Jump to content

Durbar

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Horseman at Kano Durbar (2006)
Bida Durbar (2001)
Children of Katsina mimicking the Durbar festival with sticks as horses.
Durbar Festival Of Lafia during Salah celebrated 2022

Ayẹyẹ Durbar jẹ́ ayẹyẹ ọdún ọlọ́dọdọdún tí wọ́n fi ù ṣe àfihàn àṣà, ẹ̀sìn tí wón ń ṣenní àwọn agbègbè ilẹ̀ ọya ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láàrín àwọn ẹ̀yà Hausa. Ayẹyẹ yí ìkan gbòógì lára àwọn ayẹyẹ láàrín àwọn ẹ̀yà Hausa tí ó sì ti wà fún àìmọye sẹ́ntúrì sẹ́yìn láti fi ṣàfihàn àṣà, ìṣe àti ìtàn wọn gẹ́gẹ́ bí ìran agbórí ẹṣin jagun ní àwọn apa ilẹ̀ gbígbẹ.

Wọ́n ma ń ṣe ayẹyẹ Durbar ní àwọn ìlú ilẹ̀ Hausa tí wọ́n ṣe pàtàkì bíi Kano, Kastina, ìlú Lafia, Gombe Akko Emirate Sokoto, Zazau ní Ìpínlẹ̀ Zaria , Ìpínlẹ̀ Bauchi , ìlú Bida tí ó fi mọ́ ìlú IlorinÌpínlẹ̀ Kwara.

[1][2] Àwọn ìlú tí wọ́n tí ń j'ọba òní Láwààní yí ni wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ yí lẹ́yìn gbogbo ọdún àwẹ̀ àti lẹ́yìn ọdún iléyá. [3][4] Ní Ìlú Kano, ọdún yí ma ń gbilẹ̀ gidi pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ma ń ṣàfihàn àṣà wọn nipa gígun àti fífi ẹṣin dárà.[5][6]

Wọ́n ma ń bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ọdún náà pẹ̀lú àdúraỌba ài àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ rẹ̀ yóò sì mú ẹ́ṣin gún lẹ́yìn tí wọ́n bá parí àdúra tán, olórin yóò ma kọrin àwọn onílù náà yóò sọ̀pá sílù, àwọn jagujagun á sì gun orí 3ṣin láti máa fi ẹṣjn dárà. Àwọn ènìyàn jànkàn-jànkàn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìlú yóò wálé wá ṣọdun tí wọn yóò si ma kí ọba ní mẹ́sàn án mẹ́wàá. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ Durbar ní nkan bí sẹ́ntúrì mẹ́rìnlá sẹ́yìn ní ìlú Kano tí ó jẹ́ ilẹ̀ Hausa tí ó tobi jùlọ ní aríwá ilẹ̀ Nàìjíríà. Ọjọ́ mẹ́rin ni wọ́n fi ma ń ṣe ayẹyẹ Durbar ní ìlú Kano rí wọn yóò sì ma gun ẹṣin káakiri ìgboro. [7]

Inú oṣù kejìlá ọdún 2024 ni àjọ UNESCO ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ayẹyẹ Durbar gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ohun ina tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́s ẹ́yìn.[8]

Àwọn itọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Temi, Emidun (8 September 2019). "Exploring The Wonders Of Ilorin Durbar Festival". The Guardian Nigeria News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 28 February 2022. 
  2. Jimi (2024-06-12). "Ilorin Durbar targets local, foreign investors for economic boost". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-11-05. 
  3. "A 100-Year-Old Festival of Horse Riding". Folio Nigeria. Retrieved 17 August 2020. 
  4. Tukur, Sani (8 July 2016). "In Kano, a thrilling display of ancient Durbar festival and also used to mark Eid el Fitr". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 25 August 2021. 
  5. "Emir of Kano, Sanusi II rides through Kano during Durbar festival". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-07-07. Retrieved 2023-06-05. 
  6. "Emir of Kano, Sanusi II rides through Kano during Durbar festival". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-07-07. Retrieved 2023-12-11. 
  7. "Kano Durbar Festival: Nigeria's Most Spectacular Horseparade". Google Arts & Culture (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2 August 2021. 
  8. "Eid festivities in north Nigeria make UNESCO heritage list". France 24. 6 December 2024. https://www.france24.com/en/live-news/20241205-eid-festivities-in-north-nigeria-make-unesco-heritage-list.