Iyán
Ìrísí
Iyán jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ ilẹ̀ Yorùbá tó gbajúmọ̀ jùlọ. Iṣu funfun ló dára jù fún iyán gúngún. A lè fi iyán jẹ ọbẹ̀ ẹ̀fọ́, ẹ̀gúsí tàbí ilá. Gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n tí máa ń jẹ iyán ṣùgbọ́n iyán jíjẹ wọ́pọ̀ jùlọ láàárín àwọn Ìjẹ̀ṣà, Òndó àti Èkìtì.[1][2] [3]
Tún Wò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn èròjà iyán gúngún
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣu ni ọba èròjà tí wọ́n máa ń fi gúnyán. Lẹ́yìn iṣu, a nílò odó, ó orí-odó àti omi.
Bí a ṣe lè gúnyán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- A yóò bẹ iṣu
- A yóò fọ iṣu náà tónítóní
- À yóò dáná láti se iṣu
- A yóò bu omi ní ìwọ̀nba tí ó lè se iṣu náà jiná sínú ìkòkò tàbí apẹ tí a fẹ́ fi se iṣu náà
- A yóò kó iṣu tí a ti fọ̀ ní àfọ̀mọ́ sínú ìkòkò tí a gbé kaná
- A yóò se iṣu náà títí yóò fi jiná dáradára.
- Lẹ́yìn tí iṣu bá ti jiná, a yóò wà á sínú odó tí a ti fọ̀ kalẹ̀.
- A yóò wá fi omorí odó fi gún un títí yóò fi lẹ̀ dáadáa.
- A yóò wá kọ ọ́ sínú abọ́ tàbí àwo tó mọ́ tónítóní fún jíjẹ.[4]
Àwọn ọbẹ̀ tí a fi lè jẹ iyán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Yorùbá bọ̀, wọ́n ní, "Iyán loúnjẹ, ọ̀kà logùn, àìrí rárá là ń jẹ̀kọ" Yorùbá gbádùn iyán púpọ̀, oríṣiríṣi ọbẹ̀ ni wọ́n fi ń jẹ iyán. Àwọn ni;
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Pounded Yam (Fufu) Recipe - Side Dish Recipes - PBS Food". PBS Food. 2011-09-12. Retrieved 2019-12-13.
- ↑ "Pounded Yam". All Nigerian Recipes. 2019-03-25. Retrieved 2019-12-13.
- ↑ "Iyan - Pounded Yam". My Guide Nigeria. 2014-02-12. Retrieved 2019-12-13.
- ↑ "Pounded Yam". How To Pound Yam in Nigeria. Retrieved 2019-12-13.