Funke Egbemode

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Funke Egbemode tí í ṣe ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ akọ̀ròyìn, olùdarí àti aṣàtúnkọ àgbà fún Daily Telegraph Publishing Ltd.[1] Òun sì ni ààrẹ àná fúnNigerian Guild of Editors.[2][3][4]

Ìgbésí ayé àti ètò-èkó rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni a bí Funke sí. Ó bẹ̀rẹ̀ ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Baptist Practising Primary School, ní Iwo ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó sì tún lọ sí Baptist Girls High School ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun bákan náà. Ó gboyè Bachelor’s degree ní Obafemi Awolowo University tó wà ní Ilé-Ifẹ̀ àti post-graduate diploma nínú JournalismNigeria Institute of Journalism tó wà ní ìpínlẹ̀ Èkó.[5]

Iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Funke bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó yàn láàyò gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé ní Prime People magazine. Ó dara pọ̀ mọ́ Punch Newspapers lọ́dún 1993 títí wọ 2000, nígbà tí wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi aṣàtúnkọ fún The Post Express on Saturday. Látìgbà náà ló ti jẹ́ aṣàtúnkọ fún ìwé-ìròyìn ThisDay àti Saturday Independent. Ó jẹ́ aṣàtúnkọ fún ìwé-ìròyìn Sunday Sun nígbà kan rí. Funke jẹ́ akọ̀ròyìn, olùdarí àti aṣàtúnkọ àgbà fún Daily Telegraph Publishing Ltd.[6] Ní ọdún 2006, United States Information Service (USIS) yàn án láti ṣiṣẹ́ lórí U.S. mid-term elections lọ́dún náà. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Federal Radio Corporation of Nigeria (FRCN). Funke Egbemode tó jẹ́ ààrẹ Nigeria Guild of Editors (NGE) ni Commissioner for Information and Civil Orientation ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.[7]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Yes! Dialogue. "Thriving in journalism as a woman – Funke Egbemode + Widowhood is hell". Theyesnigeria. YES!. Retrieved 10 October 2016. 
  2. Akoni, Olasunkanmi; Olowoopejo, Monsuru (May 4, 2019). "Breaking: Funke Egbemode returns as President NGE". Vanguard News. Retrieved May 30, 2022. 
  3. "Latest Nigeria news update". The Nation Newspaper. October 7, 2021. Retrieved May 30, 2022. 
  4. "Your choice of spouse ’ll determine how far you ’ll go—Funke Egbemode, President, Nigeria Guild of Editors » Xquisite » Tribune Online". Tribune Online. 2017-08-12. Retrieved 2020-05-03. 
  5. "Funke Egbemode's schedule for IPI World Congress 2018". IPI World Congress 2018. 2013-12-17. Retrieved 2020-05-03. 
  6. PeoplePill. "Funke Egbemode: Nigerian female journalist - Biography and Life". PeoplePill. Retrieved 2020-05-03. 
  7. Elites, The (2019-10-25). "Funke Egbemode Emerges Osun Commissioner for Information, Oyetola Swears-in 34 Other Aides". The Elites Nigeria. Retrieved 2020-05-03.