Funfun
Funfun ni Àwọ̀ tí ó mọ́lẹ̀ jù lọ.[1] Ó jẹ́ àwọ̀ aláìní-chroma, ìyẹn ni pé kò ní ìkúnrẹ́rẹ́ Àwọ̀. A máa ń rí àwọ̀ funfun nínú àwọn ohun bí yìnyín, ẹfun, àti wàrà, ó sì jẹ́ àwọ̀ tí ó lòdì sí dúdú. Àwọn ohun tí ó jẹ́ funfun máa ń fàya tàbí tú ká gbogbo ìgbi ìmọ́lẹ̀ tí ojú ènìyàn lè rí, tàbí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ pátápátá. Lórí tẹlifíṣọ̀n àti ojú-iboju kọ̀ǹpútà, a máa ń ṣe àfihàn àwọ̀ funfun nípa dídapọ̀ ìmọ́lẹ̀ pupa, aró (Blue) àti ewé. A tún lè ṣẹ̀dá àwọ̀ funfun nípa lílo pigmenti funfun, pàápàá jù lọ titanium dioxide, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn pigmenti funfun tí a gbajúmọ̀ jù lọ.[2]
Ìtàn àti Ọnà rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kí Àkọsílẹ̀ tó dé àti Ìgbà Ìwáṣẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Funfun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Àwọ̀ àkọ́kọ́ tí àwọn ènìyàn lò nínú iṣẹ́ ọnà. Nínú àwọn ihò inú àpáta Lascaux ní orílẹ̀-èdè Faransé ní àwọn àwòrán màlúù àti àwọn ẹranko mìíràn tí àwọn oníṣẹ́ ọnà àtijọ́ (Paleolithic) yà ní nǹkan bí ọdún 18,000 sí 17,000 sẹ́yìn. Àwọn oníṣẹ́ ọnà àtijọ́ máa ń lo kaĺsáítì (calcite) tàbí ẹfun (chalk), nígbà mìíràn gẹ́gẹ́ bí àlẹ̀yìn àwòrán, nígbà mìíràn sì rèé, wọ́n á lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n fi ń ṣàfihàn àwọn apá kan nínú àwòrán. Wọ́n tún máa ń lò èédú àti ọ̀kérè pupa àti òféfèé(red and yellow ochre) nínú àwọn àwòrán inú ihò tí ó ní àwọn Àwọ̀ tí ó mọ́lẹ̀ tí wọ́n yà lọ́nà tó lárinrin.[3][4]
Ìtàn Òde-òní
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- The monks of the order of Saint Benedict (c. 480–542) first dressed in undyed white or gray wool robes, here shown in painting by Sodoma on the life of Saint Benedict (1504). They later changed to black robes, the color of humility and penitence.
- Under Pope Pius V (1504–1572), a former monk of the Dominican Order, white became the official color worn by the Pope.
- The white lamb in the Ghent Altarpiece by Jan van Eyck. (1432)
- The Transfiguration by Fra Angelico (1440–1442)
- Mary Stuart wore white in mourning for her husband, King Francis II of France, who died in 1560.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Are Black and White Colors? | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-07-21.
- ↑ Àdàkọ:Ullmann
- ↑ Pastoureau, Michel (2005). Le petit livre des couleurs, p. 47.
- ↑ "Pigments through the Ages – Prehistory". Archived from the original on 3 October 2018. Retrieved 30 December 2016. Unknown parameter
|url-status=ignored (help)