Fatima Faloye

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Fatima Faloye tí wọ́n bí ní agbègbè Harlem ní ìlú New York jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Bárbádọ̀s. Ó kọ́ ẹ̀kọ́ ní ilé-ìwé Dalton School ní ìlú New York àti ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York University. Faloye gba àmì-ẹ̀yẹ ti NAACP Image Award for Outstanding Supporting Actress in a Drama Series ní ọdún 1996 fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Chantel Tierney nínu eré New York Undercover.[1] Faloye tún ti ní àwọn ipa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Law & Order. Ó tún ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ olùgbéréjáde tó sì ti gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù oníṣókí kan jáde.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "'Waiting to Exhale' wins big at Image awards." Jet 89(24), 29 April 1996. pp. 58-62.