Fìlà (Gòbì)

Fila gobi jẹ fìlà ìkan lára àṣà ìmúra ti awọn ọmọ Yoruba ti Iwọ-oorun Afirika n dé. [1] Àwon ohun ti afí ń hun ún ni aṣọ òfì, ápósé ,òwú , damasì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Wón ma n sábà fi òwú hun papò ṣugbọn tí wón bá hún fún lílò igbà kan wólè ma fi òwú hú pò
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fìlà wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn Yorùbá ní orílè-èdè Nàìjíríà, àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Áfíríkà mírràn àti àwon ìran Áfíríkà lókùnrin à man n de, fila naa ma n ba ori mu, wón sì ma n sábá ge fìla nà sí ègbé kan tí wón bà wò tán tí yio sì Fi Ara lè ègbé etí ẹni ti o wọ. Ṣugbọn a le ge fìlà náà sí oriṣiriṣi ọna, tàbí láti dá oriṣiriṣi àrà èyí tí ó bá wu eniti o de. Awọn kan sọpe bí aba ge fìlà yìí si ọtun (ọwọ òtún) èyí tumọ si pé Àpòn ni okùnrin tí ó de (eni tí kò ní ìyàwó), nigba ti o bá wà lapa osi (ọwọ òsì) èyí fihàn wípé ọkunrin ti o ni iyawo sílé ni enití ó ge,
ṣùgbọn bi àwon oba tabi awon Bòròkíní (ènìyàn pàtàkì) bá gèé sí ègbé kan ní gbà tí wón bá wà lágbo ka ìtúmò mírràn ni èyí, àwon tí wón bá si jé omo léyìn won náà yio ní bi wón yo se ge tí wón na, Awọn òdó a tẹ tiwọn si iwaju ti o tumọ si pe ojo iwaju jẹ tiwọn awọn agbalagba yóò ge fìlà ti wọn si ẹyìn ti o tumọ si pe akoko wọn suwòn. Aṣa atọwọdọwọ ti o wa ni ìbámu pèlú eléyì ni Bafaria pẹlu sorapo Dirndl .