Kastina
Katsina | |||
---|---|---|---|
![]() Emir's Palace in Katsina | |||
Nickname(s): KT, KT 1T, Katsina ta Korau ɗakin kara. | |||
Coordinates: 12°59′20″N 07°36′03″E / 12.98889°N 7.60083°ECoordinates: 12°59′20″N 07°36′03″E / 12.98889°N 7.60083°E | |||
Country | ![]() | ||
State | ![]() | ||
Government | |||
• Chairman | Hamisu Gambo | ||
• Emir | Abdulmumini Kabir Usman | ||
Area | |||
• Total | 142 km2 (55 sq mi) | ||
Population (2006) | |||
• Total | 318,459 | ||
Time zone | West Africa Time | ||
3-digit postal code prefix | 820 | ||
ISO 3166 code | NG.KT.KA | ||
Climate | BSh | ||
|
Katsina jẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ àti olú ìlú fún Ìpínlẹ̀ náà ní apá òkè ọya ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Kastina wà ní 260 kilometres (160 mi) ní apá ìlà Oòrùn sí ìlú Sokoto, ó sì wà ní aríwá sí 135 kilometres (84 mi) sí ìlú Kano, bákan náà ni ó pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Niger . Gẹ́gẹ́ bí ònkà ọdún 2016 ti sọ, iye ènìyàn tí wọ́n ń gbé ìlú kastina jẹ́ 429,000.[2] Wọ́n mọ ìlú Kastina fún àwọn ohun ọ̀gbìn bíi òwú, awọ, ọkà bàbà, jéró àti ẹ̀pà.[1] bákan náà ni ilé ìpèsè òróró ẹ̀pà tún wà níbẹ̀ tí ó fi mọ́ ìpèsè irin. Orísiríṣi ohun òsìn bí adìyẹ,ewúrẹ́ ,àgùtàn ni wọ́n pọ̀ níbiẹ̀ bìbà. Àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Hausa àti Fulani ni wọ́n pọ̀ jùlọ nibẹ̀. [3]
Ìtàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Odi ńlá tí ó tó 21 kilometres (13 mi) tí ó sì ti wà láti nkan bí ọgbàọ́rùn un lé lẹ́gbẹ̀rún ọdún ni ó yí ìlú Kastina po.[1] Ṣáájú kí ẹ̀sìn Mùsùlùmí tó wọ'bẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ adarí wọn tí wọ́n ń pè ní Sarki ni wọ́n lè pawọ́pọ̀ pa nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn àìkájú òṣùwọ̀n lẹ́nu ìdarí rẹ̀ kàn án. Kàstínà jẹ́ ojúkò okòwò tí ó tóbi jùlọ ní ilẹ̀ Hausa ní láàrín 17th sí 18th century, ìlú náà sì di ìkan pàtàkì nínú àwọn ìlú ńlá méje tí ó wà ní ilẹ̀ Hausà nígbà náà. Àwọn Fulani fipá gba ìlú náa mó wọ́bẹ Hausa lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ja ogun Fulani ní ọdún 1807. Ọdún 1903 ni Emir, Abubakar dan Ibrahim, gba òfin ìjọba àwọn gẹ̀ẹ́sì amúnisìn láàyè láti máa ṣàkóso títí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi gba òmìnira ní ọdún 1960. Ìlú Kastina lajú sí ẹ̀kọ́ gẹ̀ẹ́sì níìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950 nígbà tí wọ́n dá ilé-ẹ̀kọ́ ti Kastina Teachers College sílẹ̀. Lẹ́yìn èyí, oríṣiríṣi ilé-ẹ̀kọ́ ni wọ́n ti dá sílẹ̀ tí ó fi mọ́ fásitì ti Umaru Musa Yar'adua University ati Alqalam University tí ó jẹ́ ti aládàáni, wọ́n ti ní ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti Hassan Usman Katsina Polytechnic àti ilé-ẹ̀kọ́ àwọn olùkọ́ ti Federal College of Education, Katsina. Bákan náà, Mọ́sálásí tí wọ́n fi amọ̀ àti ọwọ́ imọ̀-apá kọ́ láti 18th-century tí asóró rẹ̀ ga tó 15-metre (50 ft) tí wọ́n ń pè ní Gobarau Minaret ṣì wà níbẹ̀ títí di òní.[1]
-
The Emir of Katsina, Muhammad Dikko dan Gidado, and other officials, 1911
-
Livestock market in Katsina, 1911
-
Aerial view of Katsina
Katsina Emirate
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àfin ọba Kastina jẹ́ [ilé]] ńlá rẹ̀gẹ̀jì kan tí wọ́n ń pè ní Gidan Koaru tí ó wà ní àárín gbùngbùn ìlú Kastina.[4] Àfin náà jẹ́ àmì àṣà àti ìtàn ìṣẹ̀mbáyé ilú àti àwọn ènìyàn Kasitan It is a Emir tí ó kọ́kọ́ kọ́ àfin náà ní ọdún 1348 ni Muhammadu Korau, ẹni tí wọ́n gbàgbọ́ wípé ó jẹ́ Emir àkọ́kó tí jẹ́ Mùsùlùmí ní ìlú Kastina. Èyí jẹ́ kí a mọ̀ ìdí pàtàkì tí w9n fi s9 àfin náà ní Gidan Korau (Ilé Korau). Ààfin yí jẹ́ ìkan pàtàkì lára àwọn ààfin tí wọ́n kọ́kọ́ tí ó ti pẹ́ jùlọ. Leyin eyi ni ààfin ti Daura, ààfin Kano, àti ààfin Zazzau. Orísiríṣi ẹ̀yà ara àgbò àti awọ ẹran ni wọ́n fi ṣe ààfin náà lọ́jọ̀, Ìloro tí wọ àkòdì ọba láti ẹ̀yìn ni wọ́n ń pè ní 'Kofar Bai', àwọn ohun mejie tí s dárúkọ yí ni wọ́n ti paríẹ́ báyìí,. Gbògàn ìgbàlejò Ọba ni wọ́n ṣe lọ́jọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi àwòrán ìbílẹ̀ tó kọ yọyọ. [5]
Ẹ̀sìn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Oríṣi ẹ̀sìn méjì tó ṣe gbòógì ni ó wà ní Kastina, àwọn náà ni:
Àwọn ìtọ́kast
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 Katsina The Encyclopædia Britannica Online. Retrieved 20 February 2007.
- ↑ "Nigeria: Administrative Division (States and Local Government Areas) - Population Statistics, Charts and Map". citypopulation.de. Retrieved 16 September 2023.
- ↑ "Katsina | Location, History, Facts, & Population". britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 22 October 2023.
- ↑ "Emirs Palace Katsina State :: Nigeria Information & Guide". nigeriagalleria.com. Retrieved 22 October 2023.
- ↑ "KATSINA EMIRATE COUNCIL". Archived from the original on 14 November 2011. Retrieved 6 August 2015. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help). Retrieved 6 August 2015.