Khadija Abba Ibrahim
Khadija Bukar Abba Ibrahim | |
---|---|
Member of the House of Representative from Yobe State | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 12 June 2019 | |
Asíwájú | Abdullahi Kukuwa |
Constituency | Damaturu / Gujba / Gulani / Tarmuwa |
Minister of State for Foreign Affairs | |
In office November 2015 – 9 January 2019 | |
Asíwájú | Nurudeen Mohammed |
Arọ́pò | Zubairu Dada |
Member of the House of Representative from Yobe State | |
In office 12 June 2007 – October 2015 | |
Asíwájú | Zanna Laisu |
Arọ́pò | Abdullahi Kukuwa |
Constituency | Damaturu / Gujba / Gulani / Tarmuwa |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 6 Oṣù Kínní 1967 |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | All Progressives Congress |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Bukar Abba Ibrahim[1] |
Àwọn òbí | Waziri Ibrahim (father) |
Alma mater | University of Surrey |
Occupation | Politician |
Khadija Bukar Abba Ibrahim (tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹfà oṣù kìíní ọdún 1967) jẹ́ olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ All Progressives Congress ti Ilé Ìgbìmọ̀ àwọn Aṣojú fún Damaturu, Gujba, Gulani, àti Tarmuwa (ní ìpínlẹ̀ Yobe). Ní ọdún 2016, Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn án gẹ́gẹ́ bí Mínísítà Ìjọba fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀-òkèrè.[1][2]
Ní Oṣù Kẹwàá ọdún 2018, òun àti ọmọ ọkọ̀ rẹ̀ dìjọ díje dupò kan ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣojú àpapọ̀, èyí tí ó jáwé olúborí.[3][4][5][6] Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kíní ọdún 2019, Abba Ibrahim kéde pé òun ń fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣojú láti lè gbájú mọ́ ìpolongo rẹ̀ fún ìjókòó Ilé Aṣòfin Àpapọ̀ fún Ẹkùn Ìdìbò rẹ̀ tí ó sì borí.[7][8][9] Khadija Ibrahim ni ìyàwó Alàgbà Bukar Abba Ibrahim, tí ó fìgbà kan jẹ́ Gómìnà ti Ìpínlẹ̀ Yobe, àti Sẹ́nétọ̀.[10]
Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí i sínú ìdílé Waziri Ibrahim, bẹ́ẹ̀ sì ni ó lọ ilé-ìwé Kaduna Capital School, ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Nàìjíríà, láàárí ọdún 1972 sí 1977. Ní ọdún 1978, ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Queen's College, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Ní ọdún 1980, ó lọ sí Headington School, Oxford, níbi tí ó ti parí ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ọdún 1983. Ni ọdun 1986, Abba Ibrahim gba oyè ẹ̀kọ́ Diploma nínú ìmọ̀ Business Studies and Finance láti Padworth College, Reading, UK. Ní ọdún 1989, ó gba oyè B.Sc. rẹ̀ nínú ìmọ̀ Business Studies and Sociology láti Roehampton Institute for Higher Education, tí ó jẹ́ ẹ̀ka University of Surrey.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣẹ́ tó kọ́kọ́ yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kí ó tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní yunifásítì ní ọdún 1989, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Abbey National Building Temple Fortune, North Finchley, ní UK, níbi tí ó ti kópa nínú ríra àti títà àwọn ohun-ìní àti títọ́jú àwọn àkọọ́lẹ̀ owó ilé-ìfowópamọ́ fún àwọn oníbàárà wọn. Ní ọdún 1991, o ṣiṣẹ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú Hatton Cross Heathrow, ní UK gẹ́gẹ́ bí Public Relations Officer. Àwọn ojúṣe rẹ̀ sì ni mímú àwọn oníbàárà wá sí ilé-iṣẹ́ náà. Ọdún kan náà ló kúrò ní ilé-iṣẹ́ náà láti dara pọ̀ Kaguin Nigeria Limited gẹ́gẹ́ bí Aṣèpolówó-ọjà. Àwọn rẹ̀ ni láti máa ṣèpolowó ọjà bí i ọkà àti epo rọ̀bì ní àwọn agbègbè tí ECOWAS gbilẹ̀. Ní ọdún 1992, wọ́n yàn án sípò Olùdarí ilé-iṣẹ́ OURS Insurance Brokerage, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ kan tó ń rí sí ṣíṣe ìpamọ́ àwọn ìdókòwò ìjọba àti aláàdáni. Lẹ́yìn tó ti ní ìrírí tó pọ̀ tó, Abba Ibrahim dá ilé-iṣẹ́ tirẹ̀ sílẹ̀, èyí tí ó pè ní ZAFACA Nigeria Limited, ní odún 1996. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alákòóso àti olùdarí àgbà ilé-iṣẹ́ náà láti ọdún tọ́ ṣèdásílè rẹ̀ títí wọ ọdún 2004.
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2004, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí i Kọmíṣọ́nnà for Transport and Energy, ní Ìpínlẹ̀ Yobe. Ojúṣe rẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ ní jíjẹ́ aláboójútó ètò ìfúnni níná lò ní àwọn abúlé àti ìĺ kéréjẹ, àti pé kó ṣe ìpèsè ètò àwọn ọ̀nà ìrìn-àjò tó péye ní ìpínlẹ̀ náà. Ní ọdún 2006, wọ́n yàn án sípò Kọmíṣọ́nà ilé-ìgbé , fún Nicon Insurance, ní ìpínlẹ̀ Yobe. Ní ọdún 2016, Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn án gẹ́gẹ́ bí Mínísítà Ìjọba fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè.[11][12]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 Leadership and Directors Archived 12 August 2016 at the Wayback Machine., Foreign Affairs, Nigerian government. Retrieved 10 February 2016
- ↑ "Senate resumes Batch 'B' Ministerial screening with Shittu,Khadija". Senate resumes Batch ‘B’ Ministerial screening with Shittu,Khadija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 March 2020.
- ↑ Matazu, Hamisu Kabir; Damaturu (3 October 2018). "Foreign Affairs minister defeats step son to emerge House of Reps. candidate in Yobe". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 March 2020.
- ↑ Jannah, Chijioke (4 October 2018). "2019: Buhari's minister, Khadija Ibrahim defeats son to clinch APC Reps ticket". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 March 2020.
- ↑ "Minister defeats stepson to clinch house of reps ticket in Yobe". TheCable (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 3 October 2018. Retrieved 11 March 2020.
- ↑ "Khadija Bukàr Abba wins House of Reps primary election in Yobe" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 11 March 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Another Buhari's minister resigns". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 9 January 2019. Retrieved 11 March 2020.
- ↑ "Khadija Bukar Ibrahim quits Buhari's cabinet". Businessday NG (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 9 January 2019. Retrieved 11 March 2020.
- ↑ "Minister of State for Foreign Affairs, Khadija Abba-Ibrahim, Resigns". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 9 January 2019. Retrieved 11 March 2020.
- ↑ "Bukar Abba Ibrahim Biography and Detailed Profile". Politicians Data (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 5 September 2018. Retrieved 12 May 2021.
- ↑ Leadership and Directors Archived 12 August 2016 at the Wayback Machine., Foreign Affairs, Nigerian government. Retrieved 10 February 2016
- ↑ Baba-Adamu, Muhammed; Jajere, Ibrahim Ahmed (2020-08-17). "Water scarcity measurement in the Yobe region of Nigeria". Kampala International University Interdisciplinary Journal of Humanities and Social Sciences 1 (2): 265–280. doi:10.59568/kijhus-2020-1-2-18. ISSN 2708-7050. http://dx.doi.org/10.59568/kijhus-2020-1-2-18.