Jump to content

Gaba Cannal

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Gaba Cannal
Orúkọ àbísọKhaka Yena
Ọjọ́ìbíDaveyton, South Africa
Ìbẹ̀rẹ̀Eastern Cape, South Africa
Irú orin
Occupation(s)
  • Record producer
  • DJ
InstrumentsPiano, keyboard, vocals
Years active2015–present
LabelsGaba Cannal Music Pty-Ltd
Associated acts

Khaka Yena, tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Gaba Cannal, jẹ́ olórin ilẹ̀ South Africa, agbórinjáde àti DJ. Iṣẹ́ ìgbé orin jáde rẹ̀ gbajúmọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríyá inú rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ Amapiano inú rẹ̀.[1] Orúkọ rẹ̀ "Gaba Cannal" jẹ́ èyí tí wọ́n yàn láti inú èdè Pọ́túgà, tí ó túmọ̀ sí "Let It Be".[2]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Gaba Cannal sí ìlú Daveyton, Gauteng, àmọ́ ó kó lọ sí apá Ìlà-oòrùn ilẹ̀ Johannesburg, níbi tí ó ti parí ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ kí ó tó ṣíde sínú iṣẹ́ orin kíkọ.[3] Ó kékọ̀ọ́ gboyè ní Siyalakha Christian School kí ó tó kó lọ sí apá Ìlà-oòrùn ilẹ̀ Johannesburg, níbi tí ó ti kàwé jáde ní Fumana High School.[4]

Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé orin jáde ní ọmọdún méjìdínlógún, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú jíjẹ́ olùgbé orin hip hop jáde àti atẹ dùrù.[5] Ní ọdún 2014, ó ṣe àgbéjáde orin rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Abundance, èyí tí ó lànà fun nínú iṣẹ́ orin kíkọ. Ọdún kan náà ni ó ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ orin rẹ̀ tí ó sọ ni Gaba Cannal Music Pty-Ltd.[6]

Ní ọdún 2018, Da Kruk ṣàfihàn rẹ̀ nínú orin àdákọ rẹ̀, ìyẹn Magic, èyí tí wọ́n yàn ní 2018 South African Music Awards, fún orin tí ó dára jù lọ ní ọdún náà.[7]

Ní ọdún 2020, ó ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú olórin ilẹ̀ South Africa kan, ìyẹn Busiswa, èyí sì mu gbé orin kan jáde tí ó pè ní Umhlaba Wonke.[8] Ní ọdún kan náà, ó ṣàgbéjáde àwo-orin rẹ̀, Amapiano Legacy.[9] Ní oṣù Kẹjọ ọdún 2020, orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Hold On wà ní ipò kẹwàá lórí àtẹ Good Hope FM's SA House Music Top 10.[10]

Ó ti ṣeré ní orí-ìtàgé pèlú àwọn olórin bí i Vinny Da Vinci, DJ Ganyani, Nastee Nev, DJ Clock, LinQ, MFR Souls, Giggs Superstar, KoJo Akusa, Mzee, Julian Gomes, Javaman, The Brawl, Noxolo, Mobi Dixon, Jenerik Soul, Tim White, DJ Christos, Tokzen Mthi àti DJ Terrance, pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ olórin mìíràn bí i Ralf GUM, Andy Campton àti Nick Holder, tí ó sì ti káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè bí i Eswatini.[11]

Ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2020, ó ṣe ìkéde pé àwò-orin rẹ̀, èyí tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Statement á jáde.[12]

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ọdún Ayẹyẹ ìgbà-àmì-ẹ̀yẹ Ẹ̀bùn Èsì
2018 Dance Music Awards South Africa Best Underground Record of the Year Wọ́n pèé[13]

Àtòjọ orin rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Abundance EP (2014)
  • Between Emotions EP (2018)[14]
  • Injabulo EP (2018)[14]
  • Suit And Tie II EP (2019)[15]
  • Amapiano Love Affair (2020)[16]
  • Amapiano Legacy (2020)[17]
  • Suit & Tie Episode III EP (2020)[18]
  • Great I Am (2020)[19]
  • Visionary Episode 1 (2021)
  • Agape (2022)
  • Deepest Gratitude (2022)
  • Thetha Nabo Mfundisi (2023)[20]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "ICYMI: Gaba Cannal Blurs The Lines Even Further With New Project ‘Amapiano Legacy’". Zkhiphani. Retrieved 27 November 2020. 
  2. "Gaba Cannal with ur #LunchTymMix on BestBeatsTv". bestbeats.tv. Retrieved 27 November 2020. 
  3. "NEW MUSIC ALERT: Gaba Cannal Drops Two EP’s In One Night". Zkhiphani. Retrieved 27 November 2020. 
  4. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :22
  5. "Intoxicating new genre is here to stay". Sowetan Live. Retrieved 27 November 2020. 
  6. "House Music Artist:Gaba Cannal". onenationmusic.com. Archived from the original on 18 May 2019. Retrieved 27 November 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "Black Coffee, Distruction Boyz lead Dance Music Awards nominations". iol.co.za. Retrieved 27 November 2020. 
  8. "Gaba Cannal Enlists Busiswa in New Amapiano Banger ‘Umhlaba Wonke’". Okay Africa. Retrieved 27 November 2020. 
  9. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :12
  10. "SA House Chart". goodhopefm.co.za. Retrieved 27 November 2020. 
  11. "URBAN ENTERTAINMENT TO BRING THREE TOURS IN ESWATINI". Swazi Observer. Retrieved 27 November 2020. 
  12. "GABA CANNAL SHARES UPCOMING "STATEMENT" ALBUM ARTWORK & RELEASE DATE". ubetoo.com. Retrieved 27 November 2020. 
  13. "And The Dance Music Award Nominees Are!". People Magazine. Archived from the original on 29 November 2020. Retrieved 27 November 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  14. 14.0 14.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :32
  15. "Amapiano Aficionado Gaba Cannal Drops A Second Installment Of Suit And Tie EP". Zkhiphani. Retrieved 27 November 2020. 
  16. "Gaba Cannal And Zano Finally Release Their Joined EP Amapiano Love Affair". Zkhiphani. Retrieved 27 November 2020. 
  17. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :13
  18. "GABA CANNAL RELEASES THE "SUIT & TIE EPISODE III" EP". ubetoo.com. Archived from the original on 24 April 2022. Retrieved 27 November 2020. 
  19. "GABA CANNAL PREMIERES GREAT I AM ALBUM". ubetoo.com. Retrieved 27 November 2020. 
  20. "Gaba Cannal Drops New Album ‘Thetha Nabo Mfundisi’". slikouronlife.co.za. Retrieved 5 May 2024.