Ewì ajẹmókùú

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Songs

ÌLÒ ORIN[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yorùbá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà tó fẹ́ràn orin púpọ̀. Kò sí abala kan nínú ìgbésí ayé ọmọnìyàn tí a kò ti lè kọrin. A ń kọ orin níbi ìgbeyàwó, à ń kọ orin nígbà tí a bá bímọ, nígbà ìsìnkú àgbà, orin wà láti yin Olódùmarè bẹ́ẹ̀ ni orin wà láti fi àseyọrí tàbí kù dìẹ̀ ku diẹ ẹ̀dá hàn. Gbogbo ìwà àti ìṣe Yorùbá ló ní orin tí ó bá wọn mu rẹ́gí yálà nígbà ayọ̀, nígbà ìbànújẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀.

Beier (1956), Olúkòjú (1978), Ọlátúnjí (1984), Ilésanmí (1985), Sheba (1988) àti Agbájé (1995) gbà pé ẹ̀ka pàtàkì ni orin jẹ́ nínú lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá. Bí àwọn orin yìí ṣe ń jẹyọ ni wọ́n ní iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ewì ajẹmókùú láàrin àwọn Ẹ̀gbá àti Ìjẹbú. Bí àpẹẹrẹ:

E è yà

Mo r’Ògùn la fọṣọ

E è o yà

Mo r’Ògùn la fọṣọ

Ìgbì mo délé o mi o bá baba

Ojú mi n ṣomi gbéré

(Àsomọ́ III; o.i. 185, ewì 10, ìlà 42-47)

Ọ̀nà tí akéwì gbà lo orin òkè yìí bu ẹwà kún ìgbálá tó sín. Akéwì lo orin yìí láti pe ọkàn àwọn olùgbọ́ wá sílé. Bákan náà, nínú ewì ajẹmókùú láàrin àwọn Ẹ̀gbá àti Ìjẹ̀bú a lè rí àpẹẹrẹ ìlò orin mìíràn:

Èrò sọ́run làwa ńṣe

Ayé làjò

Ọ̀run nilée wa

(Àsomọ́ III; o.i. 169, ewì 7, ìlà 1-3)

Nínú àpẹẹrẹ òkè yìí, akéwì lo irúfẹ́ orin yìí láti síde ègè dídá rẹ̀. Pàápàá jùlọ láti pèsè ọkàn àwọn olùgbọ́ sílẹ̀ nípa àkóónú ègè rẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ orin tí a rí tọ́ka sí nínú ewì ajẹmókùú láàrin àwọn Ẹ̀gbá àti Ìjẹ̀bú ni ìwọ̀nyí:

Lílé: Àwa náà yóò jẹun ọmọ

Ègbè: Gbogbo wa náà ni ó jẹun ọmọ

Lílé: Bénìyàn bímọ tí ò bà tètè kú,

A jẹun ọmọ

Ègbè: Àwa náà á jẹun ọmọ

(Àsomọ́ IVI; o.i. 208, ewì 2, ìlà 390-394)

Bóbà sèyá ẹlòmíràn ló kú

Wọn a ṣe yẹ̀yẹ́ ẹ

Wọn a dákẹ́ o

Kí ló pàyá

Omi àjàlolo

(Àsomọ́ III; o.i. 218-219, ewì 3, ìlà 25-29)

Ìwà ti ò tọ́ lolóńgbò ń hù

Ìwà tí ò tọ́ lolóńgbo ń hù

Eku bímọ rẹ̀, olóńgbò ń ko

Ó jásí pé ìwà tí ò tọ

Lọmọdé yẹn ń hù

(Àsomọ́ IV; o.i. 230, ewì 6, ìlà 78-82)

A wá a

Àwa ò ríi o

À ń wá a

Àwa ò rí i o


(Àsomọ́ IV; o.i. 234, ewì 8, ìlà 1-4)

Màmá wa ló mà kú o

Ẹwẹlẹ wẹ̀kú ẹwẹlẹ

Ìyá wa ló mà kù o

Ẹwẹlẹ wẹ̀kú ẹwẹlẹ

(Àsomọ́ IV; o.i. 234, ewì 8, ìlà 11-14)

Ẹkún mo wá sun o

É è àrò mo wá ṣe

Ẹkún mo wá sun

Ẹkún mo wá sun o

Àrò, àrò mo wá ṣe

Àrò, àrò mo wá ṣe

(Àsomọ́ IV; o.i. 234, ewì 8, ìlà 1-6)

iwe ti a yewo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mudasiru Abayomi Kareem

ÌTÚPALẸ̀ EWÌ AJẸMÓKÙÚ LÁÀRIN ÀWỌN Ẹ̀GBÁ ÀTI ÌJẸ̀BÚ


(A CRITICAL APPRAISAL OF FUNERAL DIRGES AMONG THE Ẹ̀GBÁ AND ÌJẸ̀BÚ),

M.A. Thesis, Department of Linguistics and African Languages,

Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Nigeria. (2007).

Dr. J.B. Bode Agbaje (Supervisor)