Maryam Ciroma
Haija Maryam Inna Ciroma A bí ní ọjọ́ kọkànlá; oṣù kọkànlá ní ọdún 1954. Ààrẹ olórí orílé-èdè Nàìjíríà fi jẹ oyè minister of women affairs ní oṣù keje o̩dún 2005. Wọ́n sì ró̩pọ̀ rẹ̀ pèlú Saudatu Bungudu nígbà tí Ààrẹ Umaru Yar'Adua gbà ipò Ààrẹ ni oṣù keje, ọdún 2007.[1][2]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]A bí Ciroma ní ọjọ́ kọkànlá; oṣù kọkànlá ní ọdún 1954 ní ìpínlè Borno. Ciroma lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga fáfitì ti ìjọba àpapọ̀ ìpínlẹ̀ Zaria ( Ahmadu Bello University, Zaria ). Ó kèkọ́ gboyè ní ọdún 1978, nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò òṣèlú, ó sì gba ìwé ẹ̀rí PGD nínú ìmó ìṣàkóso gbogbogbò. Ciroma ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olóòtú Cadet, NTA kaduna, kí ó dara pọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ láti ọdún 1980 si 1985. Ó sì di adarí àgbà fún ilé-iṣẹ́ Intis Investment.[3]
Ó jẹ́ opó fún olóògbé Adamu Ciroma ìyẹn Gómìnà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí fún ilé ìfowó pamọ́ gbogbogbò orílé édè Nàìjíríà àti minister fún ètò ìpolongo ìbò Ààre fún Ọbasanjọ ní ọdún 2003.[4][5]
Iṣé̩ Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Olóṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2003, Ciroma dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gégé bí olùdije fún Borno South Senatorial District.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Cabinet Shake-up: The Final Baton". ThisDay. July 17, 2005. Archived from the original on July 18, 2005. Retrieved 2010-04-18. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "The Federal Republic of Nigeria". Worldwide Guide to Women in Leadership. Archived from the original on 2009-04-21. Retrieved 2010-04-04. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Emmanuel Aziken (July 8, 2005). "Ezekwesili, Mimiko, 10 others on new cabinet list * Senate begins screening today". Online Nigeria. Archived from the original on 2016-03-03. Retrieved 2010-04-18.
- ↑ EMMA AZIKEN (July 11, 2005). "Ministerial appointments: All the intrigues". Online Nigeria. Archived from the original on 2015-07-05. Retrieved 2010-04-18.
- ↑ Agbo, Catherine (2021-10-10). "REVEALED: Top women in politics who are now missing". 21st CENTURY CHRONICLE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-02-19.