Kọ́lá Akínlàdé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Kola Akinlade

  1. Ìtàn Ìgbésí Ayé Ònkọ̀̀wé

A bí Kọ́lá Akínlàdé ní ọdún 1924, ní ìlú Ayétòrò ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Àwọn òbí rẹ̀ ni Michel Akínlàdé àti Elizabeth Akínlàdé. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù mímọ́ ní Ayétòrò. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí ni ó kọjá sí Ìlaròó tí ó sì dá iṣẹ́ tẹ̀wétẹ̀wé sílẹ̀ ńbẹ̀ fúnrarẹ̀ ni ó ka ìwé gba ìwé-èrí G.C. E. ní ilé. Lẹ́yìn tí Kọ́lá Akínlàdé gba ìwé-ẹ̀rí yìí ni ó dá ìwé ìròyàn kan sílẹ̀ tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní ‘Ẹ̀gbádò Progressive Newspaper: Lẹ́yìn èyí ni ó wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi akọ̀wé ìjọba. Ó ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìjọba ìpínlè ìwọ̀-oòrùn àtijọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Kị́lá Akínlàdé lọ kàwé ní Yunifásítì Ifẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà ó sì tún padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríà. Ní ọdún 1976 ni Kọ́lá Akínlàdé fẹ̀yìn tì. Ní ọdún 1980, ó tún gba iṣẹ́ olùkọ́ sí ìbàdàn Boys High School, Ìbàdàn, Nàìjíríà. Ó wá fi ẹ̀yìn tì ní ọdún 1984. Kọ́lá Akínlàdé ní ìyàwó ó sì bí ọmọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ni Kọ́lá Akínlàdé ti kọ. Lára wọn ni Ajá to ń Lépa Ẹkùn, Ọ̣wọ̣̣́ Tẹ Amòokùnṣìkà, Àgbákò nílé Tẹ́tẹ́, Baṣọ̀run Olúyọ̀lé, Ajayi, the Bishop, Chaka, the Zulu, Esther, the Queen, Abraham, The…..Friend of God, Sheu Usman Dan fodio, Òwe àti Ìtumọ̀ rẹ̀, Sàǹgbá fọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sì tún kópa nínú kíkọ Àsàyàn Ìtàn.

  1. Ìwé Àṣírí Amòòkùnṣìkà Tú ní Sókí

1. Ọmọ ilé-èkọ́ ni Dúró Orímóògùnjé. Ó ku Ọdún kan kí ó jáde ìwé mẹ́wàá. Ìyá rẹ̀ kú ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ìyẹ̀n ni pé ó kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Bàbá rẹ̀ nígbà tí ó kú. Ikú bàbá rẹ̀ tí ó gbọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ ni o gbé e wálé. Ìyàwó mẹ́rin ni Àkàndé Orímóògùnjẹ́ tí ó jẹ́ ìyá Dúró ti kú, ó ku mẹ́ta. Ọmọ márùn-un ni Àkàńgbé Orímóògùnjé bí Dúró sì ni àgbà gbogbo wọn. Òun ni àkọ́bí. Ìyaa folúké, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó wọ̀nyí, ni ìríjú àkándé, Orímóògùnjẹ, ìyẹn ni pé òun ni ó fẹ́ran jù. Ìya fólúké yìí ni ó mú kọ́kọ́rọ́ séèfù jáde tí ó ṣí i tí wọn kò sì bá nǹkan kan ní ibẹ̀. Ìgbà tí Àkàndé mú owó kẹ́yìn nínú séèfù yìí kí ó tó kú, owó tí ó wà nínú rẹ̀ ju ẹgbàáta náírà (N30,000.00)lọ. Ọ̀gbẹ́ni Ajúṣefínní: Òun ní ó ra kòkó lówó Àkàngbé. Ó sanwo ní 10/2/80. Àṣàkẹ́: Òun ni ó jẹ́rìí sí owó kòkó ti Àkàngbé gbà. Ohun tí ó yani lẹ́nu ni pé Ogóje náírà (N140.00) péré ni wọ́n bá ní abẹ́ ìrọ̀rí Àkàngbé nígbà tí ó kú. Àdùnní: Òun ni ìyá Dúró Orímóògùnjé. Àdùnní ti di olóògbé, ìyẹn nip é ó ti kú. Ọ̀gbẹ́ni Túndé Atọ̀pinpin: Òun ló ní kí Dúró fi ọ̀rọ̀ owó tí ó sọnù lo Olófìn-íntótó.

2. Túnde Atọ̀pinpin náà kọ lẹ́tà sí Olófìn-íntótó. Ìdẹ̀ra ni orúkọ ilé-ẹ̀kọ́ àbúrò Túndé Atọ̀pinpin. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Dúró orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n Ilẹ́sanmí ni Àdùnní ìyá Dúró Orímóògùnjẹ́. Àgbẹ̀ oníkòkó ni Àkàngbé orímóògùnjẹ́, bàbá Dúró nígbà ayé rẹ̀. Túndé Atọ̀pinpin àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa ń sùn ní ilé Àkàngbé nígbà ti wọ́n bá ń lọ sí ìhà Odò Ọya. Dúró Orímóògùnjẹ́ nìkan ni ọmọ tí Àdùnní bé. Ará ìlú Àdùnní ni Olófìn-íntótó, ọmọ Adéṣínà. Túndé Atòpinpin máa ń lọ gbé ojà ní Èkó. Ọkọ̀ ojú omi ni ọjà yìí máa ń bá dé.

3. Olófìn-íntótó, ọmọ olusínà kọ̀wé sí Túndé Atọ̀pinpìn. Àròsọ ni Olófin-íntótó àti ilésanmí ti wokò. Dírẹ́bà wọn ń sáré gan-an ni. Fìlà Olófìn-íntótó tilẹ̀ sí sọ̀nù ní ọ̀nà. Ó dá mọ́tọ̀ dúró ni kí ó tó lọ mú un Nígbà tí wọ́n dé ojà, dírébà jẹ ẹ̀bà, ilésanmí jẹ iyán ó sì ra òòyà ní irinwó náírà (400.00) Ní ọjà, Olófìn-íntótó bá obìnrin kan pàdé. Ó ra ọtí fún un. Obìnrin yìí sì mu ìgò otí kan tán ó sì mu ìkejì dé ìdajì. Ó yẹ kí a sẹ àkíyèsí obìnrin yìí dáadáa nítorí pé òun nì a wá fi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jí owó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ jí ní iwájú. Nígbà ti Olófìn-íntótó àti Ilésanmí dé Ilé-Ifè tí wọn ń lọ, ọ̀dọ̀ Àlàó ni wọ́n dé sí. Ilé-Ifẹ̀ ni Àlàó ti ń ta ojà. Àlàó ra obì àti ọtí fún Olófìn-íntótó Olófìn-íntótó mu bíà mẹ́ta. Àlàó ń mu ẹmu lẹ́yìn tí ó jẹun tán Ilésanmú sì ń mu ògógóró. Ọlọ́fìn-íntótó gbádùn láti máà fi ọwọ́ pa túbọ̀mu rẹ̀. Irun tí ó hù sí orí ètè òkè ní ìsàlẹ̀ ibi tí imú wà ni ó ń jẹ́ túbọ̀mu. Àsàkẹ́: Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Gbajímọ̀ ènìyàn ni. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ṣùgbọ́n ó dàbí ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọ̀mọ̀wé ni. Yéwándé: Ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Àkàngbé ni òun náà. Kò kàwe ṣùgbọ́n o ní ọ̀yàyà ó sì máa ń ṣe àyẹ́sí ènìyàn. Àlàó: Òun ni Olófin-íntótó àti Ilésanmí dé sí ọdọ rẹ̀. Onígbàgbọ́n ni. Jọ̀ọ́nú ni orúkọ rẹ̀ mìíràn. Ó máa ń gbàdúrà ni alaalé kí ó tó sùn. Ọmọ mẹ́ta ni ó bí. Ní ọjọ́ tí àwọn Olófin-íntótó kọ́kọ́ dé ilé rẹ̀ tí wọ́n ń gbàdúrà ó ní kí gbgbo wọn kọ orin wá bá mì gbé olúwa. Àwọn ọmọ Àlàó kò bá wọn kọ ẹsẹ kejì tí ó sọ wí pé ‘Ọjọ́ ayéè mi ń sáré lọ sópin’. Àsàmú tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Àlàó ni ó ṣe àlàyé fún bàbá rẹ̀ ìdí tí wọn kò ṣe kọ ẹsẹ kejì orin náà. Ó ní orin àgbàlagbà ni.

4. Ilésanmí rọ́ àlà tí ó lá fún Akin Atọ̀pinpin ọmọ Olúṣínà. Ó ní nínú àlá tí òun lá, òún. Rí ẹni tí ó gbé owó ṣùgbọ́n òun kò rí ojú rẹ̀ tí òun fi ta jí. Ẹ jẹ́ kí á ṣe àkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n mẹ́nu bà ní orí yìí. Dúró – Òun ni àkọ́bí nínú àwọn ọmọ Orímóògùnjẹ́. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Fólúkẹ́ - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni. Ó ṣẹṣẹ̀ wo kọ́lẹ́jì ni. Ọmọ́wùmí- Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ ni òun náà Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni. Ilé-ẹ̀kọ́ kékeré ni ó wà. Ọládúpọ̀ - - Ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjé ni òun náà. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni. Ilé-ẹ̀kọ kékeré ni ó wà. Fólúkẹ́, Omówùmí àti Oládípọ̀ jẹ́ ọmọ Yẹ́wándé. Bándélé jẹ́ ọmọ odún méje. Àṣakẹ́ ni ó bíí Yàtọ̀ sí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́, Yéwándé nìkan ni ó tún máa ń mu owó nínú séèfù. Àìsàn Orímóògùnjẹ́ kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ tí ó fi kú. Ilé Orímóògùnjẹ́ kò ju ilé kẹ́rin lọ sí ilé Àlàó. Nígbà tí àwọn Olófìn-íntótó dé ilé Orímóògùnjẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí. Yéwándé ni ó mú wọn wọlé Kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù yìí kìí ya Orímóògùnjẹ́. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni ó wà nígbà tí ó ń ṣàìsàn. Kì í yọ kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù. Àṣàkẹ́ wọlé bá wọn níbi tí wọn ti ń sọ̀rọ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwádìí nílé Orímóògùnjẹ́. Wọ́n máa ń há ìlẹ̀kùn yàrá Orímóògùnjẹ́ ṣùgbọ́n wọ́n máa ń fi kọ́kọ́rọ ibẹ̀ há orí ìtérígbà. Ẹnikẹ́ni ní inú ilé ni ó lè mú un ní ibẹ̀ kí ó sì fi sí ilẹ̀kùn Yéwándé ni ó máa ń tọ́jú Orímóògùnjẹ́ lóru nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Àṣàkẹ́ máa ń ràn án lọ́wọ́. yéwándé àti àwọn ọmọ náà máa ń wá tọ́jú Orímóògùnjẹ́ nígbà ti ó ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí àìsàn rẹ̀ bá ń yọnu. Adékẹ́yẹ ni orúkọ bàbá yéwándé. Ọjà Ajégbémilékè ni Yéwándé fẹ́ lọ ní ọjọ́ tí ọkọ rẹ̀ kú. Àlàó ni ó kó ogóje náírà (N140.00) tí wọ́n bá níbi ìgbèré Orímóògùnjẹ́ fún Yéwándé láti tójú. Orúkọ mìíràn tí Àkàngbé Orímóògùnjẹ́ tún ń jẹ́ ni Bándélé. Ẹ rántí pé eléyìí yàtọ̀ sí Bándélé orúkọ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ. Ọ̀sanyìnnínbí ni orúkọ oníṣèègùn Orímóògùnjẹ́. Ó ra páànù ìgàn méjìlá ní ọ̀dọ̀ kékeréowó. Èyí sì fẹ́ mí ìfura dání nítorí owó tí ó sonù. Àwọn kan rò pé bóyá òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ tí ó sọnù. Nílé Orímóògùnjẹ́ níbití wọ́n ti ń ṣe ìwádìí, Ọlọ́fìn-íntótó rí ẹ̀já òwú kan tí ó wà lára ọ̀kan nínú àwọn ojú kéékèèkéé inú séèfù ó sì mú un. Gbòngán ni fọláṣadé ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn Orímóògùnjẹ́ ń gbé. Ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún tàbí ọ̀sẹ̀ kan ní ifẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ kí ó tó padà sí Gbọ̀ngán. Kò bímọ kankan fún Orímóògùnjé. Ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí fọláṣadé dáadáa nítorí pé òun ni Olófìn-íntótó ra otí fún ní ọjà tíó mu ìgò ọtí kan àbò. Òun ni a sì rí ní òpin ìwé pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé.

5. Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ní sítọ́ọ̀. Káyọ̀dé ni orúkọ akọ̀wé rẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́fà kí Akin Ọlọ́fín-íntótó ọmọ Olúṣínà àti Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ ti rí ara wọn mọ kí wọn tún tó rí ara wọn yìí. Àbúrò Orímóògùnjẹ́ ni Ilésanmí tí òun àti Olófìn-íntótó jọ wá ṣe ìwádìí ní ilé-Ifè. Ọ̀rẹ́ Orímóògùnjẹ́ ni Ajíṣefínní tí ó ń ta kòkó. Bíọlá ni orúkọ ẹni tí ó ń ta ọtí Lóòótọ́, oníṣèègùn ni Ọ̀sanyìnnínbí síbẹ̀, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn Oníṣèègùn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹgbẹ́ ìlera loògùn Ọrọ̀. Awóyẹmí ni orúkọ ẹni tí ó bá àwọn Ọlọ́fìn-íntótó níbi tí wọ́n ti ń gbádùn lọ́dọ̀ Ọmọtóṣọ̀ọ́. Ilésanmí àti Ọlọ́fin-íntótó sọ nípa ara wọn pé àwọn mọ ilẹ̀ tẹ̀ múyẹ́ (Ẹ rántí pé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀lmúyẹ́ ni wọ́n ń ṣe). Ajúṣefínní, ọ̀rẹ́ orímóògùnjẹ́ ni ó bá Orímóògùnjẹ́ ra ilẹ̀ tí ó ń kọ́ ilé sí. A ó rántí pé kòkó ní Ajíṣefínní ń tà. Ọwọ́ Òṣúnlékè ni wọ́n ti r ailẹ̀ tí Orímóògùnjẹ́ fi ń kólé náà. Ẹgbẹ̀ta náírà (N600.00) ni wọ́n ra ilẹ̀ náà. Káyòdé akòwé Ọmọ́tọ́ṣọ̀ọ́ sùn ní ẹnu iṣẹ́ Ìgbà tí wọ́n bi í pé kí ló dé tí ó fi sùn ni ó dáhùn pé olè ajẹ́rangbe tí àwọn ń lé ní òru ni kò jẹ́ kí àwọn sùn dáadáa. Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Oníṣèègùn Ọ̀sanyìnnínbí ni olórí àwọn olè ajẹ́rangbé yìí gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i kà ní iwájú. Ẹran tí ó ń jí gbé yìí wà lára ohun tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn fura sí Ọ̀sanyìnnínbí pé òun ló jí owó Orímóògùnjẹ́ gbé níbi tí ó tí ń tọ́jú rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe àìsàn. Ẹran mẹ́ta ni wọ́n bá ní ilé àwọn olè wọ̀nyí nítorí pé wọ́n ti jí méjì tẹ́lẹ̀. Nítorí pé Ọ̀sanyìnnínbí jẹ́ ọ̀gá fún àwọn olè wọ̀nyí, wọ́n mú un lọ sí Àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Morèmi ní ilé-Ifè.

6. Nígbà ti Ọlọ́fìn-íntótó gbọ́ pé wọ́n mú Ọ̀sanyìnnínbí sí àgọ́ ọlọ́pàá Morèmi, òun àti Ilésanmí lọ́ sí ibẹ̀. Aago mẹ́fà sí mẹ́jọ ni ọ̀gá ọlọ́pàá máa ń rí ènìyàn ṣùgbọ́n ó gbà láti rí Akin àti Ilésanmí lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rí káàdì Akin. Pópóọlá ni orúkọ ọ̀gá ọlọ́pàá yìí. Ọ̀rẹ́ Akin Olófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà ni. Àbéòkúta ni Pópóọlá wà tẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tí wá gbé e wá sí Morèmi ní Ifẹ̀ níbi tí ó ti jẹ́ ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́ta tí ó ti rí Akìn mọ. Pópóọlá bèèrè Túndé Atọ̀pinpin lọ́wọ́ Akin. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n tí wọ́n ti ṣè àlàyé pé ọ̀rọ́ Ọ̀sanyìnnínbí tí wọ́n mú ni ó gbé àwọn wa ni wọ́n ṣe àlàye pé tí ó bá jẹ́ pé òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́, yóò ti ná tó ẹgbẹ̀jọ náírà (N1,600.00) nínú owó náà. Ẹran ti Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé ni ó jẹ́ kí wọ́n ní àǹfààní láti yẹ ilé rẹ̀ wo. Àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí àwọn ènìyàn sọ ní orú yìí tí ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí. Ilésanmí ni ó kọrin pé, ‘Iyán lóunjẹ.’ Akin ni ó sọ pé, Ajímutí kìí tí’ Akin náà ni ó sọ pé, ‘Ẹni fojú di Pópó á gba póńpó lórí…’. Orúko Pópíọlá ni ó fi ń ṣeré níbí yìí. Pópóọlá sọ pé, ‘Ẹni tí ó pe tóró, Á ṣẹnu tọ́ńtọ́..’ Ó yẹ kí á ṣe àkíyèsí pé Àlàó ni oríkì Pópóọlá. Eléyìí yàtò sí Àlàó tí ó tójú àwọn Olófìn-íntótó tí a ti ṣe àkíyèsí rẹ̀ ṣáájú. Nígbà tí wọ́n ló yẹ ilé Ọ̀sanyìnnínbí wò, owó tí wọ́n bá ní ibẹ̀ jẹ́ ọgọ́sàn-án náírà (N180.00) Níní orí yìí, a ó rí òwe, ‘Àfàgò kẹ́yin àparò…’ Ohun tí ó fa òwe yìí ni ẹran tí Ọ̀sanyìnnínbí jí gbé àti ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ní yóò lọ tí ìyàwó rẹ̀ yóò sì ti bímọ kí ó tó dé. Àpatán òwe yìí ni, ‘Afàgò kẹ́yin àparò, ohun ojú ń wá lojú ń rí.

7. Akin Olúṣínà àti Ilésanmí lọ sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, òògùn ni Ọ̀sanyìnnínbí wá ṣe. Orí yìí ni a ti mọ ìdí tí Ọ̀sanyìnnínbí fi fẹ́ràn Orímóògùnjẹ́. Ìdí tí ó fi fẹ́ràn rẹ̀ nip é nígbà tí Ọ̀sanyìnnínbí ń ṣe òkú ìyá rẹ̀, ó fún un ní ọgọ́rùn-ún náírà (N100.00) níbi tí kò ti sí ẹni tí ó tún fún un ju náírà márùn-ún lọ. Àlàó tí ó tọ́jú Akin àti Ilésanmí nígbà tí wọ́n dé Ifẹ̀ kò fẹ́ran oògùn ìbílẹ̀ Ọ̀sanyìnnínbí sọ pé Orímóògùnjẹ́ kì í finú tan Àlàó yìí Àwọn ohun tí ó tún yẹ kí á ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: Awódélé wá kí Ọ̀sanyìnnínbí Àkànbí, àbúrò Aríyìíbí, tí Ọ̀sanyìnnínbí nígbà tí ó ń ṣàìṣàn ní ó dúró fún Ọ̀sanyìnnínbí ní àgọ́ ọlọ́pàá (Ìyẹn ni pé Àkàbí tí Ọ̀sanyìnnínbí wòsàn ni ó dúró fún òun náà) Ní ọjọ́ tí àwọn Ọ̀fíntótó wá sí ilé Ọ̀sanyìnnínbí, nǹkan bí agogo mókànlá ni ó wọlé àwọn Òfíntótó sì dé ilé rẹ̀ ní aago méjì kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Nígbà tí Akin Olúṣínà àti Ilésanmí dé ọ̀dọ̀ Ọ̀sanyìnnínbí tí ó rò pé oògùn ni wọ́n wá ṣe ní ọ̀dọ̀ òun, àwọn ẹbọ tí ó kà fún wọn ni ìyá ewúrẹ́ kan, ẹgbẹ̀rún náírà ìgò epo kan, iṣu mẹ́ta àti ìgàn aṣọfunfun kan. Akin Olúsínà mu ẹmu ní ilé Ọ̀sanyìnnínbí Ajéwọlé ni ó ra kòkó lówọ́ Ọ̀sanyìnnínbí. Ẹgbẹ̀fà náírà (N200.00) ni ó gbà ní owó kòkó náà.

8. Àwọn ohun tí ó yẹ kí a ṣe àkíyèsí ní orí yìí ni ìwọ̀nyí: Láti lè mọ iye tí Ọ̀sanyìnnínbí gbà fún kòkó tí ó tà fún Ajéwọlé, ọgbọ́n ni wọ́n fi tan Ọ̀sanyìnnínbí. Wọ́n sọ fún un pé ẹnì kan ń rọbí àti pé yóò nílò oníṣèẹ̀gùn. Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Oládiípọ̀. Òun sì ni àbíkẹ́yìn Yéwándé Bándélé jẹ́ ọmọ odún mẹ́jọ. Ọmọ Àṣàkẹ́ ni Jayéjayé kan ni Àṣàkẹ́ máa ń wọ àdìrẹ tàbí borokéèdì ó sì máa ń wọ súwẹ́ta nígbà òtútù.

Fawọlé: Ó wà lára àwọn ẹni tí ó wá wo Orímóògùnjẹ́ nígbà tí ara rè kò yá. Nígbà tí Akin Olúsínà ṣe ìwádìí nípa rẹ̀, èsì tí ó rí gbọ́ ni ìwọ̀nyí: Wọ́n ní ìhà sáábó ni Fáwọlé máa ń gbe Tinúkẹ́ ni orúkọ ọmọ rẹ̀.

Nípa aṣọ tí ó wọ̀ ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́, ẹni kan sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú aṣọ òfì ni ó wọ̀. Ẹni kan sọ pé sán-ányán ni aṣọ tí ó wọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ́dé kìí tètè gbàgbé nǹkan, Akin Olúṣínà ní kí awọ́n bèèrè ìbéèrè nípá Fáwọlé lọ́wọ̀ Fólúkẹ́ àti Bándélé.

Fólúkẹ́ sọ pé aṣọ sáfẹ́ẹ̀tì ni ó wọ̀. Ó ní ó dé filà sán-ányán, ó wọ́ bàtà aláwọ̀ funfun ràkọ̀ràkọ̀ Bándélé ni ó bomi fún Fáwọlé ní ọjọ́ tí ó wá sí ọ̀dọ̀ Orímóògùnjẹ́. Folúkẹ́ ní ojoojúmọ́ ni Ọ̀sányìnnínbí máa ń wá sọ́dọ̀ Orímóògùnjẹ́ nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń sàìsàn ó sì máa ń dúró di ìgbà tí wọ́n bá ń pèrun alẹ́ kí ó tó kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. Folúkẹ́ ní òun rí nǹkan kan bí ológbò ní àpò rẹ̀ ni ọjọ́ kan. Àlàó kò gbọ́ nípa ẹni tí ó ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò nítorí pé ó lọ sí ibì òkú ìyá Báyọ̀ ní ọjọ́ náà. Ìyá Bándélé ni ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dan séèfù wò náà Orímóògùnjẹ́ kò sọ ọ̀rọ̀ eni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò yìí fún Àlàó. Yéwándé náà kò sọ fún un.

9. Igba náírà (N200.00) ni wọ́n bá ní ilé Àṣàkẹ́, ìyẹn ìyá Bándélé nígbà tí àwọn Akin Ọlọ́fìn-íntótó yẹ ilé rẹ̀ wò. Ẹni tí ó fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ni Àṣàkẹ́ ìyá Bándélé. folúkẹ́ ni ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé Àṣàké ń fi kọ́kọ́rọ́ dán séèfù wò. Àṣàkẹ́ máa ń kanra mọ́ ọmọdé. Aṣọ òfì ni Yéwándé wọ̀ nígbà tó wọ́n ń ṣe ìwádìí yìí torí òtútù. Ọjọ́ kejì ọjà Ajágbénulékè ni Àṣàkẹ́ rí kọ́kọ́rọ́ tí ó fi dán séèfù wò nínú yàrá rẹ̀. Àlàá, Àkin àti Ilésanmí fi kọ́kọ́rọ́ náà dán séèfù wò, kò sí i. Lẹ́yìn ìwádìí ti ọjọ́ yìí, Akin Ọlọ́fìn-íntótó àti ilésanmí padà sí Ìbàdàn. Ní ibi tí Akin ti dá mọ́lò dúró nígbà tí o fẹ́ ẹran ìgbẹ́ ni bàbá alágbẹ̀dẹ kan ti sọ fún ọmọ kan pé kí ó wò ọkọ̀ náà. Kọ́lá ni orúkọ ọmọ yìí. Orí yìí ní wọ́n ti wá mọ orúkọ ọmọge tí Akin Olúṣínà ra ọtí fún nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ifẹ̀ tí a ti mẹ́nu bà ṣáájú. Orúkọ ọmọge yìí ni fìlísíà Olówólàgbà. A ó rí i ní iwájú pé filísíà Olówólàgbà yìí ni orúkọ mìíràn fún ìyàwo Orímóògùnjẹ́ tí ó jí owó Orímóògùnjé gbé. Akin àti Ilésanmí wá filísíà yìí lọ sí pètéèsì aláwò pupa rúsúsúsú. Kọ́lá ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ilé yìí. Akin àti Ilésanmí sun ọ̀dọ Fìlísíà mọ́jú. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí Pópóọlá. Ó gbé wọn dé màpó.

10. Akin lọ gbowó ní bàǹkì. Òun àti Ilésanmí ni wọ́n jọ lọ. Ní báǹkì, wọ́n pàdé Kọ́lá. Ẹnu rẹ̀ ni wọ́n ti gbọ́ pé Bínpé àbúrò fìlísíà fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngán. Pópóọlá gbé Akin, Ilésanmí àti Kọ́lá. Ní ọ̀nà, ní ibi tí alágbẹ̀dẹ́ ti fi Kọ́lá sí ọkọ̀ ní ìjelòó, wọ́n rí àwọn méjì tí wọ́n ń jà Ògúndélé ni orúkọ alágbẹ̀dẹ yìi. Òun ni ó ń bá Jìnádù jà. Wọ́n gbá Adénlé tí ó fẹ́ là là wọ́n ní ẹ̀sẹ̀ nínú. Pópóọlá tí ó jẹ́ ọlọ́pàá ni ó pàṣẹ pé kí wọn dá ọwọ́ ìjà dúró tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Ohun tí ó fa ìjà tí Ògúndélé àti Jinádù ń jà ni pé Ògúndélé tí ó jé alágbẹ̀dẹ rọ kọ́kọ́rọ́ kan fún jìnádù ní múrí mẹ́ta (#60), Jìnádù san Múrí kan (#20) níbẹ̀ ó ku múrí méjì (#40). Ògúndélé bínú nítorí pé Jìnádù kò tètè san múrí méjì tí ó kì. Jìnádù bínú nítorí pé ó sọ pé Ògúndélé sin òun ní owó ní àárí àwùjọ. Jìnádù sọ pé Ògúndélé fi òrùkọ ẹ̀rẹ na òun. Nígbà tí Kọ́là sọ̀ kalẹ̀ tí ó ń lọ, ó gbàgbé àpò rẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n dá a padà fún un.

Nígbà tí Ain àti Ilésanmí ti Ìbàdàn tí wọ́n ti ń bọ̀ dé Ilé-Ifẹ̀, wọ́n lọ sí ilé fáwọlé Nígbà tí Orímóògùnjẹ́ ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tí fọláṣadé 9tí àwa tún mọ̀ sí fìlísíà) wá sí Ifẹ̀, ó lò tó ọjọ́ mẹ́ta dípò méjì tí ó máa ń lò tẹ́lẹ̀. Ìpàdé ọmọlẹ́bí tí wọ́n fẹ́ ṣe gan-an ni ó tèlè mú un padà. Yàtọ̀ sí ìgbà tí ìnáwó pàjáwùrù bá wà ọjọ́ karùn-ún kànùn-ún ni Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ nígbà tí ó wà láyé. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Yéwándé máa ń bá Orímóògùnjẹ́ mú owó nínú séèfù rẹ̀ ṣùgbọ́n ó tó oṣù kan sí ìgbà tí Orímóògùnjẹ́ tó kú tí ó ti rán an mú owó nínú rẹ̀ gbèyìn. Ọjọ́ ọjà ni ọjọ́ tí Orímóògùnjẹ́ máa ń mú owó nínú séèfù rẹ̀ máa ń bọ́ sí. Ọjọ́ kẹ́rin tí Orímóògùnjẹ́ mú owó kẹ́yìn nínú séèfù rẹ̀ ni ó kú. Ìyẹn ni pé ọjà dọ̀la ni ó kú Orímóògùnjẹ́ máa ń fún àwọn ìyàwó rẹ̀ ní owó-ìná tí ó bá ti mówó. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìwadìí yìí, Akin Olúṣínà ń fi ataare jobì. Túndé Atọ̀pinpin ní kí àwọn yẹ yàrá Fọláṣadé wò.

11. Ìsòrí kọkànlá yìí ni ó ti hàn gbangba pé Fọláṣadé, ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó Orímóògùn ni ó jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní ìdí tí òun fi jí owó náà gbé nip é òun kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́ òun kò sì fẹ́ kì tòun ó gbé sílé rẹ̀ nítorí pé ọmọ tì obìnrin bá bí fún ọkọ ni wọ́n fi máa ń pín ogún ọkọ náà ní ilẹ̀ Yorùbá. Fọláṣadé ni ó yí orúkọ padà tí ó di fìlísíà. Òun náà ni ó lọ rọ kọ́kọ́rọ́ lọ́dọ̀ bàbá àgbẹ̀dẹ tí Àṣàkẹ́ fi dán séèfù wò.


  1. Àwọn Èdá-Ìtàn

Akin Olúṣínà: Òun ni wọ́n máa ń pè ní Akin Ọlófìn-íntótó, ọmọ Olúṣínà. Òun ni ó ṣe ìwádìí owó tí ó sọnù. Àròsọ ni ó ti wọkọ̀ lọ sí Ifẹ̀ láti lọ ṣe ìwádìí owó náà. Fìlà rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀ nínú mọ́tò tí ó wọ̀. Dírẹ́bà ọkọ̀ yìí kò mọ ọkọ̀ wà dáadáa. Akin Olúṣíná fẹ́ràn ẹran ìgbẹ́. Ó máa ń mutí. Ó máa ń jobì tó fi ataa sínú rẹ̀. Ó ní túbọ̀mu ó sì máa ń fi ọwọ́ pa á. Ó ṣe wàhálà púpọ̀ kí ó tó mọ̀ pé Fọláṣadé tí ó tún ń jẹ́ filísíà nì ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó.

Foláṣádé: Òun ni ó jí owó Orímóògùnjẹ́ kó. Kò bímọ fún Orímóògùnjẹ́. Ìdí nì yí tí ó fi jí owó rẹ̀ gbé. Ó ní kí ti òun má bàa jẹ́ òfo nílé Orímóògùnjẹ́ ni ó jẹ́ kí òun jí owó rẹ̀ gbé. Fọláṣadé náà ni ó yí orúkọ padà sí fìlísíà Olówálàgbà. Orúkọ yìí ni ó si fi lọ fi owó pamọ́ sí báǹkì. Gbòngán ni ó ń gbé ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, ó ní ilé sí Ibadan. Gẹ́gẹ́ bíi fìlísíà, Ọ̀gá ni ó jẹ́ fún Kọ́lá Òwú ara súwẹ́tà rẹ̀ tí ó já bọ́ síbi séèfù wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́ láti rí i mú. Ìwé ìfowópamọ́ rẹ̀ tí Akin Olúṣínà rí lọ́wọ́ Kọ́lá náà tún wà lára ohun tí ó ran Akin Olúṣínà lọ́wọ́. Fọláṣadé wà lára àwọn tí wọ́n bí séèfù lójú rẹ̀ ní ilé Orímóògùnjẹ́ tí wọn kò bá nǹkan kan níbẹ̀. Kò sì jẹ́wọ́ pé òun ni òun kó owó tí ó wà níbẹ̀. Ó máa ń ti Gbọ̀ngán wá sí Ifẹ̀. Òun ni ìyàwó àfẹ́kẹ́yìn foún Orímóògùnjẹ́. Tí ó bá wá láti Gbọ̀ngán, ó máa ń lò tó ọjọ́ márùn-ún ní Ifẹ̀ tàbí ọ̀sẹ̀ kan. Ilé oúnjẹ ni Akin àti Ilésanmí ti kọ́kọ́ pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó jiyán tán ní ilé olóúnjẹ yìí, ó mu ìgò otí kan àti àbọ̀ nínú ọtí tí Akin Olúṣínà rà.

Àkàngbé Ọrímóògùnjẹ́: Òun ni wọ́n jí owó rẹ̀ gbé tí Akin Olúṣínà wá ṣe ìwádìí rẹ̀. Àìsàn tí ó ṣe é tí ó fi kú kò ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ. Abẹ́ ìrọ̀rí rẹ̀ ni kọ́kọ́rọ́ ojú ńlá séèfù rẹ̀ máa ń wà. Inú séèfù yìí nì ó máa ń kó owó sí. Kìí yọ àwọn kọ́kọ́rọ́ ojú kékeré séèfù yìí. Tí wọ́n bá ti ilèkùn yàrá rẹ̀, wọ́n máa ń fi kọ́kọrọ́ há orí àtérígbà níbi tí ẹnikẹ́ni ti lè mú un. Orúkọ múràn tí ó ń jẹ́ ni Bándélé. Ogóje náírà (#140), péré ni wọ́n bá nígbà tí ó kú tán. Kí ó tó kú ó ti ra ilẹ̀ tí yóò fi kọ́lè. Ajíṣafínní ni ó bá a dá sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ tí ó rà náà. Owó Òṣúnlékè ni ó ti rà á. Ẹgbàáta náírà (#6,000) ni ó ra ilẹ̀ náà.

Dúró: Dúró ni àkọ́bí ọmọ Àkàngbé Orímóògùnjẹ́. Ilé-ẹ̀kọ́ girama ni ó wà. Ọdún kan ni ó kù kí ó jáde. Òun ni ó kọ ìwé sí Akin Olúṣínà pé kí ó wá bá òun wádìí owó bàbá òun tí wọn kò rí mọ́. Àdùnní ni orúkọ ìyá rẹ̀ òun nìkan ni ó sì bí fún bàbá rẹ̀. Àdùnní yìí tí kú ní ọdún mẹ́ta ṣáájú bàbá rẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) nì Dúró. Àbúrò mẹ́rin ni ó ní. Àwọn náà ni Àdùkẹ́, Ọmọ́wùmí, Oládípò àti Bándélé.

Àdùnní: Àdùnní ni ìyàwó tí Orímóògùnjẹ́ kọ́kọ́ fẹ́. Ó kú ní ọdún mẹ́ta sáájú ọkọ rẹ̀. Òun ni ó bí Dúró fún Orímóògùnjẹ́. Ẹ̀gbọ́n ni ó jẹ́ fún Ilésanmí. Ọmọ ìlú kan náà nì òun àti Akin Olúṣínà.

  • Kola Akinlade (1976), Owo Eje. Ibadan, Nigeria: Onibonoje Press and Book Industries (Nig. Ltd). Oju-iwe = 116