Jump to content

Muazu Magaji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Muazu Magaji

Muazu Ahmad Magaji (tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Dansarauniya) ó jẹ́ ẹnjinníà epo rọ̀bì, ajìjàgbara, àti olóṣèlú Nàìjíríà láti ìpínlẹ̀ Kano.

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti ẹ̀kọ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Muazu ní Sarauniya abúlé ti Dawakin Tofa ìjọba ìbílẹ̀ ti ìpínlẹ̀ Kano. Muazu gba ìwé ẹ̀rí rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ọdún 1980; ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírí Dawaking Tofa Secondary school láàárín ọdún 1980 sí 1983, ó sì gba National Diploma nínú Mechanical engineering from Kano State Polytechnic ní ọdún 1989. Ó parí pẹ̀lú Bachelor of Engineering in Mechanical Engineering ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Bayero University Kano, ó sì gba ìwé ẹ̀rí onípò kejì nínú Oil & Gas Engineering ní Robert Gordon University ní ọdún 2000; ó gba ìwé ẹ̀rí nínú project management, oil & gas well engineering, geosciences àti Information Technology ní ọdún 2006.

Muazu bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ ní Kano State Civil Service Commission ní ọdún 1989 ó sì fẹ̀hìntì ní ọdún 2009, nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ Shell Oil Company fún ọdún mẹ́wàá.

Ní ọdún 2010, Ààrẹ Goodluck Jonathan yàn án gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso iṣẹ́ àkànṣe SURE-P níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ láàárín ọdún 2010 sí ọdún 2013. Gómìnà Rabiu Kwankwaso yàn án gẹ́gẹ́ bí Senior Special Assistant lórí iṣẹ́ àkànṣe Project Planning and Monitoring láàárín ọdún 2013 sí ọdún 2015. Muazu díje fún ipò gómìnà ní ọdún 2014 ó yọwọ́ nínú ìdíje síwájú ìbò láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́.

Muazu tún di yíyàn gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà fún Iṣẹ́ láti ọwọ́ Gómìnà Abdullahi Umar Ganduje ní ọdún 2019. Ní ọjọ́ 17 oṣù kẹrin ọdún 2020 Abba Kyari, olórí àwọn òṣìṣẹ́ sí ÀàrẹMuhammad Buhari, kú ikú ààrùn COVID-19. Ní ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀, Muazu sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ lórí ikú Ọ̀gbẹ́ni Kyari: "Jáwé olúborí … Nàìjíríà ti ní òmìnira Abba Kyari sì kú sínú àjàkálẹ̀ ààrùn … Kíkú fún ìlú ẹni ọkùnrin ṣe déédéé! Kọmísọ́nà fún Ìròyìn Comrade Muhammad Garba kéde pé Muazu pàdánù ipò Kọmísọ́nà rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nítorí pé àwọn ènìyàn ń sọ pé because ó ń ṣe àjọyọ̀ ikú Ọ̀gbẹ́ni Kyari, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Muazu kọ̀ jálẹ̀ pé irọ́ ni .

Gómìnà Abdullahi Umar Ganduje tún un yàn gẹ́gẹ́ bí Alága NNPC-AKK Pipeline Project Delivery àti ìgbìmọ̀ Kano State Industrialization.

Wọ́n se àyẹ̀wò pé Muazu náà ní ààrùn COVID-19 wọ́n sì yà á sọ́tọ̀ fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ 3 sí 4 ní ọ̀kan nínú àwọn ààyè ìyàsọ́tọ̀ 3 tó wà ní Kano. Wọ́n padà dá a sílẹ̀ lẹ́yìn tí kò ní ààrùn náà mọ́.