Bèyíokú, tí ó jẹ́ adífálà ní ìlú Origbo, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìlú Ipetumodu. Nígbà tí Ìyá ìyá rẹ̀ ń jẹ Ṣayọadé Olówu, tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ọmọ bíbí Òwú ṣáájú kí wọ́n tí gbéra lọ sí ìlú Abẹ́òkúta. Asungaga yí ni ó kò lọ sí ìlú Ilé-Ifẹ̀ látàrí bí Àbíkú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé òun gan gan fúnra rẹ̀ náà jẹ́ Àbíkú . Nígbà tí ó dé ìlú Ilé-Ifẹ̀ ní àárín ọdún 1870,Ó di Oníṣègù àti Babaláwo fún Ọba Ọọ̀ni ti Ilé-Ifẹ̀ Ọlọ́gbẹ́nlá. Kẹ́yìn tí ogun Ifẹ́ ati Òndó parí, púpọ̀ nínú àwọn jagun-jagun ni wọ́n pàgọ́ sí Abúlé kan tí wọ́n ń pè ní "Oko-igbó" tí ó di Òkè-Ìgbò nísìín. Asungaga bí ọmọ padà bí ọmọ mẹ́rin tí wọ́n gbẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ni: Ifatosa, Akintunde Fagunwa ( tí ó padà yí orúkọ rẹ̀ padà sí Joshua), Ifabunmi àti "Philip" Odugbemi.

Àwọn òbí Fágúnwà mú àṣà àti ìṣe Yorùbá ṣáájú kí wọ́n tó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sì Krìstẹ́nì láàrín ọdún 1910 sí ọdún 1920. Orúkọ abísọ rẹ̀ ni Oròwọlé tí ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ọláọ́runfẹ́mi nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ yí sí ẹ̀sìn Krìstẹ́nì. [3]. Òun nìkan ni ọmọ ọkùrin tí tó kẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀ pẹ̀lú obìnrin mẹ́ta.

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fágúnwà kẹ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ St. Luke's School,Òkè-Ìgbò, ati ilé-ẹ̀kọ́ St. Andrew's College, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣáájú kí ó tó di olùkọ́. [4]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oniọ̀wé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fágúnwà kópa nínú ìdíje tí Ministry of Education gbé kalẹ̀ ní ọdún 1938, ìdíje yí ni ó fàá tí ó fi kọ ìwé ìtàn àròsọ ọlọ́rọ̀ geere Ògbójú Ọdẹ nínú Igbó Irúnmọlẹ̀, [5]. Ìwé yí ni wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé òun ni ìwé ìtàn àròsọ ọlọ́rọ̀ geere akọ́kọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ní èdè Yorùbá , ati ìwé ìwé ìtàn àròsọ ọlọ́rọ̀ geere anọ́kọ́ ní èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká ṣe ògbufọ̀ ìwé yí sí èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ọdún 1968, tí ó pe ní The Forest of A Thousand Demons,ìwé tí wọ́n gbé jáde láti ọwọ́ ilé-iṣẹ́ itẹ̀wé Random House àti City Lights ní ọdún 2013 (ISBN 9780872866300). Lára àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ Fágúnwà tún ni: Igbó Elédùmarè (The Forest of God, 1949), Ìrèké Oníbùdó (1949), Ìrìnkèrindò nínú Igbó Elégbèje (Expedition to the Mount of Thought, 1954), àti Àdìtú Olódùmarè (1961).[6]

Àwọn ìwé ìtàn àròsọ Fágúnwà ni wọ́n da lórí alọ́ onítàn tí ó ń fi ọgbọ́n, ìmọ̀, àṣà, àti agbára ìṣẹ̀mbáyé Yorùbá. Àwọn ẹ̀dá ìtàn inú ìwé rẹ̀ ma ń sábà jẹ́ ọdẹ ni ó ma ń ṣàfihàn wọn bí wọ́n ṣe ma ń bá àwọn irúmọlẹ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn ìwé rẹ̀ tún ṣe ìyàtọ̀ láàrín ẹ̀sìn ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn Krìstẹ́nì tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn mú wọ ilẹ̀ Adúláwọ̀. Àwọn ìwé Fágúnwà ni àwọn ìwé ìtàn àròsọ tí ó gbajúmọ̀ tí àwọn ènìyàn sì ń kà jùlọ, tí iṣẹ́ rẹ̀ ó sì tún jẹ́ ìwúrí fún àwọn ònkọ̀wé bíi Amos Tutuola.[7][8] Fágúnwà tún lo ọgbọ́n ìsọ̀tàn Shakespeare nínú ìwé rẹ̀ tí ó pe anọ́lé rẹ̀ ní Igbó Olódùmarè, níbi tí ó ti lo Bàbá onírùngbọ̀-yẹukẹ láti sọ ìtàn tí ó jọ mọ́ ìtàn ìwé Romeo and Juliet tí Shakespeare kọ. Bákan náà ni Fágúnwà tún jẹ́ ònkọ̀wé ìtàn àròsọ Yorùbá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà akọ́kọ́ tí yóò lo ìtàn òye sọ ìtàn rẹ̀.

Àwọn amì-ẹ̀yẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n fún Fágúnwà ní amì-ẹ̀yẹ ìdánilọ́lá ti Margaret Wrong Prize í ọdún 1955, bákan náà ni wọ́n tún fun ní amì-ẹ̀yẹ ti Member of the Order of the British Empire (MBE) ní ọdún 1959.

Ikú rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fágúnwà jáde láyé ní ọdún 1963 sínú odò kan nígbà tí ó yọ̀ ṣubú sínú omi, tí ó sì gbìyànjú láti wẹ̀ jáde ṣùgbọ́n ọkọ̀ ojú-omi oni pákó kan tún ṣubú de mọ́lẹ̀ tí kò sì ní agbara láti janpata mọ́ títí ó fi ṣaláìsí. [9][10][11]

Àwọn ohun ìrántí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Fagunwa Memorial High School, wọ́n sì sọ ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Òkè-Igbó ní orúkọ rẹ̀ Fagunwa Grammar School ní ìrántí rẹ̀. Ọmọ rẹ̀ Yéjídé Ògúndípẹ̀ náà ṣe aṣojú ìlú rẹ̀ ní ìjọba ẹsẹ̀ kùkú (councilor) fún Ile Oluji/Okeigbo. Fagunwa day Ayẹyẹ ajọ̀dún tí wọ́n fi ń rántí Fágúnwà tí wọ́n pe ní (Fágúnwà Day) ni àwọn ẹgbẹ́ "Society of Young Nigerian Writers" pẹ̀lú Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Fágúnwà Literary Society àti Ẹgbẹ́ Òdọ́ Oniọ̀wé Èdè Yorùbá gbé kalẹ̀ láti ma fi gbé àwọn ìwé márùn ún lárugẹ.

Àwọn ìwé ìdánilẹkọ̀ọ́ nípa ọnà-èdè Fágúnwà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 • Olaleru, Olanike. "Oral Performance Techniques in the Works of D. O. Fágúnwà." Ibadan Journal of English Studies 7 (2018): 361-374.

Àwọn itọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

 1. "Fagunwa wrote his first novel in the bush". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-06-17. Retrieved 2020-05-24. 
 2. "The Novel of D.O Fagunwa - A commentary by Ayo Bamgbose". www.sunshinenigeria.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-10-27. Retrieved 2020-05-27. 
 3. "D.O. Fagunwa | Nigerian author". Encyclopedia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-27. 
 4. "D.O. Fagunwa | Nigerian author". Encyclopedia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-27. 
 5. "Fagunwa wrote his first novel in the bush". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-06-17. Retrieved 2020-05-27. 
 6. "D. O. Fagunwa". Encyclopædia Britannica. Retrieved 3 January 2012. 
 7. Okpewho, Isidore (1992). African Oral Literature: backgrounds, character, and continuity. Indiana University Press. p. 305. ISBN 0-253-34167-1. 
 8. Gikandi, Simon (2003). Encyclopedia of African Literature. Taylor & Francis. pp. 252–255. ISBN 0-415-23019-5. 
 9. Nigerian Punch newspaper, 12 August 2013 edition.
 10. "Fagunwa wrote his first novel in the bush", Vanguard (Nigeria), 18 June 2016.
 11. "D.O. Fagunwa". www.goodreads.com. Retrieved 2020-05-27. 

Àdàkọ:Authority control
Daniel Ọlọ́runfẹ́mi Fágúnwà tàbí D.O. Fágúnwà (19039 December, 1963) jẹ́ ònkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí ní Òkè-Ìgbò ní ìpínlẹ̀ Òndó. O je Oguna gbongbo Onkowe itan aroso, bakanaa o tun je oluko Ede Yoruba. Awon iwe re olokan-o-jokan lo gun opolopo awon onkowe ile Yoruba lonii ni kese ni eyi ti o mu ilosiwaju ba ede Yoruba lapapo.

Àwọn ìwé tó kọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìkìlọ̀: Bọ́tìnì ìtò àkọ́kọ́ṣe "Fagunwa, Daniel" dípò Bọ́tìnì ìtò àkọ́kọ́ṣe "Fagunwa, Daniel O." tẹ́lẹ̀.