Ẹ̀gbádò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Egbado)
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

EgbadoÈKA-ÈDÈ ÈGBÁDÒ Èdè Ègbádò jé òkan nínú àwon òpòlopò èdè abínibí tí a lè bá pàdé nínú èdè Yorùbá. Nínú òdè Ègbádò yìí ni a ti rí èdè Ìmèko tí a ń yè wò nínú isé yìí. Èdè Ìmèko yàtò sí èdè Ègbádò yòókù bí ó tilè jé pé orúko kan náà “Ègbádò” ni a fi sa gbogbo won lámì. Èdè Kétu ni Ìmèko ń so, ó sì yàtò sí èdè Ìláròí tàbí Ayétòrò. Àwon onímò èdè kan bí Òmòwé Olásopé Oyèlàràn àti Edward M. Fresco tilè ti gbìyànjú láti fi ìyàtò tó wà láàrín èdè Kétu àti Yorùbá káríayé hàn. A ó sàkíyèsí pé àwon òrò kan wà tí àwon ará àdúgbò tí mo ti se ìwádìí yìí ń so jáde lénu bí èdè Ìmèko sùgbón tó yàtò sí Yorùbá káríayé. Àwon nnkan tó jé ní l’pgún nínú isé yìí ni pé kí n se àlàyé àwon òrò tó lè rú ni lójú nínú èdè Ìmèko. Léhìn ètí, n ó se àfiwó òrò ríè mnínú èdè Ìmèko àti Yorùbá káríayé. Kì í se àlàyé nípa gírámà èdè Ìmèko ni mo féé se níbí yìí nítorí pé eléyìí tó isé mìíràn lótò. Láìfa òrò gùn, ohun tí àlàyé sókí tí mo se nípa èdè Ìmèko nínú isé yìí dúró fún ni láti fún enikéni tí ó bá fé é ka isé yìí ní ìròrùn láti se béè. Bí irú eni béè bá sì se alábàápàdé àwon òrò tó lè mú ìrújú wá, wón lè lo ìtókasí tàbí àlàyé sókí yìí láti fit ú kókó ìrújú náà. Ìyàtò díè wà larin ìlò kóńsónàntì, fáwèlì àti arópò orúko nínú ède Ìmèko àti ti Yorùbá káríayé. Àyèwò ìsàlè yìí yóò ran èyin ònkàwé lówó láti ní òye ohun tí ará Ìmèko ń wí nígbà yówù kí e bá èyíkéyìí nínú àwon nnkan tí mo ménu bá lókè pàdé nínú isé yìí. 

  • G.O. fayomí (1982), ‘Èka-èdè Èbádò’ láti inú ‘Gèlède ní ìlú Ìmèko-Èbàdò kétu.’, Àpilèko fún Oyè Bíeè, DALL, OAU, Ifè, ojú-ìwé xviii-xxiv.