Jump to content

Nedu Wazobia

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Nedu Wazobia

Nedu Wazobia (tí a bí ní Chinedu Ani Emmanuel ọjọ́ 5 oṣù kẹjọ ọdún 1982) jẹ́ oníròyìn orí rédíò Nàìjíríà, akàròyìn amóhùnmáwòrán, olóòtú, adẹ́rìn-ínpòsónú, àti olùṣẹ̀dá eré apanilẹ́rìn-ín.

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ àti iṣẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Nedu Wazobia ní ìlú Kaduna, Nàìjíríà. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣirò owó ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Madonna University ní Elele Okija, Ìpínlẹ̀ Anambra. Lẹ́yìn náà ni ó kópa nínú ètò agùnbánirọ̀ oní kànpa National Youth Service Corps (NYSC), níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́se orí afẹ́fẹ́ ní ilé iṣẹ́ rédíò radio stationJigawa. Lẹ́yìn tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ní Abuja fún ọdún méjì, ó kó lọ sí Èkó ó sì darapọ̀ mọ́ Wazobia FM gẹ́gẹ́ bí akàròyìn, níbi tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n pẹ̀lú orúkọ "Nedu Wazobia."

Ní Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ti ṣe orísìírísìí ẹ̀dá ìtàn nínú eré apanilẹ́rìn-ín orí afẹ́fẹ́ rẹ̀, tí ó fi mọ́ Sister Nkechi, Alhaji Musa, EndTime Landlord, àti Officer Jato. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùgbàlejò ètò orí afẹ́fẹ́ Honest Bunch, pẹ̀lú Husband Material, Deity Cole, àti Ezinne, èyí tí ó ń jíròrò àwọn àkòrí tó ṣe pàtàkì sí àwọn ènìyàn àtijọ́ àti ti òde òní. Ó fi ilé iṣẹ́ ìròyìn náà sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2025 látàrí awuyewuye.

Ìgbésí ayé Àdáni

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó fẹ́ Uzoamaka Ohiri ní ọdún 2013, tọkọtaya náà sì bí ọmọ mẹ́ta kí wọ́n tó kọ ara wọn sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún márùn-ún.

Ilé iṣẹ́ àti Ìbuwọ́lù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nedu jẹ́ àwòkọ́se fún ilé iṣẹ́. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilé iṣẹ́ fún MTN, Fidelity Bank, Quickteller, and Sun Lottery.

Àmì ẹ̀yẹ àti Ìfàkalẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Africa Magic Viewers' Choice Awards |Best Actor In A Comedy Drama, Movie Or TV Series |Inside Life