Fòpin sí SARS

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
End SARS
DateScript error: The module returned a nil value. It is supposed to return an export table.
LocationScript error: The module returned a nil value. It is supposed to return an export table.
Caused byKillings, assaults, and harassment by SARS in Nigeria; social media campaign by Nigerian Twitter community
MethodsProtest, demonstrations, online activism
Parties to the civil conflict
Lead figures
Units involved
Number
Casualties and losses
Casualties
Death(s)12+[1][2]

Fòpin sí SARS tí gbajúmọ̀ ògbufọ̀ rẹ̀ lédè gẹ̀ẹ́sì túmọ̀ sí End SARS, jẹ́ ìfẹ̀hónúhàn àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó bẹ̀rẹ̀ lórí ìtàkùn ayélujára,Twitter láti pe ìjọba àpapọ̀ sí fífòpin sí àkànṣe ẹ̀ka ọlọ́pàá agbóguntolè, Special Anti-Robbery Squad, tí wọ́n fẹ̀tẹ̀ sílẹ̀, tí wọ́n wá ń pa làpálàpá nípa híhalẹ̀ mọ́ àwọn aláìṣẹ̀ àti gbígbógun ti àwọn ará ìlú lọ́nà tó lòdì sí òfin.[3]

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìfẹ̀hónúhàn náà bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpolongo lórí ìkànnì ayélujára Twitter pẹ̀lú àrokò #ENDSARS láti sọ fún Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti fòpin sí àkànṣe ẹ̀ka ọlọ́pàá agbóguntolè, SARS.[4][5][6] Láàárín òpin ọ̀sẹ̀ kan, lọ́jọ́ kẹsàn-án sí kọkànlá oṣù kẹwàá ọdún 2020, (9–11 October 2020), àrokò #ENDSARS ti ní ìpolongo mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n lórí Twitter.[7] Lásìkò yìí, àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe àfihàn àwọn ẹ̀rí àwòrán àti fídíò ìwà àìbófinmu bíi: jíjínigbé, ìpànìyàn, ìfipábánilò', olè jíjà, ìfìyàjẹ aláìṣẹ̀ lọ́nà àìtọ́, títi aláìṣẹ̀ mọ́lé, pípàyàn lọ́nà àìtọ́ àti ìfipágbowó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ̀ka ọlọ́pàá SARS wọ̀nyí ń hù lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A lè rí àwọn fídíò-bóṣeńlọ lórí ìkànnì ayélujára yìí Endsars Archived 2020-12-10 at the Wayback Machine.

Wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá SARS pé, íṣe ni wọ́n dàmú àwọn aráàlú nípa ṣíṣe àyẹ̀wò ìgbónára àìtọ́ fun aráàlú, jíjínigbé, ìpànìyàn, ìfipábánilòpọ̀, olè jíjà, ìfìyàjẹ aláìṣẹ̀ lọ́nà àìtọ́, títi aláìṣẹ̀ mọ́lé, pípàyàn lọ́nà àìtọ́, ìfipágbowó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, híhalẹ̀ àti gbígba owó lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n bá rí nínú ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì, ìdásílẹ̀ ìbùdó àyẹ̀wò àìtọ́, àyẹ̀wò ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, pàápàá jù lọ iPhones.[8] Àwọn kan kéde pé Ìfẹ̀hónúhàn náà tí ṣe àṣeyọrí nígbà tí àwọn aláṣẹ ọlọ́pàá kéde pé wọ́n ti fòpin sí àkànṣe ẹ̀ka ọlọ́pàá SARS lọ́jọ́ kọkànlá oṣù kẹwàá ọdún 2020.[9] Àwọn mìíràn tako èyí, wọ́n sọ pé ìjọba tí ṣe irú ìlérí bẹ́ẹ̀ rí ṣùgbọ́n tó jásí pàbó, tàbí tó jẹ́ pé pàbó ló jásí. [10]

Ìjọba ti gbìyànjú láti fipá dá Ìfẹ̀hónúhàn náà dúró, ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo ìgbìyànjú wọn ń já sí.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Nigeria: attacks on #EndSARS protesters leave 10 dead and hundreds injured". Amnesty International. 15 October 2020. 
  2. Ekene Agbor (17 October 2020). "Two feared killed, scores injured as #EndSARS protest turns bloody in Osogbo". News Boom. 
  3. Kingsley, Omonobi (4 December 2017). "Anti-SARS campaign: IG orders investigation of anti-robbery squad". Vanguard Newspaper (Nigeria). https://www.vanguardngr.com/2017/12/anti-sars-campaign-ig-orders-investigation-anti-robbery-squad/. Retrieved 31 January 2018. 
  4. Salaudeen, Aisha (15 December 2017). "Nigerians want police's SARS force scrapped". Aljazeera. http://www.aljazeera.com/news/2017/12/nigerians-demand-police-sars-unit-171215153831230.html. Retrieved 2 January 2018. 
  5. "End SARS as a Mob Project". Nigeria: Thisday Newspapers Limited. 17 December 2017. https://www.thisdaylive.com/index.php/2017/12/17/end-sars-as-a-mob-project/. Retrieved 2 January 2018. 
  6. Ogundipe, Samuel (December 3, 2017). "#EndSARS: Police mum as Nigerians recount atrocities of Special Anti-Robbery Squad". Nigeria: Premium Times. https://www.premiumtimesng.com/news/headlines/251271-endsars-police-mum-nigerians-recount-atrocities-special-anti-robbery-squad.html. Retrieved 2 January 2018. 
  7. Kazeem, Yomi. "How a youth-led digital movement is driving Nigeria's largest protests in a decade". Quartz Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-10-13. 
  8. Kazeem, Yomi. "Young Nigerians are leading protests yet again to disband a rogue police unit". Quartz Africa (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-10-10. 
  9. "#EndSARS: Nigeria says Special Anti-Robbery Squad dissolved". Al Jazeera. 11 October 2020. Retrieved 11 October 2020. 
  10. Ademoroti, Niyi (11 October 2020). "What It Means When the Police Say They are Dissolving SARS". BellaNaija. Retrieved 11 October 2020.