Joy Bryant

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Joy Bryant, gẹ́gẹ́ bí i orúkọ rẹ̀, jẹ́ òṣèrébìnrin, oníṣòwò, àti oníṣẹ́-oge ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó ti kópa tàbí farahàn nínú-un ogunlọ́gọ̀ eré àti iṣẹ́ẹ móhùn-máwòrán láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ẹ rẹ̀ ní ọdún 2001. A bí i ní ọjọ́kejìdínlógún osù kẹwàá ọdún-un 1974 sí Bronx, ìpínlẹ̀ New York. Arúgbóbìnrin òbí i rẹ̀ ló tọ́o dàgbà; ìyá yìí náà ló sì pèsè ohun gbogbo fún-un kí ó tó wá dẹni tó rówọ́họrí. Ọmọ ọdún mẹ́ta ló sì tí máa ń dáwọ́ ijó gẹngẹ ní fífi ẹ̀bùn àtinúdáa rẹ̀ hàn. Ní kíkà, ó ti gba àmì-ẹ̀yẹ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí i ìdánimọ̀ lọ́wọ́ àjọ NAACP fún Image Award Nominations; ẹ̀wẹ̀, ó tún ti gba ọ̀kan fún Screen Actors Guild Award nomination.

Iṣẹ́ rẹ̀.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bryant bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi oníṣẹ́-oge lára pé ó farahàn nínú àwon ípolówó fún "Ralph Lauren", "Tommy Hilfiger", "Gap Inc.", àti "Victoria's Secret". Lẹ́nú iṣẹ́ẹ fíìmù, ó ní àlàjá nígbà tí ó kópa nínú-un eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Antwone Fisher" ní ọdún 2002, èyí tí ó tọwọ́ọ Denzel Washington jáde. Àwọn eré mìíràn tó tún ti kópa ni "Spider-Man 2" ní ọdún-un 2004, "The Skeleton Key", "Get Rich or Die Tryin" àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọ̀n Ìtọ́kasí.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]