Didake akewi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
   DÍDÁKÉ AKÉWÌ
 Níjó teba rakewi to dake, e maa binu akewi n wi nkan ninu ni
  Nijo teba rakewi ti ko soro, e maa binu akewi n wi nkan ninu ni
  Sugbon talo mohun takewi n ro ninu?
   Talo moro ti nbe nikun omoran?, talo morin takewi fe ko lenu?
   Omi ti ko jagbe loju, o le denu akewi ko dokun, o le denu akewi ko dosa. Efuufu tosi mokun-mosa, o le denu akewi ko ma jooru enu lo.
   Inu akewi gbose, inu akewi gbeewu, inu akewi si gbomi to mo gaara.
   Sugbon lojo teba pade akewi lona to dorikodo ti ko soro, e maa binu, e maa sebaje akewi leyin, akewi n wi nkan ninu ni.