Federal University of Agriculture, Abeokuta

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Federal University Of Agriculture, Abeokuta.
FUNAAB_Logo.jpg
Motto Knowledge For Development.
Established 1 January 1988
Type Public research university
Vice-Chancellor Professor Felix Salako[1]
Academic staff 529
Admin. staff 1,447
Students 2,538
Undergraduates 15,095
Postgraduates 1,640
Location Abeokuta, Ogun State, Nigeria
Campus Rural
Colors Green
    
Nickname Funaabites
Affiliations ACU, AAU, NUC
Website www.unaab.edu.ng

Yunifasiti eko ogbin ti ijoba apapo, Abeokuta (FUNAAB)[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Itan-akọọlẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn ti ìjoba àpapọ̀ ti o wa ni ìlú Abeokuta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni ìjoba àpapọ̀ da silẹ̀ ni ọjọ́ kini oṣù kini ọdún 1988 (1 January 1988). Ìjọba àpapọ̀ pa yunifásítì ìmọ̀ ẹrọ mẹrin papọ̀ mo awọn yunifásítì mẹrin miran ni ọduń 1984 ki o to di wipe wọ́n ni ki wọ́n da dúró. Eléyì ló fa ìdásílẹ̀ yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn méjì, ọ̀kan si ìlú Abeokuta ati èkejì sí ìlú Mákúrdi.

Ni ọjọ́ kan naa yi ni ìjọba yan ọ̀jọ̀gbọ́n Nurudeen Olorun-Nimbe Adedipe gẹ́gẹ́ bi igbákejì alásẹ àkọ́kọ́ ti yunifásítì ẹ̀kọ́ ọ̀gbìn Abeokuta. Ọ̀jọ̀gbọ́n Adedipe dáwọ́lé isẹ́ ni perewu labe ase ni ojo kejidin-logbon osu kinni odun 1988 (28 January 1988). Fun opolopo odun ni won ti sesi gba ojo ti ojogbon Adedipe dawole ise gege bi ojo idasile. Nigbati ti won se atunyewo si ofin ti o da yeunifasiti yi sile, ajo igbimo se ipinnu ninu ipade ketale-laadota re (53 statutory council meeting) ni osu kefa odun 2010 (June 2010) da ojo idasile pada si ojo kinni osu kinni odun 1988 (1 January 1988) gege bi ofin ti o da Yunifasiti eko ogbin yi se laa sile.

Ki o to di wipe yunifasiti eko ogbin Abeokuta (FUNAAB) waye, ijoba ti koko se idasile ile- eko giga ti imo ero, Abeokuta ni odun 1983. Sugbon nigba ti o di odun 1984 ni ijoba pa ile eko giga yi po mo Yunifasiti eko (University of Lagos) ti won si yi oruko re pada si ile-iwe giga ti eko ijinle ati ti imo ero ti ilu Abeokuta (College of Science and Technology, Abeokuta) (COSTAB) ki o to di wipe o da duro ni osu kini odun 1988.

Ile-eko giga Yunifasiti yi bere ise ikeko ni gbongan ile-iwe Abeokuta girama ti atijo ti o wa ni igboro isale-igbehin. Yunifasiti yi pari isipo pada re lo si ibi ti yoo wa titi laiyese ni opopona Alabata ni odun 1997.

Ni ibere pepe, eka ikeko marun-un ni won koko fi lele ni yunifasiti yi ni osu kewa odun 1988.

  • http://punchng.com/funaab-gets-new-vc/