Jump to content

Wolfgang Amadeus Mozart

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Mozart)
Wolfgang Amadeus Mozart

Wolfgang Amadeus Mozart (Ọjọ́ Kẹtadínlọ́gbọ̀n Oṣù Kìíní, Ọdún 1756 sí Ọjọ́ Karùn-ún Oṣù Kejìlá, Ọdún 1791). Ó jẹ́ ọ̀kan nínú tí ó máa ń ‘Compose’ orin. Gbajúgbajà ni nínú iṣẹ́ yìí. Láti nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ta ni ó ti ní etí inú fún orin. Láìpé sí ìgbà yìí ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí níí lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ irin iṣẹ́ tí wọ́n fi ń kọrin. Salzburg ní Austria ni wọ́n ti bíi. Ìlú yìí ni bàbá rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ orin kíkọ ní ààfin Archbishop ti Salzburg.

Ọmọ ọdún mẹ́fà ni Mozart nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin gan-an. Ó bá bàbá rẹ̀ àti à̀ǹtí rẹ̀ ṣe ìrìnàjò lọ sí ìlú Òyìnbó. Àǹtí rẹ̀ yìí náà mọ orin-ín kọ gan-an ni. Gbogbo ènìyàn ló ń gbé wọn gẹ̀gẹ́ ní gbogbo ibi ti wọ́n lọ. Ìgbà yìí ni Mozart ti bẹ̀rẹ̀ síí kọ orin fún ara rẹ̀.

Kò sí irú orin tí Mozart kò lè kọ. Ó ń kọ opera, choral music, orchestral music àti chamber music. Ara àwọn opera tí ó kọ ni ‘The Marrcege of figaro’ ‘Dio Giovanni’ àti The Magic Flute’. Nínú wọn, the Magic Flute ni ó gbajúmọ̀ jù.

Lára àwọn symphonies bí ogójì tí ó kọ ‘Jupiter’ tàbí ‘Symphony C major’. ‘Symphony ni G minor’ àti ‘the Symphony in E flat major’ ni ọ̀pọ̀ sọ pé ó dára jù lára iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ mìíràn tí ó lápẹrẹ ni ‘Eine Kleine Nachtmusik’ ti ó jẹ́ ‘serenade’ àti ‘Sinfonia Concertante’ tí ó jẹ́ ‘concerto’ fún violin àti viola.

Lékèé gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe yìí, kò lówó. Ọmọ ọdún márùndínlógájì péré ni nígbà tí ó kú wọ́n sì sin ín sí ibi tí wọ́n máa ń sin àwọn òtòsì sí ní Vienna.