Nadine Ibrahim

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Nadine Ibrahim
Ọjọ́ìbíÀdàkọ:Birth based on age as of date
Kaduna
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Gloucestershire
Iṣẹ́Film director
Ìgbà iṣẹ́2015-present

Nadine Ibrahim (tí a bí ní ọdún 1993/1994 ) jẹ́ olùdarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìsẹ̀mí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ibrahim ní ìlú Kaduna ó sì dàgbà sí inú ẹ̀sìn Mùsùlùmí. Ìyá rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Amina J. Mohammed ti fìgbà kan jẹ́ òjíṣẹ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà rìí fún ètò àyíká.[1] Láti ìgbà tí ó ti wà lọ́mọdé ni ó ti ní ìfẹ́ sí ṣíṣe fíìmù.[2] Ó kó lọ sí Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá[3] níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣe fíìmù láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Gloucestershire University. Ó tún maá n ṣiṣẹ́ lóri àwọn iṣẹ́ àkànṣe fún Ajo Agbaye pẹ̀lú ṣíṣe àwọn fíìmù tó dá lóri ìrírí ayé. Ibrahim jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n gbé eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Hakkunde jáde. Eré náà dá lóri ará Gúúsù Nàìjíríà kan tí ó ṣe alábàápàdé àṣà Ariwa fún ìgbà àkọ́kọ́.[4]

Ibrahim tọ́ka sí Tyler Perry, Alfred Hitchcock, Spike Lee àti Ang Lee gẹ́gẹ́bi àwọn àwòkọ́ṣe rẹ̀.[5]Ó tún tọ́ka sí ìyá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹni tí ó tún ní ipa pàtàkì lóri rẹ̀.[2] Wọ́n dárúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ olùbéréjáde tí ó ní ìlérí jùlọ ní Nàìjíríà.[6] Ibrahim ṣe ìgbeyàwó pẹ̀lú Nasir ní ìlú Àbújá ní ọdún 2014.[7]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 2015: Idéar (short film)
  • 2017: Hakkunde (short film)
  • 2017: Through Her Eyes (short film)
  • 2018: Tolu (short film)
  • 2019: I am not corrupt (short film)
  • 2019: Marked (short film)
  • 2019: Words cut deep (short film)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]